Innocent Idibia tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Tuface ti ráwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo èèyàn pé kí wọn ó dákùn dábọ̀ foríjìn un lórí ọ̀rọ̀ tí òun sọ pé obìnrin kan kò le tẹ́ ọkùnrin lọ́rùn.
Tuface wí pé òun kò mọ̀ọ́n láìdáa ni kí ẹ fọwọ́ wọ́nú.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, a mú ìròyìn wá pé Tuface sọ gudugbẹ ọ̀rọ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pé:
Mo ti sọ èyí nígbà kan rí tí mo sì rí àtakò lórí rẹ̀ àmọ́ mi ò ní yée sọ ọ́. Olọ́run kò dá okó ọkùnrin fún obìnrin kan ṣoṣo. Ọkùnrin ní èso tó pọ̀ lára kò sì leè já gbogbo rẹ̀ fún obìnrin kan.
Bí ẹ bá wo ìgbéyàwó èmi àti Annie ìyàwó mi tẹ́lẹ̀, ìfẹ́ tí ó wà láàárín wa ló dópin tí a fi pínyà kìí ṣe nítorí pé mo ń bá obìnrin mìíràn lájọṣepọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀ láti má pínyà àmọ́ ó di dandan kí a pínyà. Mi ò ṣetán àti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ìpínyà èmi àti ìyàwó mi.
Ní ọjọ́ kejì ni Tuface tọrọ àforíjìn lórí ọ̀rọ̀ náà pé òun kò sọ bẹ́ẹ̀ mọ́ o.
Láàrín ìgbà tí Tuface àti olólùfẹ́ rẹ̀ titun Natasha Osawuru ti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ wọn, oríṣìí fọ́nrán àti àwòrán la ti rí níbi ti wọ́n ti ń dáfẹ̀ẹ́. Òkìkí kàn nígbà kan tí Tuface gbé Natasha lọ sí ilé ìtaṣọ ìgbàlódé Vodi. A gbọ́ pé:
Tuface ti gbé olólùfẹ́ rẹ̀ titun, ẹni bí ọkàn rẹ̀, ààyò tí jẹyin òṣùpá lọ sí Vodi; ibi tí wọ́n ti ń ta àwọn aṣọ ìgbàlódé.
Tẹ̀rín tẹ̀yẹ ni Oluwaseyi Adekunle; ẹni tó ni Vodi fi gba Tuface àti Natasha káàbọ̀ sí ilé ìtaṣọ rẹ̀. Nínú fọ́nrán tí wọ́n fi léde náà la ti rí Natasha tó ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó ń yẹ àwọn aṣọ náà wò ó sì fi èyí tí yóò wọ̀ lọ́jọ́ Ajé lọ sí ìjókòó ilé hàn wá.
Ẹ má gbàgbé pé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ìpínlẹ̀ Edo ni Natasha, òun ló ń ṣojú ẹ̀kun Egor nílé ìgbìmọ̀ aṣofin.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn ẹbí Tuface kò dunú sí ìfẹ́ òun àti Natasha, ẹni tí Natasha ń bá nájà ló kọjú mọ́ ní tirẹ̀, kò jísòró rárá.
Gbogbo ohun tí Tuface ń ṣe yìí ni kò tẹ́ ìyá rẹ̀ lọ́rùn. Ó fìgbà kan ké gbàjarè pé:
A kìí ní igi lóko ká má mọ èso rẹ̀, ìyá tó bí gbajúgbajà olórin nnì Tuface ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Natasha pé kó dákun dábọ̀ tú ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tó dè é mọ́.
Arábìnrin Rose se ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nínú fọ́nrán kan tó gbòde pé ọmọ òun ìyẹn Innocent tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Tuface kìí ṣe irú ọmọ bẹ́ẹ̀ pé dájúdájú ejò lọ́wọ́ nínú.
Àlàyé ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ni pé Innocent ti jáwě ìkọ̀sílẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀ Annie.
Oríṣìí àwọn ẹ̀sùn bíi àìbìkítà ni Innocent fi kan Annie ìyàwó rẹ̀.
Orí ìkọ̀sílẹ̀ yìí ni òun àti Annie wà tí Tuface fi fi fọ́nrán òun àti Natasha léde. Nínú fọ́nrán yìí ni òun àti Natasha ti ń dáfẹ̀ẹ́ tí ó sì fún un ní òrùka ìfẹ́.
Àwọn ọ̀rẹ́ wọn wà ní ibẹ̀, wọ́n bá wọn dáwọ̀ọ́ ìdùnú pẹ̀lú.
Oríṣìí ìhà ni àwọn èèyàn kọ sí fọ́nrán yìí, àwọn àríwísí tí a rí gbà ni pé Natasha ni eku ẹdá tó dá wàhálà sílẹ̀ láàrin Innocent àti ìyàwó rẹ̀. Wọ́n ní òun ni túlétúlé tó tú ilé Tuface kó le rí ibẹ̀ wọ̀. Kò sí orúkọ tí wọn kò pè é tán, láti orí túlétúlé tó fi dé orí gbọkọgbọkọ.
Èsì tí àwọn èèyàn fọ̀ yìí kò tẹ́ ọkọ ìyàwó lọ́rùn, ó ṣe fọ́nrán mìíràn tó ti ṣe àlàyé pé Natasha kìí ṣe gbọkọgbọkọ o, ó ní òun kọ́ ló da aarin òun àti Annie rú o pé kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.
Innocent ṣe àlàyé pé òun nífẹ̀ẹ́ Natasha dọ́kàn ni òun sì fẹ́ fi ṣaya. Ó ṣe àpèjúwe Natasha bíi arẹwà, ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ tó gbá múṣé ó sì wí pé òun nífẹ̀ẹ́ Natasha ni o òun yóò sì fi ṣe aya.
Oríṣìí ìhà ni àwọn èèyàn kọ sí ìpinyà Tuface àti ìyàwó rẹ̀ yìí. Nígbà tí àwọn kan ń káàánú Annie, àwọn kan ń wí pé wàhálà rẹ̀ ló fi lé ọkọ rẹ̀ síta. Bí ó sì ṣe ń lọ yìí, kò sí ìrètí pé ìgbéyàwó wọn yóò padà bọ́ sípò mọ́.
Tuface ti tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò ìfẹ́ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀ titun ó sì tún wá sọ pé ọkùnrin kò le ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú obìnrin kan, Natasha Osawuru ni ààyò ọkàn rẹ̀ lásìkò yìí
Ibi ọ̀rọ̀ dé dúró.
Ohun tí Tuface ṣe yìí kò tẹ́ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, wọ́n fi ẹ̀sùn kan Natasha pé ó ń darí Tuface ó sì ń sọ ọ́ di ohun tí kò jẹ́.
Àwọn èèyàn wí pé awíkoko tíí sọ ojú abẹ níkòó ni Tuface láti ọjọ́ tó ti pẹ́, kíkó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ yìí lọ́wọ́ kan ìdúnkokò Natasha nínú, wọ́n ní kí Natasha ó fi Tuface lọ́rùn sílẹ̀ kó yéé kó o láyà jẹ.
Ọkọ ìyàwó kò fẹ́ kí àwọn èèyàn ó yọnu sí ìyàwó rẹ̀ lára, ó fajú ro sí ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa Natasha pé ó ń darí ayé òun. Tuface fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ibi ìṣúra ẹni wà lọkàn ẹni wà, bí ó bá sì ṣe wu oníkálukú ni yóò ṣe ṣe ìjọba rẹ̀.
Ó ní òun nífẹ̀ẹ́ Natasha, ẹ ó gbà á bẹ́ẹ̀ ni.




