Alága ìjọba ìbílẹ̀ Ẹ̀pé; Surah Animashaun ti fagi lé ètò àdúrà ọdún iléyá tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní Ẹ̀pẹ́ lẹ́yìn tó rọ Ọba Ẹ̀pẹ́ titun lóyè.
Ohun tó fa ìgbésẹ̀ tí Arábìnrin Surah gbé yìí ni pé àwọn méjì ni wọ́n ń pe ara wọn ní Olú ti ìlú Ẹ̀pẹ́ tó sì ti dá yánpọyánrin sílẹ̀ láàrín ìlú.
Lẹ́yìn tí Ọba Shefiu Adewale wàjà, àwọn olóyè mejì ni wọ́n ń pe ara wọn ní adélẹ. Orúkọ wọn ni Olóyè Adeniyi Kadri Odedeogboro àti Olóyè Iskilu Olajide Ikuforiji.
Ọjọ́ Ajé, oṣù yìí ni àwọn méjéèjì fi ara wọn jẹ Olú ti Ẹ̀pẹ́ ní ààfin. Arábinrin Surah kọ ọ́ sínú ìwé tó fi ránṣẹ́ sí wọn pé òun dá rọ àwọn méjéèjì lóyè ná tí gbogbo ọ̀rọ̀ yóò fi ní ìyanjú. Ìdí ni pé òun kò fẹ́ kí àwọn alátìlẹyìn àwọn méjéèjì ó ṣe ìkọlù síra wọn.
Bákan náà ni ó fagi lé àdúrà ọjọ́ ọdún iléyá àti irun Ídì ti ìlú Ẹ̀pẹ́, ó wí pé òun kò fẹ́ kí àwọn èèyàn ó pàdánù ẹ̀mí tàbí farapa nítorí pé o ṣeéṣe kí àwọn alátìlẹyìn àwọn ọba méjéèjì ó wojú ara wọn níbi irun ọdún náà.
Nítorí àwọn ẹ̀mí tó sọnù, Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger fagi lé àwọn àjọyọ̀ ọdún iléyá.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger; Umar Bago ti fagi lé àwọn àpéjọ àjọyọ̀ ọdún iléyá ti ọdún yìí látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé tó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ.
Àwọn àpéjọ bíi Hawan Bariki, Durbar àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé lọ́dún yìí ni ìpínlẹ̀ Niger.
Ó wí pé àwọn yóò fi àkókò ọdún yìí dárò àwọn èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ omi náà lọ àwọn yóò sì gba àdúrà fún wọn.
Ní ìlú Ìbàdàn, ọ̀dọ́mọkùnrin kan jábọ́ láti ilé kòkó.
Arákúnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Feranmi Akin-Akinye ti jábọ́ láti òkè ilé alájà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tíí ṣe ilé kòkó ní Ibadan.
Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì, oṣù Igbe yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ọkùnrin náà ṣe jábọ́.
Ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé wí pé òun rí nǹkan náà tó ń bọ̀ nílẹ̀ àmọ́ òun rò pé ẹyẹ kan tó tóbi ni àfi ìgbà tó balẹ̀ tán kí òun tó rí i pé èèyàn ni.
Ó wí pé ọkùnrin náà kọ́kọ́ jábọ́ lu òrùlé kan kó tó wá jábọ́ sílẹ̀.
Adarí ẹ̀ka ìfitónilétí ilé iṣẹ́ kòkó náà; Victor Ayetoro wí pé lójú ẹsẹ̀ ni àwọn ti ránṣẹ́ pe àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tí wọ́n sì gbé ọkùnrin náà lọ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Ibadan.
Ọ̀gbẹ́ni Ayetoro wí pé àwọn yóò fi ọwọ́ sowọpọ̀ pẹ̀lú àwọn agbófinró láti ṣe àwárí ohun tó fa bí ọkùnrin náà ṣe jábọ́.
Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Feranmi lásìkò ikú rẹ̀, ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga Afe Babalola tó wà ní Ado Ekiti.
A gbọ́ pé Feranmi ń bá ilé iṣé kan tó wà ní ilé kòkó náà ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ, àwọn ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ wí fún un pé kí ó kan àpótí ìpolówó ọjà ńlá kan mọ́ òkè abala kan ní ilé kòkó náà.
Iṣẹ́ yìí ni Feranmi fẹ́ ṣe tó fi jábọ́ tó sì gbẹ́mìí mìn.
Ní báyìí, ìròyìn fi yé wa pé wọ́n ti sin òkú Feranmi sí ìlú rẹ̀.
Àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Complete child development tí wọ́n ṣe igbákejì ọ̀gá ilé ìwé náà mọ́kumọ̀ku ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó ti fi òfin gbé òbí àti àwọn mẹ́rin mìíràn tí wọ́n ṣe ìkọlù sí igbákejì ọ̀gá ilé ìwé ọmọ rẹ̀.
Ilé ìwé Complete Child Development tó wà ní Aule, Àkúrẹ́ tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo ni èyí ti ṣẹ̀, Alexander Rotifa ni orúkọ igbákejì ọ̀gá iĺ ìwé yìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń kọ ìdánwò àṣekágbá WAEC lọ́wọ́ ló mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọ inú gbọ̀gán ìdánwò náà, níbi tó ti ń fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yìí ṣe màgòmágó ìdánwò náà ni ọ̀gbẹ́ni Alexander ti ká a tó sì gba ẹ̀rọ náà lọ́wọ́ rẹ̀.
Ọmọ yìí délé ó rò fún àwọn òbí rẹ̀, wọ́n bínú wọ́n sì faraya. Nígbà tó di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn gìrìpá mẹ́rin tí àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ yìí rán wá dé sí ilé ìwé náà, wọ́n wọ́ igbákejì ọ̀gá jáde wọ́n sì lù ú lálùkì.
Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ránṣẹ́ pe àwọn ọlọ́pàá àmọ́ ipá wọn kò ká àwọn gìrìkó yìí, wọ́n lu ọ̀gbẹ́ni Alexander lálùbami wọ́n sì tún ṣe é léṣe.
Ní báyìí, ìyá àti bàbá akẹ́kọ̀ọ́ yìí àti àwọn afurasí mẹ́rin mìíràn ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn Chidera láti ìpínlẹ̀ Ebonyi pé
Chidera Ezeokoe ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekú pa alábàágbé rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rose Awoke.
Abúlé Ezzagu ni ìjọba ìbílẹ̀ Isielu, ìpínlẹ̀ Ebonyi ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀, ẹni ọgọ́ta ọdún ni Rose Awoke lásìkò ikú rẹ̀.
Àlàyé tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi; Joshua Ukandu ṣe ni pé èdè àìyedè kan ló ṣẹlẹ̀ láàrín Chidera àti Rose ni Chidera bá gbé sọ́bìrì tó sì fọ ọ́ mọ́ Rose lórí láìmọye ìgbà.
Rose kú sínú àgbárá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí Chidera fi sílẹ̀ sí tó sì sá lọ. Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Chidera báyìí ó sì ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Ní ìpínlẹ̀ Sokoto.
Kò dín ní àwọn èèyàn méje tí wọ́n ti gbẹ́mìí mìn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Sokoto ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì oṣù yìí.
Àwọn èèyàn yìí wọ ọkọ̀ ojú omi láti Gidan Husaini, wọ́n ṣe alábàápàdé ìjì ńlá kan lọ́nà, ìjì yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó da ọkọ̀ ojú omi náà nù sínú alágbalúgbú omi.
Ìjọba ìbílẹ̀ Shagari tí ìlú Gidan Husaini wà kò tíì ṣe ìdámọ̀ àwọn èèyàn náà àmọ́ wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ ìlú Gidan Husaini ni gbogbo wọn.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìṣùná; Muhammadu Jabbi Shagari ṣe àbẹ̀wò sí ìjọba ìbílẹ̀ Shagari ní orúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto. Ó wí pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà bani lọ́kàn jẹ́.
Jabbi Shagari rọ àwọn ará ìlú láti máa wọ aṣọ ààbò orí omi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá wọ ọkọ̀ ojú omi.




