Aya Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà, OLUREMI TINUBU ṣàbẹ̀wò sí ìlú rẹ̀ lọ́jọ́ Rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá láti ṣe ìpolongo ètò ìlera pípé láti túbọ̀ ró àwọn olùtọ́jú aláìsàn lágbára, ibẹ̀ ló ti fún àwọn ìyá Agbẹ̀bí ní oríṣiríṣi ohun èlò ìlera kí iṣẹ́ wọn le è túbọ̀ tẹ̀síwájú sí i. Nígbà tó tó àsìkò ìwọlé aya Ààrẹ, orin ìkíni káàbọ̀ wọn bá di orin ọ̀tẹ̀. Bí Adarí ètò ṣe n lé orin àpọ́nlé tẹ̀rín tẹ̀yẹ láti fi bu ọla fún aya Ààrẹ, ṣe ni àwọn Nọ́ọ̀sì náà n kọrin àbùkù. Gbogbo ìgbìyànjú rẹ̀ láti yí orin padà kí ó dorin ọlọ́lá ló jásí pàbo, ṣe làwọn Nọ́ọ̀sì n gbọn ọwọ́ èkuru sí àwo tí wọ́n n tún orin dá. Orin náà lọ báyìí ní èdè fíntínrín:
Lílé : Na our mama b dis oooooo, we no get anoda one
Ègbè: Na your mama b dis ooo, eeeeee.
ÌTUMỌ̀:
Lílé : Ìyá tiwa rèé, a kò ní ìyá mìíràn mọ́
Ègbè : Ìya tìrẹ ni oooooo eeeeee
Bí Adarí ètò ti n gbìyànjú láti ṣàtúnṣe sí orin yìí bẹ́ẹ̀ ni àwọn Nọ́ọ̀sì n yarí pé àwọn kò le è fi ìyá oníyàá ṣe ìyá tiwọn. Èyí ṣàfihàn bí inú ará ìlú ti n ru sí ìṣèjọba Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU, ìjọba rẹ̀ le koko bí ojú ẹja, ara ò rokùn bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ adìẹ, ìṣèjọba náà kò mú ìdùnnú kankan wa láti àárọ̀ títí di alẹ́, oúnjẹ kò sí, kò sí iṣẹ́, ìlera pípé di imí eégún ológbojò, Aboyún ilé kò bí wẹ́rẹ́, àwọn àgàn kò ti ọwọ́ àlà bọ oṣù, kò sí owó ilé ìwé, owó orí tún gọbọi si fún mẹ̀kúnnù lójoojúmọ́, epo kò ṣe é rà mọ́ lọ́jà, owó oṣù kò tó nnkan mọ́. Àtolówó àti mẹ̀kúnnù ló n fi igbe ìlú le kò sówó lóde bọnu. Àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí kò le è jẹun ẹ̀mẹẹta kánú mọ́, Ayá n na ọkọ pa nítorí wọn kò le è tó ọkọ ọ́ ṣe lọ́ọ̀dẹ̀, owó ògùn ní ilé ìwòsàn kò ṣe é kọlù, gbogbo ìgbà ni àwọn ajínigbéṣowó n ṣọṣẹ́ káàkiri orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ yìí látàrí ètò àbò tó mẹ́hẹ, ojoojúmọ́ ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ n sákúrò ní ilé ìwé nítorí àìrówó san, gbogbo nnkan ni kò rọgbọ ràrá fún tẹrú-tọmọ nílẹ̀ yìí. Ànfàani nlá ni èyí jẹ́ fún àwọn Nọ́ọ̀sì náà láti fi ẹ̀họ́nnú wọn hàn lórí bí aya Ààrẹ, OLUREMI TINUBU ṣe kọ̀ láti bá ọkọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ kí ó ṣe gbogbo ohun ti ará ìlú n fẹ́, kí Ààrẹ jẹ́ kí ara rọ tónílé tàlejò,kí eku bẹ̀rẹ̀ sí i ké bí eku, kí ẹyẹ bẹ̀rẹ̀ sí i ké bí ẹyẹ, kí ọmọ ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn bí ọmọ èèyàn. Àwọn Nọ́ọ̀sì fi orin yìí ṣe atọ́nà fún aya Ààrẹ pé : Ìyá rere kò le máa wo ọmọ rẹ̀ níran, kí ìyá máa jẹ ọmọ, ìdí nìyí tí wọ́n fi lo àsìkò náà láti fi orin yìí pàrokò fún Adarí ètò pé ó le è jẹ́ ìya tìrẹ ṣùgbọ́n kìí ṣe tiwa nígbà tí ìwọ n rí jẹ́ nídìí màdàrú.
Fọ́nrán yìí gba orí ẹ̀rọ ayélujára tantan bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ọjọ́. Awuyewuye tó dá sílẹ̀ kò kéré rárá èyí ló fàá tí Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ilé ìwé gíga àwọn Nọ́ọ̀sì ti DELTA STATE COLLEGE OF NURSING, AGBOR tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Chioma fi sọ pé ilé ìwé gíga ti Nọ́ọ̀sì tó wà níbi ìpàdé náà pọ̀ lọ́jọ́ yìí àgàgà DELTA STATE COLLEGE OF HEALTH SCIENCES ti agbègbè SAPELE, Ilé ìwé àwọn Agbẹ̀bí, gbogbo òṣìṣẹ́ ìlera ìjọba àpapọ̀ Gómínà àti aya rẹ̀. Lọ́gán ni CHIOMA yọ ilé ìwé rẹ̀ kí ìjọba má bá a fi àwọn jófin. CHIOMA n ràwọ́rasẹ̀ pé kí ìjọba daríjín wọn kí wọ́n má fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yìí bi wọ́n. Ó wí pé : ‘.À n bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run , Ẹ foríjìn wá, Ẹ má ṣe fi ìwà wa bi wá, A kò sí lára wọn, wọ́n kówa pọ̀ ni.
Kíá! ni ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn nílẹ̀ yìí tó tún ti dipò Ààrẹ rí, OMOYELE SOWORE gbé ìgbẹ́sẹ̀ akin lórí ọ̀rọ̀ náà, ó tako bí ọ̀gá àgbà ilé ìwé ti fi ìwé ẹ̀sùn fífi fọ́nrán sórí ẹ̀rọ̀ ayélujára sun Akẹ́kọ̀ọ́ EDOBOR nígbà tí kọ́míṣánnà sì dási ni ó tún sọ ketekete pé wọ́n ti fagilé ẹ̀sùn tí alákoso ilé ìwé DDELTA STATE COLLEGE OF NURSING SCIENCES fi kan OSATO EDOBOR lórí bí ó ti ju fọ́nran ìpàdé náà sí orí ẹ̀rọ ayélujara níbi ìpàdé Aya Ààrẹ, OLUREMI TINUBU sí ilé ìwé wọn àti irúfẹ́ orin ìtàbùkù tí wọ́n dá fún ún. Ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ ni wọ́n fi kan OSATO EDOBOR lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù yìí pẹ̀lú ìbuwọ́lù PROVOST EVBODAGHE RITA OGONNE tó wí pé:
a gbọ́ pé OSATO EDOBOR lọ́jọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Erénà ọdún 2025 níbi ìbẹ̀wò aya Ààrẹ OLUREMI TINUBU, CON ní gbọ̀ngán DOME ní ASABA lásìkò tó n pin ètò ìlera ẹlẹ́bẹ̀ẹ́run márùn mẹ́wàá fún àwọn ìyá Agbẹ̀bí ní ààrin gbùngbùn south-south ni a rí níbi tó n dárin ọ̀tẹ̀ tó fi ṣẹwọ́ sí ẹ̀rọ ayélujára , èyí sì lòdì sí òfin gbáà. Ó ní ìjìyà lábẹ́ òfin ilé ìwé wa ní abala ojú ìwé kọkànlélógún. Alákoso ilé ìwé ní kí OSATO EDOBOR kọ ìwé ìtọrọ aforíjìn kí wákàtí mẹ́rìnlélógún tó ó pé, kí ó sọ ìdí tí kò ṣe ní jìyà fún èyí tó ṣe yìí lábẹ́ òfin. Nígbà tó di ọjọ́ Ẹtì tó kọjá, OMOYELE SOWORE na ìkà àbùkù sí alàkoso ilé ìwé náà pé ìwà tó wù yìí kò bá òfin ilẹ̀ wa mu, Ó pinnu pé òun yóò gbèjà Akẹ́kọ́ọ̀ OSATO EDOBOR nítorí wọn kò le è fi ìyà jẹ aláìṣẹ.
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn mìíràn ni CHIOMA IFEMEDUKE tó tún kín OMOYELE SOWORE lẹ́yìn, wọ́n sì tọ Kọ́míṣánà etò ìlera ìpínlẹ̀ ASABA lọ, JOSEPH ONOJAEME,wọn fi ọ̀rọ̀ tó o létí ó sì fi dáwọn lójú kò sóhun tó jọọ́, àrídájú lẹ́tà pé wọ́n ti káwọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Akẹ́kọ̀ọ́ náà nílẹ̀, Ó sí ti dá lẹ́tà tí wọ́n kọ́kọ́ fún un padà sí ẹ̀ká tó n mójútó àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà, àti pé olùkọ́ àgbà ti tọrọ àforíjì fún ìgbésẹ̀ tó gbé lórí OSATO EDOBOR.
Kí ó tó di ìgbà yìí ni aya Ààrẹ OLUREMI TINUBU ti lòdì sí bí wọn ti fi ìwé pe OSATO EDOBOR láti wá jẹ́ ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ náà. OLUREMI TINUBU gba àwọn Alákoso ilé ìwé náà láti f eegun òtòlò to ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n lo ọgbọ́n inú tí ejò n lò, Ó ní kí kò lẹ́tọ̀ọ́ kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú inúfo-àyàfoo látàrí fífí ẹ̀họ́nnú wọn hàn. Agbẹnusọ aya Ààrẹ, BUKOLA KUKOYI wí pé : ‘ ojútólé ojútóko ni ìwà tí àwọn Nọ́ọ̀sì hù lọ́jọ́ tí OLUREMI TINUBU lọ polongo ètò ìlera tó sì ṣe ìrànwọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún mẹ́wàá fún ìyá Agbẹ̀bí ní agbègbè south-south lọ́sẹ̀ tó kọjá, a ṣe e láti gbóríyìn fún àwọn ìyá Agbẹ̀bí káàkiri orígún ilẹ̀ yìí pẹ̀lú èròngbá láti din ikú ọmọ àti ìyá kù láwùjọ wa. OLUREMI dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ DELTA fún ìgbàlejo òun pàápàá ìdùnnú tí àwọn Nọ́ọ̀sì fihàn sí òun, fún ìdí èyí, wọ̀n kò jẹbì rárá lábẹ́ òfin nítorí gbogbo ènìyan ló lẹ́tọ̀ọ́ sí fífi ẹ̀họ́nnú hàn láìdi ẹnikẹ́ni tàbí dá ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ kọ́.
Discussion about this post