Ṣèbí oníkálukú ń ṣe tirẹ̀ lọ́jà lọ́jọ̀ náà ni, àfi gbòlà tí iná sẹ́yọ, iná ọmọ ọ̀rara, kíá ló ti ràn mọ́ àtèèyàn àti dúkìá, nǹkan yan.
Ọjà Talata-Mafara tó wà ní ìpínlẹ̀ Zamfara ni èyí ti ṣẹ̀ láàárọ̀ àná. Àwọn èèyàn ń dúnàá dúrà lọ́wọ́, arákùnrin kan wá ra ẹ̀tù sí ìbọn rẹ̀ lọ́jà náà, ibi tó ti ń ki ìbọn náà ni ó ti bú gbàmù mọ́ ọn lọ́wọ́, kìí wá ṣe pé ó bú nìkan, ó bú mọ́ àwọn ẹ̀tù ìbọn yòókù tó wà nílẹ̀, ni àrá bá ran bọ́ḿbù lọ́wọ́, àfi gbòlà tí iná dé, iná náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó bá nǹkan jẹ́ gan-an.
Àádọta àwọn èèyàn ni wọ́n jóná nínú ìjàmbá yìí, wọ́n farapa gan-an ni tó ṣe pé ilé ìwòsàn tí wọ́n kọ́kọ́ gbé wọn lọ kò le tọ́jú wọn.
Ikọ̀ akọ̀ròyìn kàn sí ilé ìwòsàn ìjọba Talata-Mafara tí wọ́n gbé wọn lọ, àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ wí pé àwọn ti ní kí wọn ó gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Usman Danfodiyo ní Sokoto nítorí pé ó ju ohun tí àwọn le tọ́jú lọ.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé bí àwọn ó ba tiẹ̀ gbìyànjú láti tọ́jú wọn gan-an, àwọn kò ní àwọn irinṣẹ́ tó kúnjú òṣùwọ̀n tí àwọn le lò. Wọ́n wí pé àwọn èèyàn náà farapa gidi gan-an ni kìí ṣe kèremí.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé iná náà kò ní òun kò run gbogbo ọjà, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn panápaná tí wọ́n wá kojú rẹ̀.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Talata-Mafara; Yahaya Yari wí pé òun wà ní Sokoto pẹ̀lú àwọn èèyàn náà àmọ́ ó kọ̀ láti sọ ipò tí wọ́n wà báyìí.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò yọrí sí rere lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
*** *** *** **** *** ** ****
A mú ìròyìn wá fún yín nígbà kan rí pé iná jó ní ọjà Anambra.
Àwọn ọlọ́jà ilé ìkọ́jàsí kan tó wà ní Tambasi, òpópónà Limca ní Idemili ìpínlẹ̀ Anambra pàdánù ọjà tó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà nínú ìjàmbá iná tó sẹ́yọ lóru.
Ohun tó ṣe òkùnfà iná náà kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Okey, ọ̀kan nínú àwọn tí ó ń gbé ní itòsí ilé ìkọ́jàsí náà wí pé iná náà bẹ̀rẹ̀ láti igun kan lára ilé náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tó sì ràn mọ́ gbogbo ilé náà láàrin ìṣẹ́jú àáyá.
Àwọn tí ilé wọn fara ti ilé ìkọ́jàsí yìí sáré kó ẹrù wọn jáde nítorí ìbẹ̀rù pé bí ó bá jó ilé ìkọ́jàsí náà tán ó le náwọ́ gán ilé wọn.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná gbìyànjú láti pa iná náà, lẹ́yìn bíi wákàtí kan tí wọ́n ti kojú rẹ̀ ni wọ́n tó ríi pa.
Ẹni tó ń mójútó àtẹ̀jáde fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Anambra; Chukudi Chiketa wí pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀, lẹ́yìn bíi wákàtí kan, wọ́n rí iná náà pa àmọ́ ṣe ni iná náà tún sẹ́yọ lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀. Wọ́n kó àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ránṣẹ́ síi wọ́n sì jọ pa iná náà lápawọlẹ̀.
Ọdún tó kọjá ni iná jó ní ibi méjì lọ́jọ́ kannáà ní Ìbàdàn.
Ìjàmbá iná tó sẹ́yọ ní ìlú Ìbàdàn ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Ọ̀pẹ, ọdún tó kọjá lé kenkà.
Ọ̀kan wáyé ní Ori-Eru, Idikan ní Ìbàdàn. Aago mẹ́ta òru kọjá ni iná náà bẹ̀rẹ̀ ní ilé alájà méjì náà. Ìyá àgbà, bàbá àgbà àti ọmọọmọ wọn ọkùnrin kan tó wá lo ìsinmi ilé ìwé lọ́dọ̀ wọn ti jóná nínú ìjàmbá iná náà o.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná gbìyànjú lóòótọ́ àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́, eléérú ti sun igi.
Ìjàmbá iná mìíràn wáyé ní ọjà Araromi, Agodi ní ìlú Ìbàdàn kannáà. Aago méjì òru kọjá ni iná náà sẹ́yọ tó sì gorí ilé fẹjú kankan.
Ọjà tó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà ló jóná nínú ìjàmbá náà.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sa ipá wọn, iná náà pọ̀ lápọ̀jù , wọ́n béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ilé iṣẹ́ panápaná kéékèèkèé pé kí wọn ó gbé omi wá nítorí afẹ́fẹ́ panápaná kò ká iná náà.
Nígbà tí àwọn panápaná ń gbìyànjú láti pa iná, àwọn jàǹdùkú ti ya wọ inú ọjà náà tí wọ́n sì ti ń jí àwọn ọjà ọlọ́jà gbé lọ.
Olùdarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́; Akinyemi Akinyinka ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn jàǹdùkú, eṣinṣin ò kọ ikú ti ya wọ inú ọjà o, wọ́n sì ti ń jí àwọn ọjà gbé sá lọ.
Akinyemi béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn panápaná àdúgbò pé kí wọn ó gbé omi wá sí ọjà Araromi náà nítorí iná náà pọ̀ ju agbára afẹ́fẹ́ ìpaná lọ.