Ọwọ́ tẹ one-chance – Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi ti tẹ ikọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún tí wọ́n ń fi ọkọ̀ ṣe one-chance ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Kebbi.
Orúkọ wọn ni Abubakar Muhammad, Shehu Ango, Shamsu Daudu, Shuaibu Umar àti Aisha Usmanu. Agbègbè Birnin Kebbi, Kalgo, Jega, Maiyama àti Aliero ni wọ́n ti ń ṣe ọṣẹ́.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi; Bashir Usman fi tó àwọn akọ̀ròyìn létí pé ikọ̀ yìí yóò gbé ọkọ̀ akérò sí ojú pópó wọn yóò sì máa pe èrò sínú rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá dé ojúgbó ni wọn yóò fi ìbọn àti ọ̀bẹ jà wọ́n lólè.
Wọ́n ti fìgbà kan wọ́ mílíọ́nù kan náírà nínú àpò owó ẹnìkan tí wọ́n gbé tí wọ́n sì tún gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ kí wọ́n tó dá a sílẹ̀ – Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.
Lọ́gbọ̀njọ́, oṣù Igbe, wọ́n gbé Shamsiyyah Samalia ní ojú ọ̀na Jega sí Kalgo, wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀, káàdì àpò owó rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án náírà.
Ìwádìí fi hàn pé wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láabi yìí, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti ṣe àgbákò wọn. Ìwàdìí ṣì ń lọ láti mú àwọn ará wọn yòókù tó fi na pápá bora.
Bashir rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ fínní kí wọ́n tó wọ̀ ọ́, ó wí pé ojoojúmọ́ ni àwọn oníṣẹ́ ibi náà ń peleke síi tí wọ́n ń fi ọkọ̀ akérò bojú ṣe àwọn èèyàn lọ́ṣẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n bá gba gbogbo ohun tí wọ́n ní yóò tún pe àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láti san owó ìtúsílẹ̀. – Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi
Kò sí ibi tí ikọ̀ one-chance ò fẹ́rẹ̀ sí mọ́, inú oṣù Ṣẹẹrẹ ọdún yìí ni wọ́n mú àwọn kan náà ní Èkó. A mú ìròyìn náà wá pé:
Àwọn ọlọ́pàá ti mú àwọn afurasí mẹ́rìnlá tí wọ́n jẹ́ ikọ̀ One-chance ní Idimu, ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọn afurasí yìí máa ń ṣiṣẹ́ káàkiri Èkó àmọ́ Idimu ni ibùdó wọn wà, ibẹ̀ ni wọ́n kọ́ ilé kótópó kan sí tí wọ́n ṣe bíi ilédì awo àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ni wọ́n ń jígbé sí ibẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló máa ń kọjá lára ilé yìí tí wọn kò sì fura nítorí wọ́n rò pé ilédì ni. Ọkọ̀ mẹ́fà ni àwọn ẹni yìí ń lò láti ṣe iṣẹ́ wọn.
Wọn yóò gbé àwọn èrò tó ń lọ sí ibi iṣẹ́ àti ibi ọjà wọn ní ìdájì àti ní alẹ́ tí wọ́n bá ń padà bọ̀. Ẹni tí wọ́n gbé tó bá rí owó san yóò gba ìtúsílẹ̀ nígbà tí ẹni tí kò bá rí owó san yóò wà ní ilé náà títí àwọn ẹbí rẹ̀ ó fi rí owó san.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Olohundare Jimoh ló ṣaájú àwọn akọ̀ròyìn lọ sí ilé náà tó sì fi ojú àwọn afurasí náà hàn.
Ó ṣe àlàyé pé ní ìdájí ọjọ́ Àìkú ni àwọn ọlọ́pàá mú mẹ́ta nínú wọn nígbà tí wọ́n ń ṣe àyẹ̀wò àwọn ọkọ̀ tó ń kọjá, wọ́n dá ọkọ̀ wọn dúró wọ́n sì bá ẹni tí wọ́n gbé náà tí ìyà ti pá a lórí, wọ́n mú wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ni wọ́n júwe àwọn ìyókù wọn àti bi tí wọ́n ti ń pàdé.
Demola Adelua ni olórí ikọ̀ yìí, ó ti lé ní ọdún mẹ́jọ tí ó ti ń ṣe é, yàtọ̀ sí ikọ̀ tí wọ́n mú yìí, ikọ̀ mẹ́fà mìíràn ni ó tún ń darí ní Èkó.
Ó ṣe àlàyé pé ìdájí kùtù hàì ni àwọn ọmọṣẹ́ rẹ̀ yóò ti gbé ọkọ̀ jáde, wọn yóò gbé àwọn tó ń jí lọ síbi iṣẹ́ ní ìgboro Èkó, ìdajì ọ̀nà ni wọn yóò ti gba gbogbo owó lọ́wọ́ rẹ̀ kí wọ́n tó já a sílẹ̀ tàbí gbé e lọ sí ibùdó bí kò bá rí owó san. Wọn yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní alẹ́ pátápátá fún àwọn tó bá pẹ́ níta.
Ìdí ni pé ọ̀nà máa ń dá ní àwọn àsìkò yìí àti pé àwọn ọlọ́pàá kìí dé òde lásìkò yìí àfi ọjọ́ tí wọ́n mú wọn náà. Ó tún ṣe àlàyé pé àwọn tí wọ́n máa ń jí lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ Àìkú àti àwọn tó máa ń ti ìṣọ́ òru bọ̀ ló máa ń ṣe àgbákò àwọn jù.
Ọkọ̀ Sienna ni ó pọ̀ jù nínú ọkọ̀ tí wọ́n ń lò náà, ìdí ni pé ó láyè dáadáa bí Adelua ṣe sọ.
Afurasí mìíràn ni Rotimi Adilola jẹ́wọ́ pé Idimu ni ibùdó àwọn wà tí àwọn ti máa ń pàdé tí wọ́n sì máa ń ti àwọn tí kò bá rí owó san mọ́.
Òmíràn ni Amos Ogunna, ó ní òun ló ni ilé náà tí òun sọ di ayédèrú ilédì fún iṣẹ́ náà, òun kìí bá wọn jáde ó kàn ń yá ikọ̀ náà nílé ni òun ló sì máa ń mójútó àwọn tí wọ́n bá kó wá sí ibẹ̀. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún náírà ni owó tirẹ̀ lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá mú wá sí ibẹ̀.
Njoku náà jẹ́wọ́ pé ó ti tó ọdún mẹ́jọ tí òun ti ń ṣiṣẹ́ náà ẹni tí àwọn bá sì gbé gbọdọ̀ san owó kó tụn tó ríta. Ẹni ọgọ́ta ọdún ni Njoku báyìí.
Láti ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ni Tina Willy ti wá darapọ̀ mọ́ ikọ̀ yìí, ó ṣe àlàyé pé lẹ́yìn tí ọkọ̀ rẹ̀ kú tí ìyà bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ òun ni ẹ̀gbọ́n òun mú òun wá darapọ̀ mọ́ ikọ̀ náà. Tina rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọn ó dá òun sílẹ̀, ikú ọkọ òun ló fà á.
Ọ̀kan nínú wọn ti lo oṣù mẹ́rin lẹ́wọ̀n rí lórí ẹ̀sun jìbìtì, òun náà jẹ́ afurasí ikọ̀ one-chance yìí.
Kọmíṣọ́nà Olohundare ṣe ìlérí pé òun yóò mú gbogbo àwọn yòókù tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ yìí, ikọ̀ kan ni wọ́n mú yìí, ó ṣì ku mẹ́fà mìíràn ní abẹ́ Adelua nìkan. Òmíràn nínú wọn gan-an kò gbé ní Èko, wọ́n ń ti ìlú wọn wá ṣe iṣẹ́ náà ni Èkó ni. Ó ní gbogbo wọn ni òun yóò ṣa pátá òun yóò sì ríi pé ètò ààbò Èkó kò mẹ́hẹ.



