Alága ètò ìdìbò ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, ( OSSIEC), Hashim Abíóyè ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìdìbò ìjọba ìpínlè Ọ̀ṣun yóò wáyé gẹ́gẹ́ bí àlàkalẹ̀ rẹ̀, ní ọjọ́ Sátidé ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejì ọdún yìí, 2025.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní ilé iṣẹ́ ètò ìdìbò ÓSSÍẸ́KÌ ní ọjọ́ Ajé tó kọjá yìí ní ìlú Òṣogbo, Alága Abíóyè sọ pé kò sóhun tó sọ pé òfin ti de àlàkalẹ̀ ètò ìdìbò náà rárá. Ó ṣàlàyé yañya-yàǹyà pé kò sí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kankan tó ká àwọn lọ́wọ́ kò láti má leè ṣètò ìdìbò náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kankan tó ní kí àwọn alága àná tí wọ́n yọ nípò tún padà sórí àlééfà o.
Ó rin kinkin mọ́ ọn pé gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ọgbọ̀n tó wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun ló ṣófo ; èyí ló sì mú un pọn dandan ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ láti wáyé, kí wọn bàa lè dí àlàfo wọ̀nyí. Ó fi dá àwọn aráàlú lójú pé ilé-iṣẹ́ àwọn tí gbà á gẹ́gẹ́ bí wọn láti ṣètò ìdìbò tó gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́, tó sì tún gbàwo bọ̀, láìsí màgòmágó nínú rárá, tí yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún tẹrú-tọmọ.
Ó rọ àwọn olóṣèlú pé kí wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ ètò ìpoloñgo ìbò fún ẹgbẹ́ wọn láìsí rògbòdìyàn bó ti wù kí ó mọ.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, Alàgbà Hashim Abíóyè sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn tó jáde láìpẹ́ yìí. Ó ní ẹjọ́ tí PDP pè lórí ètò ìdìbò náà ni ilé ẹjọ́ fagi lé, nítorí pé ẹjọ́ náà ti wà nílé ẹjọ́ kí OSSIẸ̀KÌ tóó gbé àtẹ̀jáde nípa ètò ìdìbò náà jáde. Ó ní ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga ti wáyé ní Ọgbọnjọ́ oṣù kọkànlá, ọdún 2022,tó ti wọ́gi lé ìdìbò kọ́sọ́ńgbó tó gbé àwọn alága lórúkọ ẹgbẹ́ APC wọlé, tó sì dáwon padà sílé.
Ó ní àwọn ẹgbẹ́ APC àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn tó pe ẹjọ́ kò-tẹ́ – mi-lọ́rùn lásìkò náà tún sọ fún ilé ẹjọ́ náà pé àwọn ò ní í lè tẹ̀ síwájú mọ́ nínú ẹjọ́ tí àwọ́n pè. Èyí ló mú kí ilé ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn fọwọ́ òsì da ẹjọ́ wọn nù ní ọjọ́ kẹtàlá, oșù kìn-ínní ọdún 2025 yìí.