Ọmọ odún mẹ́rìnlá kan tí a kò ní àǹfààní àtidárúkọ rẹ̀ ti sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ kúrò nílé ọkọ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Taraba. Ìpínlẹ̀ Gombe ni ó lọ fi ara pamọ́ sí. Nígbà tí àwọn tí ọkọ rẹ̀ dẹ síta ṣe àwári rẹ̀ tí wọ́n sì fi òfin Sharia gbé e ni ìjọba ìpínlẹ̀ Gombe dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Kọmíṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ti ìpínlẹ̀ Gombe; Asmau Iganus ló ṣe elégbè fún ọmọ náà. Ó wí pé òun kò ní gbà kí ọmọ náà ó padà sí ilé ọkọ rẹ̀, ìwé tó wù ú láti kà ni òun yóò ṣe ètò rẹ̀ fún un. Arábìnrin Asmau ní òun ṣetán àti tẹ̀lé ọmọ yìí lọ sí Taraba láti fagi lé ẹjọ́ Sharia tí wọ́n pè tako ọmọ yìí.
Àlàyé tí ọmọ yìí ṣe ni pé bàbábàbá òun ló lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí òun láti fi òun fún ọkọ, ó ní òun ni ìyàwó kẹta nílé ọkọ òun, gbogbo ìgbà ni ó máa ń fi ipá bá òun lájọṣepọ̀ tí yóò so ọwọ́ òun méjéèjì mọ́ ìbùsùn, nígbà mìíràn, yóò pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọlé kí wọn ó di òun mú tó bá ti fẹ́ bá òun lájọṣepọ̀ tìpátìkúùkú.
Gbogbo ọrùn ọwọ́ rẹ̀ ló ti dégbò látàrí ojú okùn, ó ní òun kò le fi ara rọ́ èyí mọ́ àti pé ìwé ni òun fẹ́ kà ni òun ṣe sá kúrò níbẹ̀. Arábìin Asmau fún ọmọ yìí ní àwọn ohun jíjẹ, aṣọ àti àwọn ohun ìdáná.
Ọmọ yìí wí pé inú òun dùn fún bí ìjọba ìpínlẹ̀ Gombe ṣe tẹ́wọ́ gba òun yìí, ó ní òun ṣetán àti kọjú mọ́ ìwé òun nítorí pé lẹ́yìn tí òun parí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni àwọn òbí òun ti dá ètò ẹ̀kọ́ òun dúró.
Ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Zaliha Shuaibu ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ní Kaduna lórí ẹ̀sùn pé ó fún ọmọ orogún rẹ̀ ní ásíìdì mu.
Ọmọ oṣù mẹ́ta ni ọmọ náà, Maryam Ibrahim ni orúkọ orogún rẹ̀ tó jẹ́ ìyá ọmọ yìí. Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ báyìí pé; lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù Èbìbí tí a wà yìí, Maryam tẹ́ ọmọ rẹ̀ sí orí ìbùsùn ó sì lọ wẹ̀, nígbà tó dé, ó bá ọmọ náà lọ́wọ́ ìyálé rẹ̀; Zaliha. Zaliha gbé ọmọ Maryam fún un ó sì bọ́ síta.
Maryam ṣe àlàyé pé nígbà tí òun gba ọmọ náà lọ́wọ́ Zaliha, òun ríi pé ó ń po ọṣẹ lẹ́nu, àpá sì wà ní ọrùn rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà ń fi ìrora hàn ni ó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ ọmọ náà kú sí ilé ìwòsàn lọ́jọ́ náà. Àyẹ̀wò àwọn dọ́kítà ló fi hàn pé asíìdì ni ọmọ náà mu tó sì rẹ́ gbogbo ìfun rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Maryam fi ẹ̀sùn kan ìyálé rẹ̀; Zaliha pé òun ló fún ọmọ náà ní ásíìdì mu. Zaliha jẹ́wọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá pé lóòótọ́ ni òun fún ọmọ náà ní ásíìdì mu, ó ní òun àti àbúrò ọkọ òun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lawal Muhammad ni àwọn jọ rọ ọmọ náà ní ásíìdì.
Lawal Muhammad ti fi ẹsẹ̀ fẹ́ báyìí àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti ń wá a. Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna; Rabiu Muhammad ṣe ìlérí pé ìdájọ́ òdodo yóò wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ọlọ́kadà kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Wasiu Babatunde Adeniran ni àgbàrá òjò ti wọ́ lọ pẹ̀lú ọ̀kadà rẹ̀ báyìí. Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ogúnjọ́, oṣù yìí ni òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá náà rọ̀ tó sì wọ́ Wasiu pẹ̀lú ọ̀kadà rẹ̀ lọ ní Alákùkọ, àti ìgbà náà ni wọ́n ti ń wá a kí wọ́n tó wá rí òkú rẹ̀ ní àná, Ọjọ́rú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn, Benjamin Hundeyin pé àwọn ti rí ọ̀kadà Wasiu àwọn sì ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ìgbókùúsì. Ẹni ọgọ́ta ọdún ni Wasiu lásìkò ikú rẹ̀.
Ní ìpínlẹ̀ Ogun kan náà.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń ṣe ìdánwò àṣekágbá oníwèé mẹ́wàá WAEC lọ́wọ́ ni ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ̀ pa báyìí ní ìpínlẹ̀ Ogun. Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama Seico tó wà ní Ikangba ní Ijebu-Ode ń bọ̀ láti ilé ìwé lẹ́yìn ìdánwò ọjọ́ Ẹtì, inú wọn ń dùn wọ́n sì mú ìwé ìbéèrè ìdánwò náà lọ́wọ́ nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré tó sì wọ àárín wọn.
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan ló tẹ̀ pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ó ṣe àwọn mìíràn léṣe. Ọ̀gbẹ́ni Eko Nicholas, ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé péo ọkọ̀ àjàgbé náà pàdánù ìjánu rẹ̀ ní òpópónà Molipa tó sì já wọ àárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kó tó wá lọ fi orí sọ ọgbà ilé ìjọsìn ìràpadà tó wà ní ibẹ̀.
Nicholas wí pé òun kò le sọ pàtó òun tó mú kí ọkọ̀ náà ó pàdánú ìjánu rẹ̀, ó wí pé láti ìgbà tí ìjọba ti tún ọ̀nà náà ṣe tó sì ti já geere ni ìjàm̀bá ti ń wáyé lójú ọ̀nà náà látàrí eré àsápajúdé àwọn awakọ̀. Ó ní òun dá ìjọba lẹ́bi àwọn ìjàm̀bá náà nítorí pé wọn kò ṣe kankéré ìdánà tí yóò mú àdínkù bá eré àsápajúdé sí ọ̀nà náá.
Àlàyé Nicholas tẹ̀síwájú síi pé ó di èèyàn mẹ́fà tí ó ti bá ìjàm̀bá lọ lójú ọ̀nà náà láàrín oṣù Èrèlé tí wọ́n ṣe ọ̀nà náà sí àsìkò yìí. Ó wí pé ilé ìwé pọ̀ ní agbègbè náà ní èyí tó mú kí àwọn ọmọ ó pọ̀ ní ọ̀nà náà. Àwọn onílé agbègbè náà ti kọ ìwé sí ìjọba pé kí wọn ó wá ṣe kankéré ìdánà sí ojú ọ̀nà náà àmọ́ wọn kò tíì rí èsì kankan gbà títí di àsìkò yìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní àwọn gba ìfisùn nípa ìjàm̀bá náà àti akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mìí mì ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀.
Discussion about this post