Àwọn arìnrìnàjò há sí ojú ònà lónìí nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan ṣàdédé gbaná lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn lónìí.
Àárín Ọ̀rẹ́méjì sí Ọlọ́runṣògo ni ọkọ̀ náà ti gbaná ní èyí tó fa kí àwọn èèyàn ó má le kọjá.
Kò sí ẹni tó bá ìjàmbá yìí lọ, ó kàn jẹ́ pé àwọn èèyàn kò le kọjá lọ ibi tí wọ́n ń lọ ni.
Iná náà pọ̀ gan-an àmọ́ kò mú ẹ̀mí lọ, àwọn panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ló ta mọ́ra dé ibẹ̀ láti kojú rẹ̀.
Adarí ilé iṣé panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́; Ọ̀gbẹ́ni Akinyemi Akinyinka fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ti yára kojú iná náà láti ṣẹ́gun rẹ̀.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkọ̀ àjàgbé agbépo yóò gbaná lójijì.
Nínú ọdún yìí ni ọ̀kan ṣẹlẹ̀ lórí afárá Otedola ní èyí tí ó mú tọkọtaya titun lọ. Ìròyìn náà kà báyìí pé;
Ọ̀sẹ̀ kẹta lẹ́yìn tí tọkọ-tayà ṣègbéyàwó, tí wọ́n filé pọn ọtí, fi ọ̀nà rokà; tí inú ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ n dùn ṣìkìn fún wọn, tí ẹbí àti ará n wúre pé ọkọ yóò gbó, ìyáwó yóò kùtà, pé ẹ̀yìn ìyàwó kò ní mẹní, pé lẹ́yìn oṣù mésàn án, a ó wá b’áwọn gbọ́wọ́ ṣíbí ìbejì lẹ́yìn ti ìyàwó ti finúṣoyún yóò fẹ̀yìn gbọ́mọ pọ̀n, pé tọkọ tayà yóò gbó kùjẹ́-kùjẹ́ ṣùgbọ́n ikú dóró, ikú ṣebí, ikú kò gbowó,ikú kò gbobì, ikú kọ̀ kò ṣe é tù lójú, ikú wólé ọlá, ikú sọ ilé ọlá di ahoro.
Ìjàmba iná yìí tún dá ẹ̀mí Mẹkáníìkì Olóòtú ìwé Ìròyìn Eagle légbodò lọ́jọ́ yìí.
Dotun Oladapo sọ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán TVC bí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣe bani lọ́kàn jẹ́ gidigidi, nítorí ṣe ni Rotimi Adeleye ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọkọ̀ Toyota ìyàwó rẹ̀ tán ni, Ó sì sọ pé kí n wá yẹ̀ ẹ́ wó pé ó ti n ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mò n gbọ́ tí Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ náà n kígbe ‘Ọkọ̀ yìí kò ní ìjánu!’ a ò tilẹ̀ tètè gbọ́ nítorí fèrèsé wà ní títì pa ṣùgbọ́n nígbà tí a máa fi gbọ́, ó ti pẹ́ jù , ní mo bá n ké tantan fún Rotimi kó kúrò lójú ọ̀nà àmọ́ kò gbọ́, àṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rin ìhòhò wọ ọjà.
Ní bàyìí, àwọn Aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ kàn ti n ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. A gbọ́ pé ènìyàn márùn-ún ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èrò tètè dù ẹ̀mí wọn lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Gbàgádà ṣùgbọ́n àìsàn ni a rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Èlòmìíràn tó tún bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná náà lọ ní ọ̀gbẹ́ni Akintayo Akintoye.
Bákan náà ni iná kan jó ní Abuja tí àwọn èèyàn ò le gbàgbé bọ̀rọ̀. Iná yii kọjá bẹ́ẹ̀. Ìròyìn náà kà báyìí pé;
Ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé afẹ́fẹ́ tí ọkọ̀ le mú sàgbára CNG ló pàdánù ìjánu rẹ̀ ní ìtòsí afárá Karu ní Abuja.
Ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́rú ni ìjàmbá yìí wáyé, ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì lọ kọlu ọkọ̀ mìíràn, kíá ni iná sẹ́yò tí ó sì ràn kárí láàárín ìṣẹ́jú àáyá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí iná yìí ká mọ́ inú ọkọ̀ ni iná yìí ti mú balẹ̀, a kò tíì le sọ ní pàtó iye ènìyàn tí ó ti bá ìsẹ̀lẹ̀ yii rìn.
Nínú fọ́nrán tí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan gbé jáde ni àwọn èèyàn ti ń kígbe tí wọ́n sì ń jó nínú iná náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àti ẹ̀ka mìíràn tọ́rọ̀ kàn dé níbẹ̀.
Iná mìíràn tí ó mìlû tìtì ni èyí tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpò ipo ìrẹsì ti jóná kọjá bẹ́ẹ̀.
Ìròyìn náà kà báyìí pé;
Iná sẹ́yọ ní ọjà ìrẹsì tó wà ní Wurukum ní ìtòsí afárá odò Benue ní Makurdi tíí ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Benue.
Ìrẹsì tó jóná kọjá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà. Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tilẹ̀ ṣaájò àmọ́ ṣe ni iná náà gori ilé fẹjú toto ni, kò ní òun ò run gbogbo àwọn ìsọ̀ ìrẹsì náà.
Ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́jà náà tó pe orúkọ rẹ̀ ní Mercy wí pé ìrẹsì tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni ó jóná nísọ̀ oun pẹ̀lú àwọn irin iṣẹ́ tí wọ́n fi ń pàkúta inú ìrẹsì.
Jeremiah náà wí pé òun kò tilẹ̀ mọ ibi tí òun yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn ọjà òun jáde lòun ṣe ń wòó títí tó fi jóná tán.
Alága ọja Wurukum; Yerva Igyar wí pé àwọn irin iṣẹ́ bíi mẹ́fà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpò ìrẹsì ló jóná keérú.
Bákan náà ni wọ́n wí pé kìí ṣe wáyà iná ló fa iná náà nítorí pé àwọn kò lo iná ọba rárá ní ọjà náà. Wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Hyacinth Alia fún ìrànlọ́wọ́.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn láti Ilorin lórí iná yìí náà ni pé Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn láti Ilorin lórí iná yìí náà ni pé:
Alagbede ni orúkọ ibùdókọ̀ yìí, ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Ìlọrin ló wà, nínú àwọn ọkọ̀ àjàgbé méjìlélógójì tó wà níbẹ̀, mẹ́ta ló jóná kọjá mímọ̀. Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ kólẹ̀-kódọ̀tí kan tó wá kólẹ̀ ló gbaná ni ìta ibùdókọ̀ yìí, kíá ni iná yìí ràn mọ́ àwọn ọkọ̀ inú ibùdókọ̀ yìí tó sì jó mẹ́ta kan éérú.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Hassan Adekunle fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀. Ó wí pé àwọn ta mọ́ra kán tí àwọn gba ìpè náà àwọn sì kojú rẹ̀ ló jẹ́ kó mọ ní ọkọ̀ mẹ́ta tó jóná nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Ìjàmbá iná kìí ṣe ohun tó dára, a kò ní kan àgbákò iná àti aya àti ọmọ o. Àṣẹ.
Discussion about this post