Nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn lánàá, ọkùnrin kan gbé ẹ̀mí mìn nígbà tí àwọn èèyàn márùndínlógún mìíràn farapa yánnayànna. ọkọ̀ náà rún wómúwómú ni, kọjá bẹ́ẹ̀, bí èèyàn bá jẹ orí ahun gan-an yóò kérora abiyamọ.
Àná ni ìjàmbá yìí wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn, ọkọ̀ Mazda kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ forí sọ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ aládàáni kan tó wà ní ojú ọnà náà.
Èèyàn mẹ́rìndínlógún ló wà nínú ọkọ̀ Mazda yìí. Àwọn èèyàn ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ eléérú sungi fún ẹni kan nínú wọn kí awon dọ́kítà tó tẹ́wọ́ gbà á rárá.
Ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé pé ọkọ̀ àjàgbé eléjò ti ilé iṣẹ́ AIM Coy jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ náà ní tirẹ̀ kó tó di pé ọkọ̀ Mazda náà sá eré àsápajúdé pàdé rẹ̀ lójijì.
Adarí àjọ ààbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Ogun; ọ̀gbẹ́ni Seni Ogunyemi fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ pé ó bani lọ́kàn jẹ́ gan-an ni.
Ogunyemi wí pé àwọn ti gbé òkú arákùnrin tó kú náà sí ilé ìgbókùúsí ilé ìwòsàn Livewell tó wà ní Shagamu. Ilé ìwòsàn Livewell yìí kan náà ni àwọn mẹ́ẹ̀dógún yòókù ti ń gba ìtọ́jú.
Èyí ni ẹni kẹjọ tí yóò bá ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó lọ láàrin ọjọ́ márùn-ún ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìjàmbá ọkọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la kọ nípa rẹ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn yìí náà.
Ọkọ̀ Toyota kan tó kó èèyàn méje láti ìpínlẹ̀ Osun wá sí Èkó pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó ń lọ ní tirẹ̀.
Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjàmbá yìí wáyé lọ́jọ́ àìkú.
Ọ̀gbẹ́ni Sanni Saifullahi ló wa ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà, ọkọ̀ àjàgbé yìí ga tó ìwọ̀n ogójì ẹsẹ̀ bàtà, ilé iṣẹ́ Ay and Rolly’s ventures tó wà ní Magodo, ìpínlẹ̀ Èkó ló ni ọkọ̀ àjàgbé yìí.
Ọgbẹ́ni Sunday Okpe ti ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló wa ọkọ̀ Sienna yìí.
Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ọ̀gbẹ́ni Sunday ti gbéra pẹ̀lú èrò méje, ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ìta Olúwo, Ìkòròdú ni ọkọ̀ yìí ti pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà.
Arábìnrin Miracle Chibuzor tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló jókòó níwájú, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá yìí, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn fara pa yánnayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn pé arábìnrin Miracle pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ló kó àwọn márùn-ún tí wọ́n farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn Falobis tó wà ní Mowe fún ìtọ́jú.
Wọ́n gbé òkú arábìnrin Miracle lọ sí ilé ìgbókùúsí Idera fún àyẹ̀wò àti ìwé ẹ̀rí.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wọ́ àwọn ọkọ̀ méjèèjì náà lọ sí àgọ́ wọn tó wà ní Shagamu kí àwọn òṣìṣẹ́ VIO le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Ìjàmbá ọkọ̀ mìíràn wáyé ní ìta Olúwo yìí kan náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ àárọ̀.
Arábìnrin kan tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ni ó jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ márúwá lẹ́nu tó sì padà gbé ẹ̀mí mìn.
Usman Abdullah; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ló wa kẹ̀kẹ́ TVS náà, obìnrin yìí fẹ́ sọdá títì ló jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ Abdullahi lẹ́nu, orí ló fi ṣèṣe. Àwọn èèyàn ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn Omowunmi tó wà ní Kusela, Ogijo àmọ́ obìnrin yìí padà jẹ́ ìpè Elédùà.
Àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀, wọ́n ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì wọ́ kẹ̀kẹ́ náà lọ sí àgọ́ wọn. Abdullahi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìwádìí lórí bí ìjàmbá náà ṣe wáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kòrò ojú sí ìjàmbá méjèèjì yìí, wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé ní èyí tó le mú kí ìjàmbá ọkọ̀ ó wáyé, bákan náà ni wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti má màa sún mọ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò pẹ́kípẹ́kí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogulowo gba àwọn awakọ̀ níyànjú.
Ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó ti gba ọ̀pọlọpọ̀ ẹ̀mí àwọn èèyàn láìròtẹ́lẹ̀, àkọsílẹ fi hàn pé eré àsápajúdé ló fa èyí tó pọ̀jù nínú àwọn ìjàmbá náà.
Nínú ọdún yìí náà ni awakọ̀ Toyota Highlander kan pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ní ojú ọnà márosẹ̀ Lekki-Epe lọ́sàn-án àná.
Awakọ̀ yìí pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì lọ kọlu ọkọ̀ àjàgbé kan tó ń lọ sí Epe, ọkọ̀ Toyota náà gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó kọlu àjàgbé náà, gbogbo akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí awakọ̀ yìí kò yọrí sí rere.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì; Adebayo Taofiq ló fi ọ̀rọ̀ náà lédè pé àwọn gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí arákùnrin tó wa ọkọ̀ náà àmọ́ ó ti kú kí wọn ó tó ríi yọ wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀.
Àjọ LASTMA gba àwọn awakọ̀ níyànjú láti ṣe pẹ̀lẹ́.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn nìkan ló ti gba ẹ̀mí mẹ́jọ láàrin ọ̀sẹ̀ kan yìí, láì tíì sọ nípa àwọn ìjàmbá ọkọ̀ àwọn ojú pópó mìíràn káàkiri.
Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀, kò fẹ́rẹ̀ sí ọjọ́ kan tí ìròyìn ìjàmbá ọkọ̀ kò kàn nílû yìí, èyí ń fẹ́ àpérò.
Púpọ̀ nínú àwọn ìjàmbá yìí ló jẹ́ pé ìjánu àwọn ọkọ̀ náà da iṣẹ́ sílẹ̀ lórí eré ni, bákan náà ni ọ̀fintótó fi hàn pé àwọn awakọ̀ yìí kìí sá eré mọ níwọ̀n.
A rọ ẹ̀yin awakọ̀ wa láti ṣe pẹ̀lẹ́ lójú pópó nítorí pé ẹ̀mí kò láàrọ̀.