Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fẹ̀sùn kan Ọ̀gá Ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí, Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun pé ó gbìmọ̀pọ̀ Pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti tẹ̀lé ” ìdájọ́ òfegèé” nípa ṣíṣe ìrànwọ́ fáwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àná tí a ti rọ̀ loyè, kí wọ́n bọ́ sórí àga ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun.
Alàgbà Sunday Bìsì; ẹni tó jẹ́ tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ PDP ló fi ẹ̀sùn yìí kan Ọ̀gá Ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní olú ilé iṣẹ́ ní Òṣogbo. Ó fẹ̀sùn kàn án pé Ẹgbẹ́tókun kó ogunlọ́gọ̀ àwọn Ọlọ́pàá wá láti sin àwọn alága àti káńsẹ́lọ̀ wọn dé ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ kóówá wọn.
Olóyè Bìsì, nínú àlàkalẹ̀ rẹ̀, sọ ọ́ ní pàtó pé ìgbésẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀nà àrà láti dojú ìjọba ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun délẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí gómìnà Adélékè di àfẹ́kù. Ó ṣàlàyé síwájú sí i pé ọ̀gá Ọlọ́pàá náà já gómìnà Adélékè kulẹ̀ pátápátá lórí igbẹ́kẹ̀lé tó ti ní nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó ní “ìjíròrò nípa ìpèsè ààbò tó ti ṣe pẹ̀lú gómìnà tẹ́lẹ̀ ti di àṣìlò báyìí. Èyí ló sì fún àwọn oníjàgídí-jàgan láàyè láti pitú burúkú ọwọ́ wọn ní ìpínlẹ̀ yìí”
Ẹgbẹ́ PDP tún tẹnu mọ́ ọn pé ẹgbẹ́ APC ti ń wá gbogbo ọ̀nà láti ba ìjọba Adélékè jẹ́ láti ìgbà tí ẹgbẹ́ APC ti fìdí rẹmi nínú ìbò ọdún 2022.
Olóyè Bìsì sì ń ṣe ikilọ fún Ọ̀gá Ọlọ́pàá pé kó dẹ̀yìn nínú rúkè-rúdò àti wàhálà tó ń fà lẹ́sẹ̀ láti gbè lẹ́yìn ẹgbẹ́ APC.
Ó ní kí gbogbo àgbáyé kilọ̀ fún ọgbẹ́ni Ẹgbẹ́tókun pé kó dẹ́yìn nínú wíwá gbogbo ọ̀nà láti rẹ́yìn gómìnà. Ó ní gbogbo ìgbésẹ̀ yìí ló ti wà lọ́kàn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun látìgbà tí àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti fi ìbò yọ ọwọ́ kí-là-ń-kó wọn kúrò nínú ìsèjọba, nínú ìbò tí wọ́n dì ní 2022.
Wàhálà yìí tún súyọ gbúkẹ́ ní ọjọ́ Ajé tó kọjá nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC gbìyànjú láti gùn lé ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ ní tipátipá, kí wọn sì gba ìṣàkóso ètò ìjọba ìbílẹ̀ jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun.. Àmọ́, ìgbésẹ̀ yìí ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP ò fara mọ́, tó sì fi di gbódó-n-róṣọ láàárín àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì, tí ẹ̀mí èèyàn mẹ́fà sì bá a rìn, nínú èyí tí a ti rí ọ̀kan nínú àwọn olóyè APC, tí í ṣe Rẹ̀mí Abass tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá sì tún bàjẹ́.
Pẹ̀lú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí náà, àwọn alága àti káńsẹ́lọ̀ APC sì tún tẹ̀síwájú láti gba àkóso ìjọba ìbílẹ̀ náà ní ọjọ́rùú tó kọjá – 19/02/25.
Ọ̀rọ̀ yìí kò jọ ohun tí yóò tán bọ̀rọ̀, láti ìgbà tí rúkèrúdò náà ti ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti ń nàka àbùkù síra wọn.
Àná ni àwọn ọmọlẹ́yìn Oyetola nàka àbùkù sí i pé àwọn kábàámọ̀ lórí òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó ṣẹlẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Wọn ní gómìnà àná ló ṣì wọ́n lọ́nà lórí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí inú ń bí náà dẹ̀bi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ru Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Olóyè Adégbóyega Oyetọ́lá ; wón ṣàpèjúwe Oyetọ́lá gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tí kò náání àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn tó lu jáde láti inú ẹgbẹ́ APC, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ni wọ́n kẹ́nu bo Oyetọ́lá nípa kíkúnná tó kùnà tó kùnà láti dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀.
Wọ́n tilẹ̀ bínú pé Oyetọ́lá àti àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ kọ̀ láti sọ Òótọ́ àti pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i gbangba kedere ni pé ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò tilẹ̀ bá ohun tí wọ́n sọ lọ rárá ni. Lára ohun tó lu síta nínú ìjíròrò wọn rèé ” Ẹ̀yin èèyàn mi, a ti dé ìkòríta tó yẹ ká tún èrò wa pa báyìí, kí a fojú sùnnùkùn wo ọjọ́ iwájú wa nínú ètò ìṣèlú pẹ̀lú ọkùnrin tí a ń pè ní aṣáájú wa yìí o. Aṣáájú tó jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀.”
Ó sọ ọ́ débi pé ” Alhaji Oyetọ́lá ti ní ẹ̀mí ìmọtara-eni jù, kò sì wá Ire fún wa rárá ” Wọ́n ní wàhálà tó dé bá wọn lónìí, Oyetọ́lá ló fà á ; tó bá ti jẹ́ kí wọ́n kópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀, àwọn ì bá má ti máa sá kijokijo káàkiri báyìí. Wọ́n ní oore-ọ̀fẹ́ bàǹtà-bañta ni ètò ìdìbò náà I bá jẹ́ fún wọn láti mọ ibi tí ó kù sí fún wọn, káwọn sì ṣe àtúnṣe tó yẹ de ìbò gómìnà tó ń bọ̀.
Ta ló kàn tí wọn yóò nàka àbùkù sí báyìí?