Chukwunonso Okafor; ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ìwé kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó yóò lo gbogbo ìṣẹ̀mí rẹ̀ yòókù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́ta lò pọ̀ ní ilé ìwé tó ti ń ṣiṣẹ́ náà.
Adájọ́ Abiola Soladoye ló gbé ìdájọ́ yìí kalẹ̀, lẹ́yìn gbogbo atótónu, adájọ́ wí pé kò sí àní àní lórí ọ̀rọ̀ náà, Okafor jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
Àlàyé ẹ̀sùn náà ni pé wọ́n ká Chukwunonso mọ́ ibi tó ti ń mu ọyàn ọmọ náà tó sì tún gbé okó rẹ̀ sí ọmọ náà lẹ́nu. Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ó ti bá ọmọ náà ní àjọṣepọ̀ dáadáa.
Adájọ́ ti pàṣẹ báyìí pé kí Chukwunonso ó lọ lo gbogbo èyí tó kù nínú ìṣẹ̀mí rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Kìí ṣe ònì ni a ti ń gba ìròyìn nípa àwọn olùkọ́ tí wọ́n ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lò. Àwọn olùkọ́ ilé ìwé ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣì ń gba atẹ́gùn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n báyìí lórí ẹ̀sùn ìfipá bá akẹ́kọ̀ọ́ lò pọ̀ yìí náà.
Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kà báyìí pé:
Àwọn olùkọ́ ilé ìwé ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ni ilé ẹjọ́ gíga ti fi téèbù wọn ẹ̀wọ̀n fún bíi ẹni wọn gààrí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fipá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lò pọ̀. Ohun tó so okùn ọ̀ràn yìí mọ́ wọn lọ́run daindain ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ọmọdé lábẹ́ òfin nítorí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlọgún.
Àwọn olùkọ́ náà ni: Gbenga Ajibola; ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti Ayodele Olaofe: ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta. Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́ta ni wọ́n fi kan àwọn olùkọ́ méjì yìí, ìfipábánilò ni olúborí àwọn ẹ̀sùn náà. Àwọn olùkọ́ náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ẹni máa parọ́ lá ní ẹlẹ́rìí òun wà lọ́run, àwọn ọmọbìnrin yìí jẹ́rìí níwajú adájọ́ Adeniyi Familoni ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti. Ọ̀kan nínú wọn ṣe àlàyé pé ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ni ọ̀gbéni Ajibola ń kọ́ òun nílé ìwé náà, ó ní lọ́jọ́ náà, ọ̀gbéni Ajibola wí pé kí òun ó wọ aṣọ ilé wá ó sì fún òun ní igba náírà pé kí òun ó lọ dúró de òun ní iwájú ilé epo kan ní òpópòná ilé ìfowópamọ́ kan ní Ado-Ekiti.
Ọmọ yìí wí pé nígbà tí òun dé ibẹ̀, ọmọ kíláàsì òun kan náà dé bá òun níbẹ̀ ó sì wí pé ọ̀gbẹ́ni Olaofe ló ní kí òun ó wá dúró de òun níbẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn olùkọ́ méjéèjì yìí dé wọ́n sì kó wọn lọ sí ilé ìtura kan tó wà ní Oke-Ila, Ado-Ekiti. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n mú àwọn ọmọ náà lọ́kọ́ọ̀kan lọ sí yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n sì fi okó ba abẹ́ wọn jẹ́.
Ọmọ yìí wí pé láti ìgbà náà ni ọ̀gbẹ́ni Ajibola ti ń da òun láàmú pé kí àwọn ó tún lọ ṣe síi, nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ ló sọ fún ìyá rẹ̀ tí àwọn ìyá méjéèjì sì fi tó àwọn agbófinró létí.
Agbẹ̀jọ́rò àwọn olùkọ́ yìí gbìyànjú tirẹ̀, àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́fà ló kó wá sílé ẹjọ́ tí wọ́n wá tako ẹ̀sùn náà, ó wí pé àwọn ọ̀tá àwọn olùkọ́ yìí ló fi ìtàn náà sí àwọn ọmọ náà lẹ́nu pé irọ́ ni wọ́n ń pa.
Adájọ́ Adeniyi ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí àwọn ọmọ náà láti orí ìwé àyẹ̀wò dọ́kítà nílé ìwòsàn tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọ náà gba kùmọ̀ sára tó fi dé orí ìwé ìforúkọsílẹ̀ ilé ìtura náà, Adájọ́ wí pé àwọn olùkọ́ yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún ló wọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ìdí nip é àwọn ọmọ náà jẹ́ màjèsín, ẹ̀kejì ni pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni àwọn olùkọ́ yìí àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà lábẹ́ òfin kí àwọn yóòkù ó le fi tiwọn kọ́gbọ́n
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan lórí ìfipábánilò yìí kan náà pé:
Olajobi Taiwo ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Olajobi nígbà tí ọmọbìnrin náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.
Ìyá rẹ̀ fẹ́ nà án ló ṣe sá kúrò nílé, ọwọ́ Olajobi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló kó sí, wọ́n tàn án wọlé wọ́n sì fi ipá báa ní àjọṣepọ̀. Agbègbè Oke ila ní Ado Ekiti ni èyí ti ṣẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì; Sunday Abutu wí pé ọwọ́ àwọn ti tó Olajobi o lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá ọmọdébìnrin náà lò. Wọ́n ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà ṣọwọ́ sí ẹ̀ka tó kàn gbọ̀ngbọ̀n.
Lórí ìfipábánilò yìí kan náà ni Akeem Somonu fi rí ẹ̀wọ̀n he. A gbọ́ pé:
Akeem Sumonu, ẹni ogún ọdún ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Agbègbè Olodo ní ìjọba ìbílẹ̀ Odeda, ìpínlẹ̀ Ogun ni èyí ti ṣẹ̀.
Inú oṣù Ọ̀wàrà ọdún 2024 ni Akeem fi ipá bá ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò tó sì tún ṣẹ̀rù bà á pé kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.
Ọmọ yìí kò wí lóòótọ́, ìyá rẹ̀ ló kíyèsí pé ọmọ náà ń yí padà, ó pè é ó sì tẹ̀ ẹ́ nínú dáadáa, ọmọ yìí jẹ́wọ́ pé bùọ̀dá Akeem ló fi ipá bá òun lò.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé wọ́n fi ipá gba ìbálé ọmọ náà ni, pabambarì ni pé ọmọ yìí ti fẹ́rakù látàrí ìbálòpọ̀ tìpátìkúùkù yìí.
Christiana; ẹni tó jẹ́ ìyá ọmọdébìnrin yìí ló fi ọlọ́pàá gbé Akeem, pàkò bí ẹni ọkọ̀ já sílẹ̀ ni ó ń wò, ó jẹ́wọ́ pé òun hu ìwà náà lóòótọ́.
Ṣé ẹ̀yin ò rò pé àsìkò ti tó láti máa gé okó ọkùnrin tó bá fipá bá obìnrin lò?




