Ẹ LỌ FỌKÀN BALẸ̀! : orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu ti sọ̀rọ̀ sókè láàárọ̀ yìí, ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrin, oṣù Ògún.
Ohun tí ààrẹ sọ náà ni pé kí a ṣe ara wa lóṣùṣù ọ̀wọ̀, kí a má fi ààyè gbà àwọn ọ̀tá tí wọn kò fẹ́ ìlọsíwájú ìlú làti dá rúdurùdu sílẹ̀.
Èyí wáyé làtàrí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kìíní oṣù yìí tí ò sì ti ń la ìjàngbọ̀n lọ láwọn apá ibìkan nílẹ̀ yìí.
Ààrẹ ti wá pè fún iṣọ̀kan àti ìfọwọ́sọ́pọ̀ gbogbo àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí pátá porogodo pé kí a fún ìjọba rẹ̀ láàyè àti wa ọkọ̀ Nàìjíríà dé èbúté ògo.
Ó ní ká má gbàgbé pé ó ti pẹ́ ọ̀nà sì ti jìn tí ọkọ̀ ojú omi Nàìjíríà ti ń ṣebí èyí tí yóò rì làtàrí ìṣejọba burukú àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, gbogbo ipá ni ìjọba òun yóò sà láti mú Nàìjíríà dé ilẹ̀ ìlèrí.