Orílẹ̀-èdè India kan ní òní, ọjọ́ kejìlá, oṣù Igbe nígbà tí ọkọ̀ bàlúù kan tó kó èrò tó lé ní igba já lulẹ̀ tó sì gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Pápákọ̀ òfurufú tó wà ní Ahmedabad ni ọkọ̀ yìí ti gbéra, London ni ó ń lọ àmọ́ kò tó ìṣẹ́jú kan lẹ́yìn tó gbéra ló já lu ilé àwọn dọ́kítà pápákọ̀ òfurufú náà.
Èèyàn kan ṣoṣo ló jáde nínú rẹ̀ láàyè àmọ́ pẹ̀lú àpá ni.
Ìròyìn fi yé wa pé ìjayà ló sẹkú pa ọ̀pọ̀ àwọn èrò náà kó tó di pé ó já gan-an.
Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ni wọ́n ń kí India kú ilédè àwọn èèyàn tó bá ìṣẹlẹ náà rìn.
Láàrin Tinubu àti Nyesom Wike.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe ìlérí fún mínísítà olú ìlú wa; Nyesom Wike pé bí ó bá nífẹ̀ẹ́ àti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ààyè wà fún un nínú ẹgbẹ́ náà.
Ààrẹ wí pé bí Wike bá fi dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwọn yóò jọ náà kọrin bú àwọn alátakò.
Ààrẹ sọ èyí ní ọjọ́ Kejì tí Wike kéde àyípadà orúkọ gbọ̀ngán ìlú tó wà ní Abuja sí orúkọ Bola Ahmed Tinubu.
A gbọ́ pé:
Mínísítà fún Olú ìlú wa; Nyesom Wike ti ṣe àyípadà gbọ̀gán ìlú tó wà ní Abuja tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abuja International Conference Centre sí Bola Ahmed Tinubu International Conference Centre.
Bákan náà ni ó ṣe àyípadà àwọn yàrá ìpàdé tó wà nínú gbọ̀gán náà sí orúkọ àwọn èèkàn òṣèlú ilẹ̀ wa, àwọn náà ni; Kashim Shettima, Tajudeen Abass àti Kekere Ekun.
Níbi ìfilọ́lẹ̀ gbọ̀gán náà tó wáyé lónìí ni Wike ti ṣe ìkéde àyípadà àwọn orúkọ náà, ó wí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ wa fi ọwọ́ sí àwọn àyípadà orúkọ yìí.
Wike wí pé òun kò kàn ṣàdédé yí orúkọ náà padà o, òun ń fẹ́ nǹkan tí yóò mú ìsọ̀kan Nàìjíríà dúró ṣinṣin, àwọn ẹni tí àwọn fi orúkọ wọn sọ àwọn yàrá ìpàdé náà jẹ́ èèkàn èèkàn ní ẹ̀ka ìjọba kọ̀ọ̀kan lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, èyí yóò mú ìsọ̀kan Nàìjíríà dúró ṣinṣin.
Láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn ará ìlú.
Àwọn ará abúlé Ifa Ikot Akpan ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ké gbájarè sí àwọn ọlọ́pàá láti gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń dún mọhurumọ̀ruru mọ́ àwọn.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK kọ ìwé pélébé há fún àwọn ará ìlú, ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé náà ni pé kí àwọn aráàlú náà ó máa múra ìkọlù tó lágbára tí àwọn yóò ṣe sí wọn.
Wọ́n ní àwọn yóò ṣe ìkọlù sí àwọn aráàlú náà nítorí pé wọ́n màá ń yọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn lẹ́nu ní gbogbo ìgbà.
Ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK fi ẹ̀sùn kan àwọn ará ìlú Ifa pé wọ́n ń fi àwọn ọlọ́pàá halẹ̀ mọ́ àwọn wọ́n sì ń yọ àwọn lẹ́nu. Wọ́n ní ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún wá kó àwọn tàbí yọ àwọn lẹ́nu, àwọn èèyàn tí àwọn yóò pa díi ni:
Ọ̀gbẹ́ni Abasiama Eti Eyo, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Offiong Essien, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Etim Ben, Ọ̀gbẹ́ni Eddiong Efiong àti Ọ̀gbẹ́ni Victor Edet Asuquo.
Wọ́n ní àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n ń ta àwọn ọlọ́pàá lólobó nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.
Wọ́n wá fi ìkìlọ̀ kún un pé ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn, gbogbo àwọn tí àwọn dárúkọ náà ni wọn yóò lọ síi nítorí pé ọmọ ìlú Ifa náà ni olórí àwọn, àwọn kò tún gbodò máa bẹ̀rù láàárín ìlú.
Baálẹ̀ abúlé Ifa Ikot Akpan; Ọ̀gbẹ́ni Eteidung Ebong fi ọ̀rọ̀ náà tó kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa Ibom àti Gómìnà Umo Eno láti gba àwọn kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà láti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ní ìlú náà. Ó wí pé òun mọ àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn tí wọ́n dárúkọ sínú ìwé náà ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.
Chidera sẹkú pa alábàágbé rẹ̀.
Chidera Ezeokoe ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekú pa alábàágbé rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rose Awoke.
Abúlé Ezzagu ni ìjọba ìbílẹ̀ Isielu, ìpínlẹ̀ Ebonyi ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀, ẹni ọgọ́ta ọdún ni Rose Awoke lásìkò ikú rẹ̀.
Àlàyé tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi; Joshua Ukandu ṣe ni pé èdè àìyedè kan ló ṣẹlẹ̀ láàrín Chidera àti Rose ni Chidera bá gbé sọ́bìrì tó sì fọ ọ́ mọ́ Rose lórí láìmọye ìgbà.
Rose kú sínú àgbárá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí Chidera fi sílẹ̀ sí tó sì sá lọ. Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Chidera báyìí ó sì ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá
Ní ìpínlẹ̀ Ògùn
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde kan ni a ti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ìmọ̀ ẹ̀rọ, Igbesa ní ìpínlẹ̀ Ogun tí wọ́n de akẹgbẹ́ wọn lóbìnrin mọ́lẹ̀, wọ́n so ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì ń nà án ní ẹgba.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ọmọbìnrin yìí náà ni pé ó gba ọ̀rẹ́kùnrin ọ̀kan nínú wọn.
Wọ́n na ọmọbìnrin yìí tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ẹjẹ̀ fi dà lára rẹ̀ tó sì ní àpá lẹ́yìn.
Wọ́n sọ nínú fọ́nrán náà pé ìyá àwọn mọ̀ nípa ohun tí àwọn ṣe yìí, ẹni tó bá mọ̀ ni kó lọ fi ẹjọ́ sùn, wọ́n sọ pẹ̀lú ìgboyà pé kò sí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fèsì fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ọlọ́pàá Igbesa ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀.
Discussion about this post