Olólùfẹ́ da ásíìdì sí ọmọṣẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lára nítorí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ – Obìnrin kan ti wà nílé ìwòsàn báyìí lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́kùnrin ọ̀gá rẹ̀ rán ẹnìkan láti da ásíìdì síi lára. Olorunseunfunmi Awosogbon ni orúkọ obìnrin náà, ó ń ṣiṣẹ́ nílé atúnraṣe kan ní Lekki. Lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Awosogbon lọ sí Lakowe láti ṣiṣẹ́ àmọ́ bí ó ṣe sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ọkùnrin kan sún mọ́ ọn tó sì da ásíìdì síi lára.
Ọ̀gá Awosogbon tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olorunmaye Ifeoluwa ni ẹni náà lérò àti da ásíìdì sí lára àmọ́ ọmọṣẹ́ rẹ̀ ló rán tí ó sì ṣe àgbákò náà.
Ifeoluwa ṣe àlàyé pé ẹnìkan ló kàn sí ilé iṣẹ́ rẹ̀ láti wá túnra ṣe fún un nílé rẹ̀ ní Lakowe, wọ́n fi ẹnu kò sí ọjọ́ àti iye tí yóò san. Lọ́jọ́ náà, Ifeoluwa rán Awosogbon lọ sí ibẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà láìmọ̀ pé ẹ̀ẹ̀dẹ ni. Bí Awosogbon ṣe sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ẹni náà sún mọ́ ọn tó sì da ásíìdì síi lára.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Awosogbon kàn sí Ifeoluwa tí ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe gbé e lọ sílé ìwòsàn. Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ló ṣe atọ́nà bí wọ́n ṣe mú Ziaulihak Zakari tó da ásíìdì náà sí Awosogbon lára. – Olólùfẹ́ da ásíìdì sí ọmọṣẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lára nítorí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Zakari ló jẹ́wọ́ pé Owolabi Daniel ni ó rán òun níṣẹ́ náà. Daniel ni olólùfẹ́ Ifeoluwa tẹ́lẹ̀. Ifeoluwa ṣe àlàyé pé Daniel wá sí ilé iṣẹ́ òun ní ọdún tó kọjá ó sì nífẹ̀ẹ́ bí òun ṣe tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ ara wọn, lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Ifeoluwa ní òun kò ṣe mọ́ nítorí wàhálà rẹ̀ pọ̀ jù.
Láti ìgbà náà ni Daniel ti ń dúnkokò mọ́ Ifeoluwa, oríṣìí àtẹ̀jíṣẹ́ ni ó fi ránṣẹ́ síi pé òun yóò gba ẹ̀mí rẹ̀. Lọ́gán tí Zakari da ásíìdì náà sí Awosogbon lára ni Daniel fi àtẹ̀jíṣẹ́ mìíràn ránṣẹ́ sí Ifeoluwa pé ásíìdì nìkan kọ́, òun ń bọ̀ wá pa á láìpẹ́.
Ifeoluwa ṣe àlàyé pé òun fi àwọn àtèjíṣẹ́ ìdúnkokò náà tó àwọn ọlọ́pàá létí ṣaájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ nítorí Daniel kò kọ orúkọ rẹ̀ síi kò sì fi òǹkà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀ ẹ́, àwọn ọlọ́pàá da ẹ̀sùn náà nù pé kò sí ẹ̀rí pé Daniel ni ó ń tẹ àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ náà.
Ní báyìí ni ẹ̀kọ fi ojú mí mu hàn pé Daniel ni ó wà nídìí àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ náà, àwọn ọlọ́pàá gbé òun àti Zakari àmọ́ wọ́n ti gba onídùúró Daniel ó sì ti padà sílé.
Èyí ló kọ Ifeoluwa lóminú pé ǹjẹ́ ẹ̀mí òun dè báyìí tí Daniel ti jáde látìmọ́lé? Ifeoluwa ní ọkàn òun ò balẹ̀ lórí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe gba onídùúró Daniel, ó ní ó ṣì le ṣe òun ní ìjàm̀bá.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí bàbá Daniel lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní òun kò ní ohunkóhun tí òun le sọ láìṣe pé agbẹjọ́rò òun wà ní orí ìjókòó. Ó ní ọgọ́ta ẹgbẹ̀rún náírà ni òun san fún ìtọ́jú Awosogbon, kín ni kí òun tún ṣe? – Olólùfẹ́ da ásíìdì sí ọmọṣẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lára nítorí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Daniel kọ́ ni yóò kọ́ da ásíìdì lé obìnrin lórí nítorí ìkọ̀sílẹ̀, Timothy náà ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún tó kọ́já:
Àwọn ọlọ́pàá ti ń wá Timothy Gilbert lẹ́yìn tó fi ásíìdì wẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ Angela Ogah ní ìpínlẹ̀ Edo.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Moses Yamu ni pé Timothy fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ lẹ́yìn tó dá ọ̀ràn náà ní agbègbè Ihovbe, Ikpoba.
Ẹni ogójì ọdún ni Angela Ogah, lọ́jọ́ náà, èdè àìyedè wáyé láàrin Timothy àti Angela, Timothy kò ṣe méní ṣe méjì, ó da ásíìdì lé Angela lórí ó sì sálọ.
John Izegaegbe; ẹni tó jẹ́ agbẹjọ́rò Angela ṣe àlàyé pé Angela ti wà ní ilé ìwósàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú, ó ní àwọn ti kọ̀wé sí ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Yamu rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún àwọn olólùfẹ́ ọ̀ràn ó sì ṣe ìlérí pé àwọn yóò mú Timothy láìpẹ́.
Zaliha kò tilẹ̀ da ásíìdì lé ọmọ orógun rẹ̀ lórí, ó rọ ọ́ síi lẹ́nu ni:
Zaliha Shuaibu ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ní Kaduna lórí ẹ̀sùn pé ó fún ọmọ orogún rẹ̀ ní ásíìdì mu.
Ọmọ oṣù mẹ́ta ni ọmọ náà, Maryam Ibrahim ni orúkọ orogún rẹ̀ tó jẹ́ ìyá ọmọ yìí. Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ báyìí pé; lọ́jọ́ kẹtàlá, oṣù Èbìbí, ọdún 2025, Maryam tẹ́ ọmọ rẹ̀ sí orí ìbùsùn ó sì lọ wẹ̀, nígbà tó dé, ó bá ọmọ náà lọ́wọ́ ìyálé rẹ̀; Zaliha. Zaliha gbé ọmọ Maryam fún un ó sì bọ́ síta.
Maryam ṣe àlàyé pé nígbà tí òun gba ọmọ náà lọ́wọ́ Zaliha, òun ríi pé ó ń po ọṣẹ lẹ́nu, àpá sì wà ní ọrùn rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà ń fi ìrora hàn ni ó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ ọmọ náà kú sí ilé ìwòsàn lọ́jọ́ náà. Àyẹ̀wò àwọn dọ́kítà ló fi hàn pé asíìdì ni ọmọ náà mu tó sì rẹ́ gbogbo ìfun rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Maryam fi ẹ̀sùn kan ìyálé rẹ̀; Zaliha pé òun ló fún ọmọ náà ní ásíìdì mu. Zaliha jẹ́wọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá pé lóòótọ́ ni òun fún ọmọ náà ní ásíìdì mu, ó ní òun àti àbúrò ọkọ òun tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lawal Muhammad ni àwọn jọ rọ ọmọ náà ní ásíìdì.
Lawal Muhammad ti fi ẹsẹ̀ fẹ́ báyìí àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti ń wá a. Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kaduna; Rabiu Muhammad ṣe ìlérí pé ìdájọ́ òdodo yóò wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.



