Alága ìjọba ìbílẹ̀ Hong ní ìpínlẹ̀ Adamawa; Usman Wa’anganda bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní agbègbè rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ méjì síra. Ó wí pé àwọn èèyàn mẹ́tàdínlógun ni àwọn agbésùnmọ̀mí ti pa lápapọ̀ láàrín ọ̀sẹ̀ méjì síra.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Usman wí pé àwọn ọdẹ mẹ́wàá ni wọ́n pa lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní abúlé Kopre. Nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìnlélọgún, oṣù Igbe yìí ni ìkọlù náà wáyé.
Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n pa yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni wọ́n dáná sun tí àwọn èèyàn sì wà nínú ìbẹ̀rùbojo. Usman ní òun gan-an ò le fi ojú ba oorun láti ìgbà yìí.
Ó wí pé àwọn agbésùnmọ̀mí máa ń wọ abúlé Kopre lóòrèkóòrè nítorí pé ó pààlà pẹ̀lú igbó Sambisa ní èyí tó mú un rọrùn fún wọn láti wọlé jáde.
Usman tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ nìkan ni àwọn ní ní aláàbò, kò sí ológun kankan ní ìtòsí abúlé náà, àwọn ọlọ́pàá tó súnmọ́ àwọn kìí dáhùn bí àwọn bá ránṣẹ́ pè wọ́n. Ó ní ó bani lọ́kàn jẹ́ gidi. Usman rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Adamawa láti da àwọn ọmọ ológun sí abúlé náà kí àwọn ó le padà sí oko.
Abúlé Kopre ni ìlú akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀rí; Mustapha. Àwọn ológun a máa dáàbò bo abúlé náà láti ibùdó Garaha tí kò jìnnà sí Kopre àmọ́ lọ́gán tí Mustapha kúrò nípò ni wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ológun náà kúrò tí ibùdó náà sì ṣófo.
Àwọn ará abúlé Kopre ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí tó ń fi ojoojúmọ́ pa wọ́n bíi adìyẹ. Wọ́n ní inú fu àyà fu ni àwọn wà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni wọ́n le ṣe ìkọlù sí àwọn.
Ìkọlù èyí wáyé lẹ́yìn èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Plateau tí àwọn èèyàn náà kò tíì rán oró rẹ̀ tán.
Ìkọlù tó wáyé ní Plateau léraléra lọ́sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí, abúlé bíi mẹ́ta ló fẹ́rẹ̀ run tán, ó burú débi pé wọn kò le sin àwọn èèyàn náà bó ti yẹ, wọ́n sin gbogbo wọn pọ̀ sí ojú kan ni. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Abúlé Zikke gbóná janjan nígbà tí àwọn agbébọn bá wọn lálejò. Ìjọba ìbílẹ̀ Bassa ni abúlé Zikke wà ní Jos tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau.
Òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn náà dé sí abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi ọgọ́rin wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìkọlù yìí tún jẹ́ ọ̀tun lẹ́yìn gbogbo àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau kan náà lọ́sẹ̀ kan sẹ́yìn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ run gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Bokko. Àádọ́ta èèyàn ni wọ́n pa lọ́sẹ̀ náà nìkan tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì tún ṣòfò dànù.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì yìí.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti paradà di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Wàyí o, àwọn ará abúlé náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iná gbà jó wọn. Lancaster Akpa; ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta wí pé ẹbí òun mẹ́sàn-án ló bá ìkọlù náà lọ. Akpa wí pé Jos ni òun wà nígbà tí àbúrò òun pe òun pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ó ní òun kò le sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà, ìgbà tí òun pe aago rẹ̀ tí kò lọ mọ́ ni ara ti ń fu òun kó tó wá di pé òun dé bá òkú rẹ̀, ẹ̀gbọ́n òun àti àwọn ọmọ wọn méjéèje.
Akpa wí pé àwọn tí wọ́n wá ṣe ìkọlù náà wọ aṣọ ológun àmọ́ Fulani ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun gbọ́.
Jerry Muwa náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọọmọ òun mẹ́fẹ́ẹ̀fà ni wọ́n dáná sun mọ́lé nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já. Ó ní òun rápálá jáde lóru ọjọ́ náà ni pẹ̀lú ọmọ òun tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà. Muwa wí pé àwọn ọmọ náà jóná di éérú débi pé kò sí ẹran tàbí eegun tí àwọn le sin, àwọn kan kó éérú wọn jọ sínú sàárè kan ni.
ÌGBÉSẸ̀ TÍ GÓMÌNÀ GBÉ
Gómìnà Caleb Mutfwang ti pàṣẹ pé bẹ̀rẹ̀ láti òní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, ọṣù Igbe, ọdun yìí, kò gbọdọ̀ sí dída ẹran màlúù ní alẹ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọkọ̀ kó màlúù lẹ́yìn aago méje alẹ́. Bákan náà ni ọ̀kadà kò gbọdọ̀ rìn lẹ́yìn aago méje alẹ́ di aago mẹ́fà àárọ̀.
Gómìnà Caleb ṣe ìlérí pé gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù náà ni kò ní mú un jẹ nítorí pé gbogbo wọn ni àwọn yóò ṣà lọ́kọ̀ọ̀kan.
Títí di àsìkò yìí, a kò gbọ́ nǹkan nípa àwọn tó ṣe ìkọlù náà àti ìlérí tí Gómìnà ṣe.
Discussion about this post