ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Ìròyìn Agbègbè

WỌ́N TI GÚN ỌMỌ OGUN OJÚ ÒFURUFÚ KAN PA NÍ SHASHA, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.

Àti àwọn mìíràn tó gún ara wọn pa

by Adeola Olanrewaju
November 25, 2025
in Ìròyìn Agbègbè
0
WỌ́N TI GÚN ỌMỌ OGUN OJÚ ÒFURUFÚ KAN PA NÍ SHASHA, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ọ̀rọ̀ ti di iṣu ata yán-an-yàn-án ní agbègbè Shasha, ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò gún ọmọ ogun ojú òfurufú ilẹ̀ wa lọ́bẹ pa.
A gbọ́ pé lọ́jọ́ kẹsàn-án, oṣù Belu yìí ni ọmọ ogun náà ń ré kọjá láì wọ aṣọ ní òpópónà Oremeji lásìkò tí àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò ń gbá bọ́ọ̀lú àfẹsẹ̀gbá lọ́wọ́, ọ̀kan nínú wọn gbá bọ́ọ̀lù mọ́ ọmọ ogun yìí ni ó bá gbé bọ́ọ̀lù náà nílẹ̀ tó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ìbóm̀bó ti ọmọ tó gbá bọ́ọ̀lù lù ú.
Nígbà tí àwọn yòókù rọ̀gbà rẹ̀ láti gba ọmọ náà kalẹ̀ ló fa ọ̀bẹ yọ tó sì fi fa bọ́ọ̀lù náà ya, ó tún wí pé òun yóò gún ẹni tó bá sún mọ́ òun.
Àwọn ọ̀dọ́ yìí kò le farada bí ó ṣe ń lu ara wọn, wọ́n sún mọ́ ọn láti gba ọ̀bẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀ àwọn náà sì farapa lẹ́yìn náà ni ọ̀kan nínú wọn fi ọ̀bẹ náà gún un. Wọ́n gbé e ní dìgbàdìgbà lọ ilé ìwòsàn àmó ó padà kú.
Gbogbo àsìkò yìí, wọn kò mọ̀ pé ọmọ ogun ni ọkùnrin náà nítorí kò wọ aṣọ, nígbà tí àwọn ọmọ ogun ya wọ àdúgbò ni wọ́n tó mọ̀ pé àwọn ti kẹ́ran, wọ́n lu àwọn èèyàn lálùbami wọ́n sì ń wá ọmọ tó gún un lọ́bẹ̀ náà.
Inú ìbẹ̀rùbojo ni àwọn ará agbègbè náà wà, gbogbo àwọn onísọ̀ kò leè sí ìsọ̀ nítorí ìbẹ̀rù.
Shola; ọ̀kan nínú àwọn aráàlú náà wí pé inú ìbẹ̀rùbojo ni òun wà látàrí pé àwọn tí wọ́n gún ológun náà ti fẹsẹ̀ fẹ́ àwọn aláìmọ̀kan ni àwọn ológun ń kó.
Esther Komolafe tí òun náà jẹ́ aráàlú wí pé àwọn ológun náà yin afẹ́fẹ́ tajútajú mọ́ àwọn lọ́jọ́ kejì nígbà tí wọ́n wá kojú àwọn ọ̀dọ́ náà. A kò le gba ojú ọ̀nà gbangba lásìkò yìí, a ń ṣẹ́nà gbà ni.
Ohun tí àwọn aráàlú sọ yìí tako ohun tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abimbola Adebisi sọ nípa pé ọmọ ogun náà kò kú.
Lóòótọ́ ni pé wọ́n jọ́ ní fàǹfa wọ́n tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ irọ́ ni pé àwọn ológun ń yọ wọ́n lẹ́nu ládùúgbò náà, kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá.
Nígbà tí àwọ ológun fẹ́ gbẹ̀san lọ́jọ́ kejì, ọ̀gá ọlọ́pàá dá síi wọ́n sì yanjú rẹ̀ ní tùbínùbí.

Kìí ṣe òní ni àwọn èèyàn ti ń gún ara wọn pa, ní ìpínlẹ̀ Kwara níjọ́sí, àwọn ọ̀rẹ́ méjì kan gún ara wọn pa.

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Gafar àti Hammed kó tó di pé abo dá ìjà sílẹ̀ láàrin wọ́n. A gbọ́ pé àwọn méjéèjì nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan náà wọn kò sì ṣetán àti yọ̀ǹda rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Hammed Usman Tunde nígbà tí Gafar jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọmọ ìlú Ilorin ni àwọn méjéèjì.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn méjéèjì pàdé ní ìsọ̀ onírèké lọ́jà Gboro, Ilorin. Èdè àìyedè ni wọ́n kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ àgi bó ṣe di ìjàkadì, ẹ̀ẹ̀kan náà ni Gafar fa ọ̀bẹ yó tó sì fi gún Hammed láyà, lẹ́yìn náà ló sá lọ.
Àwọn èèyàn ṣe aájò Hammed dé ilé ìwòsàn aládàáni kan ní Gboro àmọ́ ó ti kú kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹni tó mọ ibi tí Gafar wà bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sá kúrò nílé.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Aderemi. Ó wí pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní aago méjì ọ̀sán lọ́jọ́rú, nígbà tí wọn dé ibẹ̀, ẹ̀jẹ Hammed ni wọ́n bá nílẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn ọlọ́pàá ta mọ́ra lọ sílé Gafar àmọ́ wọn kò bá ẹyẹ, tọdé tàgbà ilé náà tin a pápá bora kódà wọn kò dúró kó ẹrù.
Kọmiṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Adekimi Ojo bá àwọn ẹbí Hammed kẹ́dùn ó sì kí àwọn ará ọjà Gboro kú ìbọ̀wọ̀ fún òfin tí wọn kò dáná sun Gafar náà.

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Lilian náà gún olólùfẹ́ rẹ̀ pa:

Lilian; ẹni ọdún mọ́kànlélógún tó sì jẹ́ ìyá àwọn ọmọ méjì ti gún ọkọ rẹ̀ pa nígbà tí wọ́n ń jà.
Òpópónà ijanpa ni Lilian ń gbé pẹ̀lú ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ọdún kẹrin rèé tó ti wà nílé ọkọ rẹ̀. Ọmọ méjì ni ó bí fún un.
Àlàyé tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé lọ́jọ́ náà, Lilian àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìjà, Lilian wí pé ọkọ òun ní òun kò fẹ́ òun mọ́ kí òun máa lọ tó sì tún fi ẹgba na òun, ìgbà náà ni òun wọ ilé ìdáná lọ mú ọ̀bẹ tí òun sì gún un pa.
Lilian ní òun fi ọ̀bẹ náà gbèjà ara òun nígbà tó ní kí òun máa lọ. Ó ní ọdún kẹrin rèé tí òun ti ń bá a gbé, ọkùnrin méjì ló bí fún un, àkọ́bí jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà tí èkejì jẹ́ ọmọ ọdún méjì.
Lọ́jọ́ Ajé tí ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀, Lilian wí pé ọkọ òun yan òun lódì, nígbà tó yá, ó ní kí òun ó máa lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ òun pé òun kò fẹ́ ẹ mọ́, ọ̀rọ̀ náà di ìjà láàrin wọn, ó fi ẹgba na òun ó sì tún fọ́ orí òun mọ́ ògiri.
Ìbínú èyí ni òun fi lọ yọ ọ̀bẹ òun kò gbèrò láti pa á.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn tọkọtaya láti máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #b#iweiroyinyoruba#MurderCase#murdercases #murdercasestory#news #happenings#newsfeed#NewsOnline #iweiroyinyoruba #NewsUpdat#newsupdate2025#newsupdates#onlinenewspaper #NEWS #CrimeNews#TRENDINGNEWSTODAY#trendingpostbreakingnewscrisise #news #news #happeningse #newsonlinnewsonlinenewsupdateonlinenewspolicereakingnews #trendingnews
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin fipá bá akẹgbẹ́ wọn lò pọ̀.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin fipá bá akẹgbẹ́ wọn lò pọ̀.

Recommended

Àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢOJÚṢÒFIN MÉJÌ YAPA KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ NNPP.

1 year ago
BOKO HARAM LÓ GBÉ ÀDÓ OLÓRÓ NÁÀ WỌ MỌṢÁLÁṢÍ – ILÉ IṢẸ́ OLÓGUN.

BOKO HARAM LÓ GBÉ ÀDÓ OLÓRÓ NÁÀ WỌ MỌṢÁLÁṢÍ – ILÉ IṢẸ́ OLÓGUN.

5 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.