Àwọn ará abúlé Ifa Ikot Akpan ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ké gbájarè sí àwọn ọlọ́pàá láti gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń dún mọhurumọ̀ruru mọ́ àwọn.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK kọ ìwé pélébé há fún àwọn ará ìlú, ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé náà ni pé kí àwọn aráàlú náà ó máa múra ìkọlù tó lágbára tí àwọn yóò ṣe sí wọn.
Wọ́n ní àwọn yóò ṣe ìkọlù sí àwọn aráàlú náà nítorí pé wọ́n màá ń yọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn lẹ́nu ní gbogbo ìgbà.
Ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK fi ẹ̀sùn kan àwọn ará ìlú Ifa pé wọ́n ń fi àwọn ọlọ́pàá halẹ̀ mọ́ àwọn wọ́n sì ń yọ àwọn lẹ́nu. Wọ́n ní ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún wá kó àwọn tàbí yọ àwọn lẹ́nu, àwọn èèyàn tí àwọn yóò pa díi ni:
Ọ̀gbẹ́ni Abasiama Eti Eyo, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Offiong Essien, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Etim Ben, Ọ̀gbẹ́ni Eddiong Efiong àti Ọ̀gbẹ́ni Victor Edet Asuquo.
Wọ́n ní àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n ń ta àwọn ọlọ́pàá lólobó nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.
Wọ́n wá fi ìkìlọ̀ kún un pé ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn, gbogbo àwọn tí àwọn dárúkọ náà ni wọn yóò lọ síi nítorí pé ọmọ ìlú Ifa náà ni olórí àwọn, àwọn kò tún gbodò máa bẹ̀rù láàárín ìlú.
Baálẹ̀ abúlé Ifa Ikot Akpan; Ọ̀gbẹ́ni Eteidung Ebong fi ọ̀rọ̀ náà tó kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa Ibom àti Gómìnà Umo Eno láti gba àwọn kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà láti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ní ìlú náà. Ó wí pé òun mọ àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn tí wọ́n dárúkọ sínú ìwé náà ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.
Ìròyìn nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kò tán síbẹ̀ o, a gbọ́ nípa ìkọlù tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣe sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga Niger tí wọ́n ṣá láṣàápa.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì ti ilé ìwé gíga Niger Delta tó wà ní Amassoma ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣá láṣàápa báyìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn méjì yìí wà ní Gbarantoru ní Yenogoa, ìpínlẹ̀ Bayelsa, ìwé ìpè sí àgùnbánirọ̀ ni wọ́n ń retí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tó ṣá wọn pa.
Orúkọ èkíní ń jẹ́ Ayaokpe Sinclair nígbà tí a kò tíì mọ orúkọ èkejì. Ìrọ̀lẹ́ àná; Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Èbìbí ni wọ́n ṣá wọn pa.
Aláṣẹ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Bayelsa; Tolummbofa Johnathan ṣe àlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì yìí ń rìn lọ ní òpópónà ni àwọn kan pariwo láti inú ọkọ̀ pé “àwọn nìyẹn” wọ́n bọ́ sílẹ̀ tì àwọn méjì náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo “Aye, Aye” kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn ládàá.
Ayaokpe kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ èkejì rẹ̀ gbìyànjú àti sálọ, awakọ̀ tó gbé wọn wá ríi pé àbúrò òun ni ó sì gbé e lọ sínú ọkọ̀ kó le gbé é sálọ àmọ́ wọ́n ká wọn mọ́ inú ọkọ̀ náà wọ́n sì ṣá a pa.
Johnathan wí pé àwọn rí awakọ̀ náà mú àwọn sì ti fàá lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣá olórí wọn láṣàápa ní ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ kà báyìí pé:
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Bobos ti ṣekú pa olórí wọn; Olotu Omubo nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ipò náà.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé àwọn ọmọlẹ́yìn Olotu Omubo náà ni wọ́n pa á nítorí pé wọ́n fẹ́ fi èèyàn tiwọn sí ipò náà ní ẹni tí wọ́n lérò pé àsìkò rẹ̀ yóò san àwọn.
Ìdílé Nembe ni Omubo ti jáde wá, òpópónà Goodnews ní Azikoro, Yenagoa ni wọ́n pa á sí lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ìṣọ́wọ́paá nípakúpa tí wọ́n pa á kalẹ̀ ló tọ́ka sí pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni.
Bákan náà ni àwọn èèyàn rò o pé o ṣeéṣe kó jẹ́ àwọn ikọ̀ mìíràn ló pa á ní ìránró àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó ti pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìjà abẹ́nú wà nínú ẹgbẹ́ Bobos tí Omubo jẹ́ olórí wọn, wọ́n ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ló pa á lọ́nà tí yóò fi dàbí pé àwọn ikọ̀ mìíràn ni ó ṣekú pa á. Wọ́n ní ìdí ni pé wọ́n kò fẹ́ Omubo ní olórí wọn mọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àfikún pé oríṣìí ẹ̀sùn ni Omubo ní nílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn ọkùnrin kan tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí pa ní Ikorodu pé:
Àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n ti ṣá arákùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Benjamin pa ní Ikorodu báyìí o. Ohun tí a gbọ́ ni pé Benji ni ìnàgijẹ ọkùnrin náà ó sì jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣàwámà tí ilé iṣẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Chibest. Agbègbè Ebutte-Ipakodo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni àwọn ọkùnrin méjì kan dé sí ìsọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń dá àwọn oníbàárà lóhùn lọ́wọ́, wọ́n sún mọ́ ọn dáadáa kí wọ́n tó yin ìbọn fún un láìmọye ìgbà. Kò sí ẹni tó le sún mọ́ Benji títí wọ́n fi lọ pátápátá. Nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, Benji ti dágbére fáyé.
Àwọn ará àdúgbò wí pé ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní oró ọ̀kan lára wọn tí wọ́n pa ni wọ́n fi ikú Benji rán.




