Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní òní, Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ yìí ni gbogbo wọn ó di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lógidi. Kí a máa retí ìsọdọ̀tun ní ìpínlẹ̀ Delta ló kù báyìí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn olóṣèlú máa kọ ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn àmọ èyí kàmọ̀mọ̀, gbogbo ìlú lẹ́ẹ̀kan náà! Ó pọ̀.
Ìkéde ìṣípòpadà yìí jáde ní ọjọ́ kejì tí wọ́n kéde ikú olùbádámọ̀ràn Gómìnà Sheriff lórí okòwò; Olóyè Love Shimite.
A gbọ́ pé A gbọ́ pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti pàṣẹ kí ìwádìí tó jinlẹ̀ ó wáyé lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú Love Shimite. Ìdí ni pé ọkọ Love Shimite sá tọ àwọn ọlọ́pàá pé ní kété tí ìyàwó òun kú ni àwọn ẹbí rẹ̀ ti fi ẹ̀sùn kan òun tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ òun pé òun lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé ọkọ Shimite pamọ́ nítorí bí àwọn ẹbí ìyàwó rẹ̀ ó bá lọ káa mọ́lé.
Àlàye tí a rí gbà lẹ́nu Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ni pé Olóyè Love Shimite dágbére fáyé lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ. Ọkọ rẹ̀ ló gbé e lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí àwọn dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti kú.
Àwọn ẹbí Love Shimite kọ̀ láti gbà pé ọmọ wọn ṣe àìsàn ni, wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọkọ rẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ikú rẹ̀ wọ́n sì lọ fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò ṣe ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí àwọn ẹbí Love Shimite fi kan ọkọ rẹ̀ yìí, àmọ́ ní báyìí, ọkọ rẹ̀ wà ní ọ̀dọ̀ àwọn nítorí kí wọ́n má ba à ṣe é ní ìjàm̀bá.
Olóyè Love Shimite kò ní àǹfààní àti bá Gómìnà Sheriff ṣèjọba pẹ́, ikú ti yọ ọwọ́ rẹ̀ láwo láìpé ọjọ́.
Ìròyìn mìíràn tí a fẹ́ fi tóo yín létí ni ti ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kano gbé kalẹ̀ lónìí. Ṣebí ẹ mọ̀ pé ìkànnì wa náà ni ẹ ó toi rí ojúlówó ìròyìn òòjọ́ tó ń gbóná fẹlifẹli láìsí àbùlà.
A gbọ́ pé Ilé ẹjọ́ gíga tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Kano ti dájọ́ ikú fún Sagiru Rijiyar-Zaki, ẹni ọdún méjìlélógún lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Rijiyar-Zaki náà ni pé ó gún ìyàwó bàbá rẹ̀; Rabiatu Sagir lọ́bẹ pa ó sì tún fi ìbòrí fún àbúrò rẹ̀; Munawara lọ́rùn pa.
Adájọ́ Amina Adamu-Aliyu wí pé gbogbo atótónu àti ẹ̀rí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Rijiyar-Zaki jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀.
Àlàyé tí a rí gbà lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ní pàtó ni pé ní ọjọ́ keje, oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún 2023, èdè àìyedè kan wáyé láàrin Rijiyar-Zaki àti ìyàwó bàbá rẹ̀, ọmọ ìyàwó bàbá rẹ̀ yìí tó jẹ́ àbúrò rẹ̀ sì gbè lẹ́yìn ìyá rẹ̀.
Nígbà tó di alẹ́ tí gbogbo wọn wọlé sùn tán, Rijiyar-Zaki mú ọbẹ tọ ìyàwó bàbá rẹ̀ yìí; Rabiatu lọ ó sì gún un láyà títí tó fi kú. Lẹ́yìn náà ni ó fi ìbòrí fún Munawara tó jẹ́ ọmọ Rabiatu lọ́rùn pa.
Rijiyar-Zaki ní òun kò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn yìí àmọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀; Amòfin Mubarak Abubakar kò ní àwọn ẹ̀rí tó le tako àwọn ẹ̀rí agbẹjọ́rò ìjọba tó jẹ́ olùpẹjọ́. Adájọ́ Amina Adamu-Aliyu wí pé àwọn ẹ̀rí olùpẹjọ́ àti àwọn ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n jẹ́rìí sí i fìdí ẹ̀ múlẹ̀ gbangba gbàǹgbà pé ó jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà.
Ẹ má jìnnà sí ìkànnì wa fún àkọtun ìròyìn.
Discussion about this post