Gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe; Muhamadu Inuwa Yahaya ti ṣe ìlérí mílíọ̀nù méjì náírà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹbí àwọn èèyàn tí ọkọ̀ tẹ̀ pa lọ́jọ́ ọdún Àjínde.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde la ti rí àwọn olùjọsìn tí wọ́n ń bọ̀ láti orí òkè tí wọ́n ti lọ pàdé Jesu, wọ́n ń ṣe àjọyọ̀ wọ́n sì ń kọrin lọ ní tiwọn, ṣàdédé ni ọkọ̀ àjàgbé eléjò yìí sì la àárín wọn kọjá lọ láìbìkítà rárá. Àwọn èèyàn mẹ́rin ló tẹ̀ pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nigba tí àwọn mẹ́jọ mìíràn fara pa.
Ìjọba Ìbílẹ̀ Billiri ní ìpínlẹ̀ Gombe ni èyí ti ṣẹlẹ̀.
A mú ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wá pé:
Àwọn olùjọ́sìn kan tí wọ́n lọ sí orí òkè lọ pàdé Jesu ní Gálílì láàárọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ àjínde ni ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ mẹ́rin pa nínú wọn.
Ohun tí a gbọ́ ni pé bí àwọn èèyan náà ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà ni ọkọ̀ yìí já wọ àárín wọn tó sì tẹ àwọn mẹ́rin pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn mẹ́jọ mìíràn di èrò ilé ìwòsàn.
Kíá ni àwọn èrò ti sọ iná sí ọkọ̀ àjàgbé yìí, àwọn ọlọ́pàá ló dá wọn lọ́wọ́ kọ́, wọn ò láwọn ò ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Òpópónà Billiri ní ìpínlẹ̀ Gombe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ láàárọ̀ òní ọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ ọdún àjíǹde. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn, ọ̀gbẹ́ni Buhari Abdullahi wí pé èèyàn mẹ́rin ló dèrò ọ̀run nínú ìkọlù náà nígbà tí àwọn mẹ́jọ mììràn farapa yánnayànna.
Ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì ni àwọn tó kú náà, ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Gombe tó wà ní Billiri náà ni wọ́n gbé àwọn tó farapa náà lọ.
Gómìnà Yahaya fúnra rẹ̀ ló ṣe àbẹ̀wò sí ìjọba ìbílẹ̀ náà, ó bá wọn kẹ́dùn àwọn tó kú náà, ó sì tún gbàdúrà fún àwọn tó wà nílé ìwòsàn.
Gómìnà Yahaya ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi èyí tó bani lọ́kàn jẹ́, ó kàn jẹ́ pé Ọlọ́run níí fini dárà tó bá wù ú.
Gómìnà wí pé òun yóò san owó ìwòsàn àwọn tó wà ní ilé ìwòsàn náà.
Bákan náà ni ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí awakọ̀ náà hù, ó ní èyí ni irú ẹ̀ kẹta léraléra tí àwọn awakọ̀ àjàgbé ń wa ọkọ̀ wọ àárín àwọn èrò lásìkò ọdún ẹ̀sìn.
Gómìnà Yahaya rọ àwọn agbófinró láti wá ojútùú sí ìwà yìí.
Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó gba àlàáfíà láàyè láàrin ìlú.
Ní èsì sí ọ̀rọ̀ Gómìnà, Alága àjọ kìrìsìtẹ́nì ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Gombe; Pásítọ̀ Alphonsus Shinga pè fún ìdásílẹ̀ àwọn tí ọlọ́pàá mú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó gba àwọn ẹlẹ́sìn níyànjú láti tẹ̀lé àwọn àlàkalẹ̀ ètò ààbò fún gbogbo àjọyọ̀ àti àpéjọ.
Ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti omi ìwòsàn tí àwọn èèyàn ń lọ mu ní ìpínlẹ̀ Kano.
Ìjọba Kano ti lọ da ibẹ̀ wó báyìí o, a gbọ́ pé Àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano tí a mọ̀ sí Hisbah ti lọ wó ibùdó omi ìwòsàn kan tí àwọn èèyàn ń lọ rọ́ mu ní Kano.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde ni a ti rí ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń bu omi mu láti inú ihò àpá ẹsẹ̀ méjì kan tó wà ní ilẹ̀.
Ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn náà ni pé àpá ẹsẹ̀ náà jẹ́ ẹsẹ̀ Ànọ́bì Muhammed, wọ́n sì gbàgbọ́ pé omi náà jẹ́ omi mímọ́ tí yóò ṣe ìwòsàn ati gbígbà àdúrà.
Láti gbogbo orígun Kano ni àwọn èèyàn ti wá mu omi náà, àwọn kan ti ìlú wọn wá mu nínú omi ìwòsàn yìí.
Agbègbè Hotoron Arewa ní Kano ni omi yìí wà, àwọn ọlọ́pàá Hisbah ti lọ sí ibẹ̀ báyìí wọ́n sì ti dí àpá ẹsẹ̀ náà.
Adarí ikọ̀ Hisbah; Dọ́kítà Abba Sufi fi ìdí èyí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé wọ́n ti lọ da ibẹ̀ wó lóòótọ́.
Dọ́kítà Sufi wí pé àwọn kò ní la ojú àwọn sílẹ̀ kí àwọn kan máa fi àdánwò àwọn èèyàn gba owó lọ́wọ́ wọn lábẹ́ ẹ̀sìn. Ó ní àwọn tó gbé omi náà kalẹ̀ fi ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì ni nítorí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ àlàáfíà fún àìlera wọn ni àwọn ṣe dà á wó.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan láti ìpínlẹ̀ Kwara nípa òkú ọkùnrin kan tó léfòó lórí odò Asa ní Ìlọrin.
A gbọ́ pé Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìdámọ̀ òkú èèyàn tí wọ́n rí tó léfòó sí orí odò Asa ní Ìlọrin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara.
Ẹ̀ka tó ń ṣe àmójútó àwùjọ ló rí òkú náà tó lé téńté sórí odò Asa náà, àwọn ló ránṣẹ́ pe ilé iṣẹ́ panápaná.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Ọ̀gbẹ́ni Hassan Adekunle ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè náà àwọn sì ta mọ́ra dé ibẹ̀. Wọ́n yọ òkú náà lodò wọ́n sì gbé e fún ẹ̀ka tó ń mójútó àwùjọ kí wọn ó le ṣe ìdámọ̀ rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Hassan wí pé òkú náà kò le ju ẹni ọdún márùndínláàdọ́ta lọ nígbà ayé rẹ̀.
Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Falade Olumuyiwa wí pé kí àwọn èèyàn ó mójútó ètò ààbò nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.
Èyí ni ìròyìn kejì nípa òkú tí wọ́n rí lórí omi láàárín ọ̀sẹ̀ kan síra. Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n rí òkú àwọn méjì kan lórí odò. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọ ìyá méjì kan náà kú sínú kòtò ìwàkusà ní ìpínlẹ̀ Nasarawa. Ẹ̀gbọ́n wọn ni wọ́n tẹ̀lé lọ sí odò lọ fọ asọ kí ó tó di pé wọ́n lọ kó sínú kòtò ìwàkusà níbi tí wọ́n ti ń serepá.
Discussion about this post