BOBRISKY TI KÚRÒ LỌGBA ẸWỌN KIRIKIRI TO WA. Iroyin to tẹ ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ lọwọ sọ pe gbajumọ ori itakun ayelujara, Idris Okuneye ti ọpọ eya mọ si Bobrisky ti gbominira lọgba ẹwọn Kirikiri to wa ni ipinlẹ Eko.
Adajọ Abimbola Awogboro ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Eko lo sọ Bobrisky si ẹwọn oṣu mẹfa gbáko pẹlu iṣẹ asekara laisi anfani owó ìtanràn sisan lori ẹsun pe o ṣe owo naira ni iṣekuṣe.
Ajọ to n gbógun ti ṣiṣe owó ilu kumọkumọ EFCC lo gbe Bobrisky lọ ile ẹjọ, to sí ka ẹsùn pe ọ tabuku owó Naira nibi to ti n na owo loju agbo.
https://www.bbc.com/yoruba/articles/ce311zekypdo
https://iweiroyinyoruba.com/irin-ajo-egberun-maili-bere-pelu-igbese-kan-%e1%b9%a3o%e1%b9%a3o/
Aarọ ọjọ Aje Monday ọjọ kaarun osù kẹjọ ọdún 2024 taa wa ninu rẹ yìí ni fidio kan eyi ti Bobrisky ati Eniola Ajao wa ninu rẹ lu ori ayelujara pa paapa julọ oju opo twitter to ti di X ni sin.
Bobrisky sọ ninu fidio naa pe ‘’Mo ti ṣafẹri ẹyin ololufẹ mi gidigidi.
Mi o si le duro lati ri gbogbo yin pada ki n si bẹrẹ si n fun yin ni awọn nkan ti mo maa n fun yin tẹlẹ.