Ilé ẹjọ́ kéréje tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Sokoto ti pàṣẹ kí wọn ó dá Hamdiyya Sidi Shariff dùbúlẹ̀ kí wọn ó fún un ní ẹgba méjìlá, lẹ́yìn náà ni kí wọn ó sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n fún odidi ọdún méjì gbáko. Adájọ́ Faruk Umar ló gbé ìgbẹ́jọ́ yìí kalẹ̀ lórì ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Hamdiyya pé ó tàbùkù Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto àti pé ohun tó kọ nípa rẹ̀ le da àlàáfíà ìlú rú.
Ta ni Hamdiyya Sidi Shariff?
Hamdiyya jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún méjìdínlógún, ó jẹ́ ajìjàǹgbara lórí ìkànnì ayélujára. Ìpínlẹ̀ Sokoto ni ó ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀. Àwọn ohun tó máa ń kọ nípa rẹ̀ náà ni ipò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ Sokoto àti àwọn àdojúkọ wọn, pàápàá àwọn obìnrin.
Ní ọjọ́ kan, Hamdiyya ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí àwọn olè dá a lọ́nà, wọ́n lù ú lálùbami kí wọ́n tó tì í bọ́lẹ̀ láti inú kẹ̀kẹ́ maruwa lórí eré lẹ́yìn tí wọ́n ti gba gbogbo ohun tó wà lára rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mú kí Hamdiyya ó tún tẹpẹlẹ mọ́ àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀. Èyí tó kó o sí wàhálà yìí ni fọ́nrán tó ṣe ní èyí tó ti ké sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ohun tó sọ nínú fọ́nrán náà ni wí pé Àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọlé jáde láìsí ìdíwọ́ kankan, àrà tó wù wọ́n ni wọ́n ń dá tọ́sàn tòru sì ni wọ́n fi ń wọ ìlú wá ṣe ọṣẹ́ ọwọ́ wọn. Hamdiyya wí pé àwọn obìnrin tí wọ́n ti sọ di aláìlọ́kọ mọ́ ń jìyà kiri abúlé ni, bí wọ́n bá tún wá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí olú ìlú ní àwọn ibùdó aláìnílé, níṣe ni wọ́n ń bá wọn sùn ní tìpátìkúùkú níbẹ̀’
Hamdiyya dárúkọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu nínú fọ́nrán náà pé kó wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ẹ̀sùn tí ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto fi kan Hamdiyya Sidi Shariff.
Ilé ẹjọ́ Sharia ni wọ́n kọ́kọ́ gbé Hamdiyya lọ, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé ó bú Gómìnà Ahmed Aliyu ó sì gbìyànjú láti kọ ẹ̀yìn àwọn èèyàn sí Gómìnà náà. Wọ́n ní ohun tó kọ le da omi àlàáfíà ìlú rú.
Ẹjọ́ yìí pe àkíyèsí àwọn àjọ àgbáyé wọ́n sì bèèrè fún ìgbẹ́jọ́ òdodo. Èyí ló mú kí ẉọn ó tari ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ ìjọba.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Hamdiyya ní ilé ẹjọ́ ìjọba ni pé ó bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Sokoto ní èyí tó tàbùkù ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto. Láti inú oṣù Bélú ọdún tó kọjá ni ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní àǹfààní àtilọ ilé.
Bí Hamdiyya ṣe ń jìyà ní àtìmọ́lé ni agbẹjọ́rò rẹ̀ náà; Abba Hikima ń kojú oríṣìí àdánwò níta. Onírúurú ìpè ni Hikima ń gbà lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kó jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà bí kò bá fẹ́ jásẹ̀, oríṣìí àwọn èèyàn ló ń ká a mọ́lé láti dúnkokò mọ́ ọn. Bákan náà ni wọ́n ń lọ bá a ní ilé ìtura tó fara pamọ́ sí láti halẹ̀ mọ́ ọn.
Níbi tó le dé, Hikima ní láti gba àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí wọ́n dúró tìkanratìkanra lọ sí ilé ẹjọ́ ní ìgbẹ́jọ́ tó kọjá. Ó hàn gbangba gbàǹgbà pé ẹ̀mí Hikima ò dè ní Sokoto.
Àjọ Amnesty International Nigeria ti dá sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n bèèrè fún ìwádìí àti ìdájọ́ òdodo lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Hamdiyya láti adarí wọn; Isa Sanusi. Bákan náà ni wón tàbùkù ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Hamdiyya pé ó bú Gómìnà Ahmed Aliyu, wọ́n ní èyí lòdì sí òfin.
Àjọ Amnesty International Nigeria wí pé ìdúnkokò mọ́ Hikima tó jẹ́ agbẹjọ́rò Hamdiyya jẹ́ àṣìlò agbára pátápátá. Wọ́n wí pé èyí tí ìjọba Sokoto ó fi wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ lóòótó bí Hamdiyya ṣe sọ, níṣe ni wọ́n ń bá ọmọ náà ṣẹjọ́ tí wọ́n tún fẹ́ pa agbẹjọ́rò rẹ̀.
Àjọ Amnesty International Nigeria kín ohun tí Hamdiyya sọ lẹ́yìn, wọ́n ní ojoojúmọ́ ni àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọ àwọn àbúlé ní Sokoto tí wọ́n ń ṣe àwọn èèyàn báṣubàṣu tí kò sì sí ẹni tó ń dá wọn lọ́wọ́ kọ́. Bí wọ́n ṣe ń dáná sun ilé ni wọ́n ń pa àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń jí àwọn obìnrin àti ọmọdé gbé lọ.
Ìdásí àjọ Amnesty International Nigeria yìí ló jẹ́ kí ilé ẹjọ́ ó gbà kí wọn ó gba onídùúró rẹ̀ pẹ̀lú àádọ́ta ẹgbẹ̀rún náírà àmọ́ ẹjọ́ kò tíì parí.
Ìhà tí àwọn èèyàn kọ sí ẹjọ́ Hamdiya Sidi Shariff.
Oríṣìí ìhà ni àwọn kọ sí èyí lórí ìtàkùn ayélujára, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló tàbùkù ohun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto ṣe yìí. Lára àwọn ohun tí wọ́n kọ ni ‘Báwo ni fífi èrò ọkàn ẹni hàn nípa ọ̀ràn tó ń lọ nílùú ṣe jẹ́ ọ̀ràn dídá nígbà tí ọ̀ràn náà gan-an tí àwọn ọ̀daràn ń dá kìí ṣe ọ̀ràn lójú ìjọba? Kín ni ìdí tí ìjọba Sokoto fi wí pé ohun tí Hamdiyya kọ le da omi àlàáfíà rú tí wọ́n sì fi àwọn tió ń da omi àlàáfíà rú gan-an sílẹ̀?’
Ẹlòmíràn kọ ọ́ pé ‘ó jẹ́ ohun tó burú pé a bá ara wa ní irú ipò báyìí lọ́wọ́ nínú ìṣejọba alágbádá, bí ó bá jẹ́ ológun ni irú Gómìnà yìí, kín ni kò bá dán wò ná?’
Ẹnìkan náà kọ ọ́ pé ‘òfin Sharia tí wọ́n fẹ́ náà ni wọ́n rí yẹn lójú páálí’
Discussion about this post