Awakọ̀ Uber ni Ayinde Yusuf, ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ ló wà ní ọjọ́ Ẹtì nigbà tí àwọn ẹni ibi tíí pọnmọ re balùwẹ̀ náà pè é láti ojú òpó uber pé kí ó wá gbé àwọn. Àṣé jàgùdà alọkólóhunkígbe agbénipa ni wọ́n, arak ò fu Ayinde rárá nígbà tó ṣe pé iṣẹ́ rẹ̀ náà ni kó máa fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé èèyàn.
Nígbà tí Ayinde dé ibi tí àwọn èèyàn burúkú yìí júwe fún un, wọ́n jáde síi láti inú igbó, wọ́n gún lọ́bẹ káàkiri ara, òpópónà Agidingbi ní Ikeja ni wọ́n gbé òkú rẹ sí kí wọn ó tó gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ sá lọ.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alága ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ Uber; ọ̀gbẹ́ni Jaiyesinmi Azeez pé ó bani lọ́kàn jẹ́ gidi ó sì jẹ́ ohun burúkú pé àwọn ẹni ibi yìí tan Ayinde pa.
Ọ̀gbẹ́ni Azeez ṣe àlàyé pé àdojúkọ ńlá ni ààbò àwọn awakọ̀ yìí, ó kérora lórí ikú Ayinde yìí. Ó ṣe àpèjúwe Ayinde gẹ́gẹ́ bíi ojúlówó ọmọ ẹgbẹ́ tí kìí ṣe ìmẹ́lẹ́. Àmọ́ àwọn ẹni ibi kò jẹ́ kí ó jẹ tí wọ́n fi yọ ọwọ́ kílàńkó rẹ̀ láwo.
Alága Jaiyesinmi ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá àti àwọn àṣàyàn ẹ̀ṣọ́ aláàbò yóò ṣiṣẹ́ nífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí Ayinde láti mú àwọn atannipa náà.
Ó wí pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀ gan báyìí.
Ayinde ṣe ìlérí láti ríi pé ẹgbẹ́ náà gba ìdájọ́ òdodo lórí ikú Ayinde.