Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo ti tẹ ọlọ́pàá kan tó jẹ́ olórí ikọ̀ adigunjalè ẹlẹ́ni mẹ́rin.
Agbègbè Benin ni ọlọ́pàá yìí àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ ti ń ṣọṣẹ́. Ìjínigbé, ìdigunjalè, ìdúnkokò mọ́ni, ìlọ́nilọ́wọ́gbà àti àwọn ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀ ni ìjọba fi kan ọlọ́pàá yìí.
Ọkùnrin kan tí wọ́n jí gbé ni ó ṣe fọ́nrán kan síta, nínú rẹ̀ ló ti ṣe àlàyé pé òun mọ ọ̀kan nínú àwọn mẹ́rin tó jí òun gbé náà dáadáa pé ọlọ́pàá ni.
Ọkùnrin yìí ṣe àlàyé pé wọ́n jí òun gbé, wọ́n na òun, wọ́n gba gbogbo owó inú àpò ilé ìfowópamọ́ rẹ̀ wọ́n sì tún gbé ọkọ̀ rẹ̀ lọ.
Ó wá ṣe àpèjúwe ọlọ́pàá yìí pé òun mọ̀ ọ́n dáadáa pé ọlọ́pàá ni.
Fọ́nrán yìí ló mú kí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ó dìde ńlẹ̀ tí wọ́n sì fi ìjúwe náà tọpinpin ọlọ́pàá yìí, nígbà tí wọ́n yóò mú un, inú ọkọ̀ tí ọkùnrin yìí sọ pé wọ́n gbà lọ́wọ́ òun ni wọ́n ti bá a tó ń jáde lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo; Moses Yamu fi yé wa pé ọlọ́pàá náà àti àwọn mẹ́ta yòókù ti wà ní àhámọ́ àwọn báyìí.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo; Monday Agbonika ti pàṣẹ fún àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ẹ̀sùn náà délẹ̀, ó ṣe ìlérí pé àwọn tí ajere ọ̀rọ̀ náà bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ojú winá òfin.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá náà fi kún un pé irú àwọn ọlọ́pàá báyìí ni ó ń tàbùkù ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, ó ní òun yóò fi eléyìí ṣe àríkọ́gbọ́n.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a máa kọ ìròyìn nípa ìwà ọ̀daràn tí àwọn ọlọ́pàá kan ń hù.
Ní ìpínlẹ̀ Enugu ni wọ́n ti mú ọmọ ìyá méjì tí ọ̀kan jẹ́ ọlọ́pàá tí èkejì rẹ̀ sì jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìrìn àjò IMMIGRATION, ìjínigbé ni àwọn méjèèjì náà lọ ṣe ní Enugu, wọn yóò dá ọkọ̀ dúró lójú ọ̀nà márosẹ̀ wọn yóò sì gbé àwọn èèyàn náà lọ.
Ìgbà tí wọ́n gbé ẹ̀gbọ́n wọn ni àṣírí wọn tú.
Ìròyìn nípa àwọn ọmọ ìyá méjì yìí kà báyìí pé:
Ọmọ ìyá méjì kìí réwèlè ni Yorùbá wí àmọ́ àwọn ọmọ ìyá bíi àwùsá kan ló lẹ̀dí àpò pọ̀ tí wọ́n jí ẹ̀gbọ́n wọn gbé ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Ìròyìn fi yé wa pé Juliet Chukwu àti Ngozi Nancy Chuku lẹ̀dí àpò pọ̀, wọ́n jí ẹ̀gbọ́n wọn; Friday Chukwu gbé.
Juliet Chukwu jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ẹ̀ka NSCDC nígbà tí Ngozi jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìrìn-àjò IMMIGRATION, àwọn méjéèjì gbìmọ̀pọ̀ wọ́n sì gbé ẹ̀gbọ́n wọn; Friday ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Enugu sí Port Harcourt.
Ọgbọ̀n mílíọ́nù náírà ni wọ́n gbà lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n wọn kí wọ́n tó dá a sílẹ̀.
Èyí tó bu wọ́n lọ́wọ́ ni alámòójútó ilé iṣẹ́ China Orienta Mining Company; Amojú ẹ̀rọ ni Dennis Igwe tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà kan náà.
Mílíọ́nù mẹ́wàá náírà ni wọ́n gbà lọ́wọ́ rẹ̀ owó ìtúsílẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ló tọpinpin wọn dé inú ilé kan tí wọ́n ń fara pamọ́ sí bí wọ́n bá ti fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìjínigbé wọn, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n ti ń pín owó lọ́wọ́ wọ́n sì fi òfin mú wọn.
Ìgbà náà ni wọ́n ríi pé ẹṣọ́ aláàbò ni àwọn méjéèjì tí wọ́n sì túbn jẹ́ ọmọ ìyá. Ìwádìí ló fi hàn pé àwọn náà ló gbé ẹ̀gbọ́n wọn lọ́sẹ̀ tó ṣáájú ọ̀sẹ̀ tí wọ́n gbé Dennis Igwe.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Lórí ìjínigbé yìí kan náà, ẹni tí kò rí ẹni tí yóò jíi gbé tún jí ara rẹ̀ gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo nítorí kí ó le gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀.
Azeez náà ni a ń sọ nípa rẹ̀, ìròyìn rẹ̀ lọ báyìí:
Bello Azeez; ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó parọ́ fún àwọn ẹbí rẹ̀ pé wọ́n jí òun gbé.
Lọ́jọ́ kọkànlá, oṣù Ògún yìí, Bello gbéra kúrò ní Ondo, ó dágbére Ìbàdàn fún àwọn ẹbí rẹ̀.
Nígbà tó di alẹ́, ó pe bàbá rẹ̀ pé wọ́n ti jí òun gbé lọ́nà Ìbàdàn kí wọn ó wá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà owó ìtúsílẹ̀.
Bello fi kun un pé inú àpò owó òun ni kí wọn ó san owó náà sí.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ló fura tí wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí, àwọn ọlọ́pàá wá tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ dé Ọ̀wọ̀, ibẹ̀ ló fara pamọ́ sí tó ti ń pè.
Bello jẹ́wọ́ pé òun bèèrè owó lọ́wọ́ bàbá òun láti san gbèsè àmọ́ kò fún òun ni òun ṣe dáa bí ọgbọ́n.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo wí pé Azeez yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti bá ìjínigbé lọ, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gan-an kò lè sọ pàtó iye àwọn èèyàn tí wọ́n ti ṣe àgbákò ìjínigbé yìí.
Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n ko irú ikú àìtọ́jọ́ yìí ni Fish Magnet, ikú rẹ̀ gba omi lójú àwọn èèyàn.
Iroyin ikú rẹ̀ kà báyìí pé:
Ìròyìn tó ba ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn nínú jẹ́ ni ìròyìn ikú ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí àwọn ajínigbé dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò ní ìpínlẹ̀ Anambra.
Ifesinachi Onyekere ni orúkọ ọmọkùnrin yìí, òwò ẹja ni ó ń ṣe.
Ní òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni àwọn ajínigbé náà ya wọ ilé rẹ̀ ní Ezinifite, wọ́n kó o ní pápámọ́ra, wọ́n yin ìbọn fún un lẹ́sẹ̀ kí wọ́n tó fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé e lọ.
Ọjọ́ mẹ́ta ni ó lò ní àkàtà wọn tí wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ ṣeni wọ́n pa á tí wọ́n sì ju òmú rẹ̀ nù sí ẹ̀gbẹ́ títì.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé àwọn ti rí ọkọ̀ Onyekere tí wọ́n fi gbé e lọ àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.





