Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ àwọn mẹ́jọ kan tí wọ́n pa ọmọ ọdún mẹ́fà kan nípakúpa. Abúlé Bura-Bunga ní agbègbè Bajude ní ìjọba ìbílẹ̀ Kwami, ìpínlẹ̀ Delta ni àwọn àgbàlagbà mẹ́jọ yìí ti pa ọmọ náà.
Àwọn afurasí mẹ́jọ náà ni Magaji Adamu; ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta, Babayo Musa; ẹni ọdún méjìdínlógún, Jibrin Muhammad; ẹni ogójì ọdún, Usman Abubakar; ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì, Sadam Umaru; ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, Idris Dayyabu; ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta, Abdulrauf Hussainu; ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti Isiyaku Muhammad; ẹni ọdún mọ́kàndínlógọjì. Gbogbo wọn ló jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Gombe.
Àlàyé tí a rí gbà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe; Buhari Abdullahi ni pé àwọn afurasí náà jí Muhammad Bulama gbé, wọ́n sì pá fún aájò owó.
Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni Muhammad Bulama, Babayo Musa ló jí i gbé ní ilé bàba-bàbá rẹ̀ ní abúlé Bura-Bunga ní nǹkan bíi aago márùn-ún ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́.
Babayo gbé ọmọ náà fún Magaji; ẹni tó gbé e lọ sí igbó Wuro-Doya tó sì fi ọ̀bẹ dú ọrùn rẹ̀. Ẹ̀yìn náà ni Mogaji gé ọmọ náà sí méjì ọgbọọgba. Ó ju ìdá òkè rẹ̀ láti ọrùn dé ìbàdí sínú kànǹga ó sì gbé ìdá kejì fún Jibrin àti Usman.
Ìwádìí fi hàn pé Sadam ló bá wọn wá adáhunṣe fún aájò owó tí wọ́n fẹ́ ṣe, adáhunṣe yìí ló bèèrè ẹ̀yà ara èèyàn láti ìbàdí sílẹ̀ tí wọ́n fi pa ọmọ náà.
Orúkọ àwọn adáhunṣe náà ni Idis àti Adulrauf, wọ́n gba ẹ̀yà ara Bulama lọ́wọ́ Jibrin, wọ́n yọ ibi tí wọ́n nílò wọ́n sì sin ìyókù.
Ẹ̀sùn tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi kan Isiyaku ní tirẹ̀ ni pé kò tú àṣírí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá. Wọ́n ní ó ní òun kò bá wọn ṣe aájò owó àmọ́ kò fi tó àwọn ọlọ́pàá létí ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe yìí.
Nínú ìwádìí ni àwọn afurasí náà ti sọ pé Gimba; ẹni tó jẹ́ bàbá ọmọ náà ló yọ̀ǹda ọmọ náà fún àwọn. Wọ́n ní Gimba kò fẹ́ ìyá ọmọ náà níyàwó kò sì fẹ́ kí ohunkóhun dà wọ́n pọ̀ mọ́ ló ṣe fa ọmọ náà kalẹ̀. Kódà, Jibrin àti Usman wí pé Gimba tẹ̀lé Magaji nígbà tó wá gbé àgékù ọmọ náà fún àwọn.
Gimba ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lásìkò yìí ní èyí tí kò jẹ́ kí a fìdí ẹ̀sùn yìí múlẹ̀ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ń wá a.
Yàtọ̀ sí ẹ̀sùn ìpànìyàn yìí, Babayo àti Magaji jẹ́wọ́ pé àwọn wà lára àwọn agbésùnmọ̀mí tó ń ṣe ìkọlù sí abúlé Bura-Bunga.
Bákan náà ni ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ àwọn oníṣòwò èèyàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ọwọ́ tẹ àwọn kan tí wọ́n jẹ́ afiniṣòwò ní Ọ̀yọ́, wọ́n yóò tan àwọn ẹni náà pé àwọn yóò bá wọn wá iṣé bákan náà ni wọn yóò tún gba owó ìwáṣẹ́ lọ́wọ́ wọn.
Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n ń tàn, bí wọ́n bá rí eni bá ṣe é jí gbé, lọ́wọ́ kan ni. Èèyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́rin ni wọ́n bá nínú ilé náà lápapọ̀.
Inú ilé kan ní Ọ̀yọ́ ni wọ́n ń kó àwọn èèyàn náà sí tí àwọn oníbàárà sì wá ń mú wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.
Púpọ̀ nínu àwọn tí wọ́n bá nínú ilé náà ló jẹ́a àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Congo nígbà tí àwọn mìíràn jẹ́ ọmọ ìbàdàn.
Wọ́n ti kó àwọn tí wọ́n rí gbà náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Eleyele, Ìbàdàn nígbà tí ìwádìí ṣì ń tẹ̀síwájú.
Ìròyìn mìíràn tó farapa èyí ni ìròyìn nípa Cecelia; eni ọdún mọ́kàndínlógún kan tí Johnson tà fún afiniṣòwò nàbì. A gbọ́ pé ọwọ́ àwọn agbófinró ìpínlẹ̀ Bauchi ti tẹ àwọn méjì kan tí wọ́n jẹ́ afọmọṣòwò nàbì.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi; Ahmed Wakil ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé Rhoda Cosmos ló wá fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé àwọn kan ṣe ọmọ òun báṣubàṣu.
Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Cecelia Cosmos, ní ọjọ́ kejìlá, oṣù Igbe tí a wà yìí ni Johnson John sọ fún un pé òun bá a rí iṣẹ́ sí Èkó, ó fa Cecelia lé ẹnìkan tí wọ́n ń pè ní Mámà lọ́wọ́, Mámà ló mú Cecelia lọ sí Burkina Faso lọ fi ṣe òwò nàbì.
Lọ́gán ni àwọn ọlọ́pàá ti he Johnson, kódà kò jiyàn, wọ́rọ́wọ́ ló ṣe àlàyé bí ó ṣe ta ọmọ náà fún Mámà.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé ikọ̀ dìde tí yóò ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà fínní, mámà ti júbà ehoro lásìkò yìí àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn nípa Rijiyar Zaki tó sẹkú pa ìyàwó bàbá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀. A gbọ́ pé ilé ẹjọ́ gíga tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Kano ti dájọ́ ikú fún Sagiru Rijiyar-Zaki, ẹni ọdún méjìlélógún lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Rijiyar-Zaki náà ni pé ó gún ìyàwó bàbá rẹ̀; Rabiatu Sagir lọ́bẹ pa ó sì tún fi ìbòrí fún àbúrò rẹ̀; Munawara lọ́rùn pa.
Adájọ́ Amina Adamu-Aliyu wí pé gbogbo atótónu àti ẹ̀rí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Rijiyar-Zaki jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀.
Àlàyé tí a rí gbà lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ní pàtó ni pé ní ọjọ́ keje, oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún 2023, èdè àìyedè kan wáyé láàrin Rijiyar-Zaki àti ìyàwó bàbá rẹ̀, ọmọ ìyàwó bàbá rẹ̀ yìí tó jẹ́ àbúrò rẹ̀ sì gbè lẹ́yìn ìyá rẹ̀.
Nígbà tó di alẹ́ tí gbogbo wọn wọlé sùn tán, Rijiyar-Zaki mú ọbẹ tọ ìyàwó bàbá rẹ̀ yìí; Rabiatu lọ ó sì gún un láyà títí tó fi kú. Lẹ́yìn náà ni ó fi ìbòrí fún Munawara tó jẹ́ ọmọ Rabiatu lọ́rùn pa.
Rijiyar-Zaki ní òun kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn yìí àmọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀; Amòfin Mubarak Abubakar kò ní àwọn ẹ̀rí tó le tako àwọn ẹ̀rí agbẹjọ́rò ìjọba tó jẹ́ olùpẹjọ́. Adájọ́ wí pé àwọn ẹ̀rí olùpẹjọ́ àti àwọn ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n jẹ́rìí sí i fìdí ẹ̀ múlẹ̀ gbangba gbàǹgbà pé ó jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà
Discussion about this post