ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, July 20, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

WỌ́N TI YÌNBỌN PA ỌMỌ IMAAMU ABUJA.

ÀWỌN ẸBÍ FI Ẹ̀SÙN KAN ỌLỌ́PÀÁ.

by Adeola Olanrewaju
August 4, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọ̀rọ̀ ìdílé
0
WỌ́N TI YÌNBỌN PA ỌMỌ IMAAMU ABUJA.
0
SHARES
0
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Níbi ìjà ilẹ̀ tó wáyé ní agbègbè Kuchibuyi ní Abuja ni wọ́n ti yìnbọn pa ọmọ bàbá Imaamu Abuja.
Orúkọ ọmọ imaamu yìí ni Attahiru Abubakar, Attahiru kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Abass àti imaamu bàbá wọn fara gbọta wọ́n sì wà nílé ìwòsàn.
Josephine Adeh; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá lọ sí agbègbè náà láti pẹ̀tù sí aáwọ̀ ilẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ , nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ takò wọ́n, wọ́n ṣe ìkọlù sí àwọn ọlọ́pàá, àwọn ọlọ́pàá sì mú nínú wọn.
Josephine wí pé kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá Abuja ti fèsì pé kò sí ààyè fún àwọn ọ̀dọ́ láti máa ṣe ìkọlù sí àwọn ọlọ́pàá, ó ní àwọn kò ní fi ààyè gba irú rẹ̀ àwọn yóò sì fi àwọn afurasí náà jófin.
Wàyí ọ, àlàyé tí àwọn ẹbí Imaamu náà ṣe àti èyí tí àwọn ará àdúgbò náà ṣe tako ẹ̀yí tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe yìí.
Àwọn ẹbí náà fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n gbè lẹ́yìn olówó kan tó ti ń da àdúgbò náà láàmú nítorí pé ó fẹ́ gba ilẹ̀ kan tó wà níbẹ̀.
Àwọn ará àdúgbò náà ṣe àlàyé pé bàbá olówó náà jẹ́ abánikọ́lé tó ń gbìyànjú àti gba ilẹ̀ náà, yóò kó àwọn jàǹdùkú àti àwọn ológun wá sí orí ilẹ̀ náà wọn yóò sì máa lé àwọn èèyàn kúrò lórí ilẹ̀ náà.
Wọ́n ní àwọn ológun yóò dúró yípo ilẹ̀ yìí wọn yóò sì máa lé àwọn tó ń kọjá.
Lọ́jọ́ Àbámẹ́ta tó lọ yìí, bàbá yìí tún kó àwọn ológun dé wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lé àwọn èèyàn, wọ́n tún gbé igi dí ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ tú jáde láti dá wọn lẹ́kun ọ̀rọ̀ náà sì fẹ́ di wàhálà.
Àwọn àgbààgbà àdúgbò dá síi, ó sì rọlẹ̀ . Ǹjẹ́ kí oníkálukú ó padà sí ilé rẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá tí bàbá náà pè dé, wọn kò bèèrè ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ṣíná ìbọn bolẹ̀, wọ́n yìnbọn pa Attahiru nígbà tí ìbọn ba àwọn mẹ́fà mìíràn. Wọ́n sì tún kó àwọn tí ọwọ́ wọn bà lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé kò sí òtítọ́ nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn yìí pé àwọn ọ̀dọ́ náà ló kojú àwọn ọlọ́pàá.

Ta ni ká gbàgbọ́ báyìí?

Ọ̀rọ̀ yínyin ìbọn pa èèyàn ti fẹ́ kúrò ní ìròyìn ní Nàìjíríà báyìí nítorí pé gbogbo ìgbà ni irú nǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀.
Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń yin tiwọn ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ń yìn, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ náà kò gbẹ́yìn.
Kẹ̀ù kẹ̀ù ni ìró ìbọn dà lọ́tùn-ún lósì.

Nínú oṣù Agẹmọ tó kọjá yìí ni a mú ìròyìn kan wá nípa ọmọdékùnrin kan tó lọ ra oúnjẹ tí ìbọn bà láìtọ́jọ́.

ADVERTISEMENT

Ìròyìn náà kà báyìí pé:

Ọmọkùnrin ọmọ ọdún méjìlá kan ni àṣìta ìbọn ti ṣekú pa báyìí ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì ni wọ́n ń gbéná wojú ara wọn ní nǹkan bíi aago mẹjọ alẹ́ lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹta, oṣù Agẹmọ.
Wasiu; ìyẹn ọmọdékùnrin yìí lọ ra oúnjẹ lọ́dọ̀ olóúnjẹ kan tí wọ́n ń pè ní ìyá ìbejì ní ìsàlẹ̀ ilé rẹ̀ tó wà ní Olosha kí ó tó di pé ìbọn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà bà á tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Tale Amoo; ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò náà ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni àwọn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn, Wasiu sá sí abẹ́ isọ̀ kan nítorí ìpayà, ibẹ̀ náà ni ìbọn ti lọ bá a.
Amoo wí pé àwọn ọkọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà gbìyànjú àti sá lọ àmọ́ wọ́n rí mú nínú wọn.
Àwọn èèyàn tilẹ̀ ṣe aájò Wasiu dé ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó LUTH àmọ́ títì ni ilẹ̀kùn ilé ìwòsàn náà wà kó tó di pé ọmọ náà padà kú.
Àwọn ará àdúgbò wí pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ òkùnkùn máa yìnbọn pa èèyàn báyìí, wọ́n ké sí ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí i.

Báyìí ni ikú àìtọ́jọ́ ṣe mú Wasiu lọ láìrò tẹ́lẹ̀.

Kò tán síbẹ̀ o, ìròyìn ikú ìbọn méjì ni a mú wá nínú oṣù Okúdù.
Ọ̀kan ní Anambra, èkejì ní Onitsha.

ADVERTISEMENT

Ní ìpínlẹ̀ Anambra:
Ọmọ náà ń fi ìbọn bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ọlọ́pàá ṣeré ni ìbọn náà bá yìn mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ba bàbá rẹ̀ lẹ́yìn ó sì tún ba àbúrò ọmọ yìí ní ọrùn ọwọ́.
Okolie Amechi ni orúkọ ọlọ́pàá yìí, nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, ó ti dágbére fáyé àmọ́ ọmọ kejì ṣì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra; Tochukwu Ikenga. Ó ṣe àlàyé pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra àti Nàìjíríà lápapọ̀ ń ṣe ìdárò ẹni ire tó lọ, ìyẹn Rìpẹ́tọ̀ Okolie Amechi tí ọmọ rẹ̀ ṣèèṣì yìnbọn pa nínú ilé rẹ̀.
Wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ìgbókùúsí wọ́n sì ti gba ìbọn náà pamọ́ fún àyẹ̀wò.

Ó tún ṣẹlẹ̀ ní Onitsha náà:

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra lẹ́yìn tí ìbọn bà á.
Òpópọnà Ifejike ní Gúùsù Onitsha ni èyí ti ṣẹlẹ̀. A gbọ́ pé ọmọkùnrin náà jókòó sí iwájú ilé àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí àwọn ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Agunechemba ń lé afurasí ọ̀daràn kan lọ, ọ̀kan nínú wọn yin ìbọn sókè àmọ́ ọmọ náà ló bà tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà fẹ́ sá lọ àmọ́ àwọn èrò àti àwọn ọlọ́jà ló dá wọn dúró tí wọ́n sì ní kí wọn ó gbé òkú ọmọ náà dandan. Wọ́n ní èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn ó yin ìbọn pa aráàlú.

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#newsfeed#newsupdatesAbujabreaking newsIGPIroyin Agbegbeland disputemurdernews onlinenewsinyorubanewsonlinenewsupdateNigerpolicePolice brutalitytrendingViolence
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

ADVERTISEMENT

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In

Add New Playlist

No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.