ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Ìròyìn Agbègbè

WỌ́N RÍ ÒKÚ BÀBÁ ẸNI ỌDÚN MÁRÙNDÍNLÁÀDỌ́RIN KAN NÍNÚ KÀNǸGA.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
December 6, 2025
in Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ Logo

ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ LOGO ITOKASI AWORAN : ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ

0
SHARES
2
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàárọ̀ yìí kò ṣenure rárá látàrí pé òkú ọkùnrin bàbá àgbàlagbà ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin kan ni wọ́n ṣàdédé rí nínú kànǹga lọ́jọ́bo, ọjọ́ kẹrin, oṣù Ọ̀pẹ.
Agbègbè oke-oga Atipe ní Idi aga, Ìbàdàn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀, kò tíì àlàyé kan pàtó sí lórí bí bàbá náà ṣe dé inú kànǹga náà lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Moroof Akinwale; ẹni tó jẹ́ adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.

ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN ṢEKÚ PA ỌLỌ́PÀÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.

Àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ti ṣekú pa ọlọ́pàá kan àti èèyàn kan ní agbègbè Ijebu-ode, ìpínlẹ̀ Ogun.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Eiye àti Aiye ya wọ àdúgbò náà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn lákọlákọ. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjéèjì dojú ìjà kọ ara wọn, ìbọn ń ró bíi ti ogun kírìjí ìgbà náà, nínú èyí ni wọ́n ti yìnbọn pa ọlọ́pàá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olamilekan àti ẹlòmíràn tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ báyìí.
Lanre Ogunlowo; kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé wọ́n pa Olamilekan lóòótọ́ tó jẹ́ ọlọ́pàá nínú ìkọlù náà àmọ́ wọn kò tíì ṣe ìdámọ̀ ẹnìkejì náà.

ÈÈYÀN MÉJÌ NI WỌ́N PA NÍPAKÚPA NÍ ÌPÍNLẸ̀ BORNO.

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Bí èèyàn bá jẹ orí ahun, yóò sun ẹkún bó bá fi ojú kan òkú Rofkatu Yohana tí wọ́n pa sínú yàrá rẹ̀.
Ọjọ́ kẹta, oṣù Ọ̀pẹ ni wọ́n bá òkú Rofkatu ní orí ìbus̀n rẹ̀ nínú yàrá rẹ̀, wọ́n dú ọrùn rẹ̀ wọ́n sì ṣá a ládàá káàkiri ara.
Ilé ìwòsàn ìjọba Maiduguri ni wọ́n tọ́jú òkú rẹ̀ sí fún àyẹ̀wò ọwọ́ sì ti tẹ afurasí kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Salisu Muhammed Nura lórí ikú Rofkatu náà.
Lọ́jọ kan náà ni wọ́n rí òkú Muhammed Ibrahim Saje nínú ọkọ̀ rẹ̀, ọrùn ni wọ́n ti dú òun náà. Ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé Rofkatu sí ni wọ́n gbé Muhammmed náà lọ.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí fínní lórí ìṣẹ̀lẹ̀ méjéèjì náà.

ỌWỌ́ TẸ BÀBÁ ẸNI ÀÁDỌ́TA ỌDÚN TÓ GBA ÌBÁLÉ ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌLÁ.

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ti tẹ bàbá kan ẹni àádọ́ta ọdún tó fi ipá gba ìbálé ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé ìyá ọmọ yìí ló fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Iléṣà nígbà tó rí ikun funfun nínú pátá ọmọ rẹ̀ náà.
Ọmọ náà jẹ́wọ́ pé bàbá náà tó jẹ́ alábàágbé wọn ló fipá bá òun lájọṣepọ̀. Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé ìjákújàá ni bàbá yìí já ìbálé ọmọ náà, gbagada ló fa abógundé rẹ̀ ya.
Ọmọ yìí ṣe àlàyé pé láti inú oṣù Agẹmọ ni bàbá yìí ti ń bá òun lájọṣpọ̀ tí yóò sì fún un ní igba náírà kó fi ra oúnjẹ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Ibrahim Gotan korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó rọ àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.

ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC FI ÒFIN DE IYIOLA OMISORE NÍNÚ ÌDÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀ṢUN.

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti fi òfin de aṣòfin tẹ́lẹ̀rí; Iyiola Omisore àti àwọn mẹ́fà mìíràn nínú ìdíjedupò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Omisore àti àwọn mẹ́fà náà kò ní ní àǹfàání láti kópa nínú ìdìbò abẹ́lé tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù yìí.
Àwíjarè ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórí ìgbésẹ̀ náà ni pé àwọn èèyàn náà ń ṣe ṣégeṣège, wọn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ sínú ẹgbẹ́ náà.

ỌKỌ̀ AGBÉPÒ DÙBÚ Ọ̀NÀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.

Ọkọ̀ agbépo kan ti ṣubú ó sì dùbú ọ̀nà ní Igboukwu-Uga ní ijọba ìbílẹ̀ Aguata, Anambra.
Inú ìfòyà ni gbogbo àwọn ará agbègbè náà wà lórí pé ọkọ̀ náà le gbaná lẹ́ẹ̀kan náà.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé awakọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré, ó fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ epo inú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàn.

ỌDÚN MÉJE LÓ YẸ NÍ SÁÀ KAN FÚN IPÒ ÌṢÈLÚ – ADEWUNMI FALODE.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Adewunmi Falode tó jẹ́ olùkọ́ nílé ìwé gíga LASU ti ṣe àlàyé ìdí tí ìṣèlú orílẹ̀-ède was ̣e ń fòníkú fọ̀ladìde, ó wí pé àìṣedéédé ètò ìṣèlú wa àti ìdí tí kò fi sí ìlọsíwájú dàbí alárà ni pé ọdún mẹ́rin kò tó ṣe ohun gbòógì, kí a tó ṣẹ́jú pẹ́, ọdún mẹ́rin ti pé yóò wá dàbí ìgbà pé ẹni náà kò ṣe nǹkankan lórí ipò náà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí dábàá kí a sọ sáà ipò ìṣèlú di ọdún méje dípò mẹ́rin tí a ń lò lọ́wọ́ yìí, èyí yóò fún Gómìnà àti ààrẹ ní àǹfààní àti gbé nǹkan ṣe lórí ipò.
wàyí o, ọ̀jọ̀gbọ́n Falode wí pé tí a bá ti ṣe èyí, kò ní sí àǹfààní fún sáà kejì, sáà kan ọlọ́dún méje ni ẹni tó bá ti jẹ yóò máa lò.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn gómìnà àti ààrẹ kò ní tíì lò ju oṣù márùn-ún lọ lórí ipò tí wọn yóò ti máa sáré bí wọn yóò ṣe wọlé ẹlẹ́ẹ̀kejì, èyí kò ní jẹ́ kí wọn ó rójú ràyè ṣe ètò ìlú bó ti yẹ.

ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA ADEKUNLE AJAASIN KAN FIPÁ BÁ AKẸGBẸ́ WỌN LÒ PỌ̀.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti tẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin méjì tí wọ́n fipá bá akẹgbẹ́ wọn lájọṣepọ̀.
Olushola Ayanlade; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn ẹni náà tan ọmọbìnrin ẹni ogún ọdún náà lọ sí ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ darapọ̀ mọ́ wọn nílé ìwé náà. Ọmọbìnrin yìí ti mọ Queen Sodo; ẹni ọdún mọ́kàndínlógún láti ilé ìwé girama ó sì lọ kíi nígbà tó wọ ilé ìwé gíga tí òun náà wà.
Nígbà tó dé ilé Queen, ó mu nǹkan mímu láì mọ̀ pé Queen ti fi òògùn olóró sínú rẹ̀, nígbà tí obìnrin yìí sùn lọ, Queen bọ́ síta ó sì pe ọkùnrin náà wọlé láti bá a lájọṣepọ̀.
Aráalé Queen ló gbọ́ ohun tí kò fanimọ́ra láti inú yàrá Queen ló yọjú wo inú ilé náà, ó ṣí ilẹ̀kùn yàrá náà ó sì bá ọkùnrin náà lórí ọmọ yìí.
Wọ́n ṣe aájò ọmọ yìí dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Àwọn afurasí méjéèjì jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni àwọn fún un ní òògùn olóró mu àti pé kìí ṣe tirẹ̀ ni àkọ́kọ́.
Ayanlade wí pé àwọn afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí ó sì rọ àwọn òbí láti máa gba àwọn ọmọ wọn níyànjú lóòrèkóòrè.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#newsfeed#newstodaysnews#newsupdatesbreakingnewsgoviralIroyin AgbegbeÌròyìn Tó Gbòdenewsnewsinyorubanewsonlinenewsupdatesharenewstrendtrendingviralyorubanews
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÌYÁ ÀTI ÌYÁ ÌYÁ TA ỌMỌ ỌJỌ́ MÉJÌ.

ÀWỌN ARÁ KETU-ALAPERE FI Ẹ̀SÙN KAN ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ PÉ ALỌ́NILỌ́WỌ́GBÀ NI WỌ́N.

Recommended

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin fipá bá akẹgbẹ́ wọn lò pọ̀.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajaasin fipá bá akẹgbẹ́ wọn lò pọ̀.

6 months ago
ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWÁRÍ IBI TÍ WỌ́N TI Ń FI ỌMỌ ṢÒWÒ

ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ ṢE ÀWÁRÍ IBI TÍ WỌ́N TI Ń FI ỌMỌ ṢÒWÒ.

1 month ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.