Ìjà burúkú kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin Olamide àti ìyàwó rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun, irin tó gbé sókè pé kó fi fọ́ orí ìyàwó rẹ̀ báyìí, ìyàwó yẹ irin náà ó sì bá ọmọ wọn, ọmọ ọdún kan débi pé ojú ẹsẹ̀ náà ni ọmọ náà dákẹ́.
Agbègbè Elega ní Abeokuta tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun ni èyí ti ṣẹ̀ láàrin Olamide àti ìyàwó rẹ̀. Òru ọjọ́ Àbámẹ́ta mọ́jú ọjọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀ yìí ni ìjà náà bẹ́ sílẹ̀ láàrin tọkọtaya yìí, ohun tó ṣe okùnfà ìjà náà gan-an ní pàtó kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò yìí àmọ́ àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu arábìnrin Bolatito tó jẹ́ alábàágbé wọn ni pé òun ń gbọ́ tí ìyàwó Olamide ń pariwo kíkan kíkan lóru ọjọ́ náà pé ọkọ òun ti pa ọmọ òun o.
Nígbà tí òun dé inú yàrá wọn, òun bá Ayinde (ọmọ náà) tó ń pòfóló, ìyá rẹ̀ wí pé irin tí bàbá rẹ̀ fi máa ń gbé ìwọ̀n ló fọ́ mọ́ ọmọ náà lórí. Bolatito ní òun sá jáde lóru náà láti wá ọkọ̀ tí yóò gbé àwọn lọ sí ilé ìwòsàn, ó sì rí ẹnìkan tó gbà láti gbé wọn lọ.
Ilé ìwòsàn Trinity tó súnmọ́ wọn jù náà ni wọ́n gbé ọmọ náà lọ, àwọn dọ́kítà wí pé ọmọ náà ti kú wọ́n sì gbé e padà sílé. Nígbà tí wọ́n délé, ọmọ náà ń dún lọ́hùnlọ́hùn-ún fíntínfíntín ni wọ́n bá tún gbé e lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn, ibẹ̀ ni àwọn dọ́kítà ti wá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà ti kú pátápátá.
Gbogbo àsìkò tí wọ́n fi ń gbé ọmọ yìí kiri ni Olamide tó jẹ́ bàbá rẹ̀ ti sá lọ tèfètèfè, kò sí ẹni tó gbúròó rẹ̀ di àsìkò yìí.
Irú èèyàn wo ni Olamide bàbá Ayinde?
Àwọn ará ilé fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé Olamide kìí ṣe ẹran rírọ̀, wọ́n ní kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa lu ìyàwó rẹ̀ náà, kódà, oyún tí obìnrin náà kọ́kọ́ ní fún un, ẹ̀ṣẹ́ ló fi gbọ̀n ọ́n yọ níkùn rẹ̀.
Alága adúgbò wọn; Ọ̀gbẹ́ni Ramoni Adegbola náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nípa irú èèyàn tí Olamide jẹ́. Ó wí pé gbogbo òògùn olóró ni Olamide máa ń mu bí omi, kò fẹ́rẹ̀ sí irú òògùn olóró kan tí kò sí nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Ramoni wí pé òun sáré dé ibẹ̀ ni lóru tí wọ́n ránṣẹ́ pe òun àwọn sì jọ gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ àti èkejì ni níbi tí wọ́n ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà ti dágbére fáyé.
Àlàyé alága Adegbola tẹ̀síwájú pé Olamide kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa lu ìyàwó rẹ̀ náà ní ìlù bàrà, bí ó bá ti gba gbogbo òògùn olóró rẹ̀ sára tán, lílù bíi aṣọ òfì ni ó máa ń fi ìyàwó rẹ̀ ṣe. Wọ́n ní ó lu obìnrin yìí lọ́jọ́ kan tó sì dákú tó ṣe pé gbogbo ará àdúgbò ló ṣara jọ láti jíi lọ́jọ́ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Omolola Odutola. Wọ́n wí pé àwọn ti gba ìfisùn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀.
Ìròyìn mìíràn tí a fẹ́ fi tóo yín létí ni ti Rìpẹ́tọ̀ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ara rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí bí Maxwell Zubu ṣe yìnbọn pa ara rẹ̀. Ọlọ́pàá ni Maxwell, Rìpẹ́tọ̀ sì ni pẹ̀lú, ohun tó mú un yìnbọn pa ara rẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lé lórí báyìí.
Maxwell ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ fún alága ìjọba ìbílẹ̀ Port Harcourt tẹ́lẹ̀rí.
Agbegbe Eagle Island ní Port Harcourt, ìpínlẹ̀ Rivers ni èyí ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Igbe tí a wà yìí. Kò sí ẹni tó le sọ ohun tí ó le mú Maxwell yìnbọn pa ara rẹ̀ tó fi dé orí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.
Ìròyìn ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá láti àgọ́ Azikwe ti dé ibi tó pa ara rẹ̀ sí láti ṣe ọ̀fintótó. Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers; Grace Iringe-Koko fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn àmọ́ kò wí nǹkankan nípa rẹ̀.
Bákan náà la gbọ́ pé wọ́n rí òkú àwọn èèyàn méjì ní Idimu, ìpínlẹ̀ Èkó. Ìròyìn fi yé wa pé òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni wọ́n pa àwọn èèyàn náà kí àwọn èèyàn tó jí rí wọn láàarọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Lanre Ajao, ẹni tó jẹ́ ará àdúgbò náà wí pé Baba ọjà ni àwọn ń pe ọ̀kan nínú àwọn òkú náà, ìyẹn èyí tí orí rẹ̀ ṣì wà lọ́rùn rẹ̀, ó wí pé ó nira láti dá èkejì tí kò ní orí náà mọ̀.
Lanre wí pé òdú ni bàbá ọjà ní agbègbè náà, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ aládàáni ló máa ń sọ́nà fún nínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ, wọ́n ní ó ṣì sọ́nà fún ọkọ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Jamiu Raji náà bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó wí pé ìṣọwọ́ pa àwọn èèyàn náà tọ́ka sí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn. O ní kò sí ìjà tàbí fàǹfà kankan ló jẹ́ kí òun ròó bẹ́ẹ̀ àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kò ṣẹlẹ̀ rí ní àdúgbò náà. Bákan náà ló ṣe ìdámọ̀ ẹnìkejì bíi ará àdúgbò náà.
Àwọn akọ̀ròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó lé ní wákàtí mẹ́wàá kí àwọn ọlọ́pàá tó dé ibẹ̀, ẹnìkan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun wí pé àwọn gba owó lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn òkú náà kí wọ́n tó jẹ́ kí wọ́n gbé wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò tíì fèsì sí ibéèrè àwọn oníròyin lórí pé ṣé lóòótọ́ ni wọ́n gba owó náà.
Discussion about this post