Ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ké tantan pé kí àwọn èèyàn ipinle Osun má bẹ̀rù àtilọ dìbò lọ́jọ́ àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejì ọdún yìí, 2025.
Ó ní àwọn ti ṣètò ààbò ní sẹpẹ́ fún ìdìbò náà, ṣáájú ìdìbò ; lákòókò ìdìbò àti lẹ́yìn ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo nípìn-ínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Agbẹnusọ wọn, ìyẹn Arábìnrin Yẹ́misí Ọ̀pálọlá ló sọ bẹ́ẹ̀.
Nínú Ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nu-wò látọ̀dọ̀ àwọn oníròyin ní ìlú Òṣogbo lọ́jọ́ Ọjọ́rú tó kọjá-19/02/25, Arábìnrin Ọ̀pálọlá ní ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá tí ṣètò àwọn elétò ààbò láti rí i pé ètò ìdìbò náà lọ láìsí akùdé. ‘Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, ọ̀gá Ọlọ́pàá yán-án-yán-án, Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun ti pèsè àwọn Ọlọ́pàá kògbérèégbè ní ànító àti àníṣẹ́kù sí Ìpínlẹ̀ yìí láti pèsè ààbò ṣáájú àti ní àkókò ìdìbò.
‘ Àwọn kan yóò máa pààrà ojú pópó láti rí i pé kò sí ìwà jàǹdùkú àti àtakò kankan bó ti wù ó mọ’. Arábìnrin Ọ̀pálọlá ké sí gbogbo àwọn olùdìbò tó ní káàdì ìdìbò lọ́wọ́ kí wọ́n jáde tán láti wá ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí olùdìbò lọ́jọ́ ìdìbò náà.
Ó tilẹ̀ tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má fòyà láti jáde wá kópa nínú ètò ìdìbò náà, àwọn ti pèsè ààbò tó dájú fún gbogbo àwọn olùdìbò àti àwọn àjọ elétò ìdìbò.
Ìdìbò síjọba ìbílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun yóò wáyé ní ọjọ́ Sátidé tó ń bọ̀, ìyẹn ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejì ọdún yìí, 2025, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣètò rẹ̀.
Ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí jáde láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí àwọn lájọlájọ, ikọ̀-ikọ̀ nàka àbùkù sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá láìyọ ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá sílẹ̀ pé àwọn ló ṣe ègvè fún rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ náà, ṣé ọ̀nà àti tún ìwà wọn ṣe ni èyí?