Gbajúgbajà ìlúmọ̀ọ́nká olórin tàkasúfě nnì; Innocent Idibia tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Tuface ti ṣe ìgbéyàwó ìbílẹ̀ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀ titun; Natasha Osawuru.
Àwọn àwòrán ayẹyẹ náà gba orí ìtàkùn ayélujára kan lánàá níbi tí a ti rí àwọn àwòrán tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbéyàwó náà wáyé ni ìlànà àṣà ìlú wọn.
A rí àwòrán tọkọtaya titun tí wọ́n jókòó ọlá, a rí àwòrán ìgbà tí wọ́n ń fi ìdí Natasha jókòó lé ẹsẹ̀ Tuface gẹ́gẹ́ bíi àṣà wọn, a rí àwòrán bí àwọn àgbààgbà ṣe wúre fún Natasha àti Tuface a sì tún rí àwòrán ibi tí Natasha ti ń jẹun.
Ìgbéyàwó yìí ti sọ iná sí orí ìtàkùn ayélujára ó sì ti ń jó ráìnràìn.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló kí wọn kú oríire àmọ́ àwọn kan fi àìdunnú wọn hàn nípa ayẹyẹ yìí.
Arábìnrin kan tilẹ̀ bèèrè ìdí tí Tuface fi múra ní ìbámu pẹ̀lú àṣà Natasha tí kò wọ aṣọ ìbílẹ̀ ẹ̀yà Benue.
Ó wá ṣe àwàdà pé se ṣé Tuface kò lè wọ aṣọ ìbílẹ̀ ẹ̀yà rẹ̀; Benue ni? Kín ni ìdí tí ó fi wọ aṣọ ìbílẹ̀ ẹ̀yà Natasha?
Ṣáájú ìgbéyàwó yìí náà ni àwọn èèyàn ti ń fi ẹnu kun Natasha pé ó ń darí Tuface bíi ìgbà tí afẹ́fẹ́ bá darí igi oko.
Wọ́n ní kò jẹ́ kó rímú mí kò sì jẹ́ kó ṣe ohun tàbí sọ ọ̀rọ̀ bó bá ṣe wá láti ọkàn rẹ̀, wọ́n ní ó ti sọ Tuface di aròbó.
Ohun tó fa ọ̀rọ̀ yìí ni bí Tuface ṣe jáde wá tọrọ àforíjì lórí ọ̀rọ̀ tó sọ lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe.
Ohun tó sọ náà ni pé:
Mo ti sọ èyí nígbà kan rí tí mo sì rí àtakò lórí rẹ̀ àmọ́ mi ò ní yée sọ ọ́. Olọ́run kò dá okó ọkùnrin fún obìnrin kan ṣoṣo.
Ọkùnrin ní èso tó pọ̀ lára kò sì leè já gbogbo rẹ̀ fún obìnrin kan.
Bí ẹ bá wo ìgbéyàwó èmi àti Annie ìyàwó mi tẹ́lẹ̀, ìfẹ́ tí ó wà láàárín wa ló dópin tí a fi pínyà kìí ṣe nítorí pé mo ń bá obìnrin mìíràn lájọṣepọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀ láti má pínyà àmọ́ ó di dandan kí a pínyà. Mi ò ṣetán àti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ìpínyà èmi àti ìyàwó mi.
Ní ọjọ́ kejì ni Tuface tọrọ àforíjìn lórí ọ̀rọ̀ náà pé òun kò sọ bẹ́ẹ̀ mọ́ o.
Ó wí pé òun kò mọ̀ọ́n láìdáa ni kí ẹ fọwọ́ wọ́nú.
Láti ìgbà náà ni àwọn èèyàn ti ń fi ẹnu kun Natasha lòrí ìtàkùn ayélujára. Wọ́n ní awíkoko ni Tuface ṣáájú kí ó tó pàdé Natasha, Tuface ọ̀ún ló wá sọ̀rọ̀ tó tún wá kóo jẹ báyìí.
Gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu Natasha, kò tilẹ̀ wo ibẹ̀ rárá, fìlà máwobẹ̀ ló dé, ẹni tó ń bá ná ọjà ló kọjú mọ́ kò wo ti ariwo ọjà rárá.
Gbogbo ayé ni ó ń jẹ pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀, oríṣìí àwòrán àti fọ́nrán ló ń fi léde.
Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni ilé ìtaṣọ Seyin Vodi tí òun àti olólùfẹ́ rẹ̀ ti lọ ra àwọn aṣọ àsìkò.
Ìròyìn rẹ̀ kà báyìí pé:
Tuface ti gbé olólùfẹ́ rẹ̀ titun, ẹni bí ọkàn rẹ̀, ààyò tí jẹyin òṣùpá; Natasha Osawuru lọ sí Vodi; ibi tí wọ́n ti ń ta àwọn aṣọ ìgbàlódé.
Tẹ̀rín tẹ̀yẹ ni Oluwaseyi Adekunle; ẹni tó ni ilé iṣẹ́ Vodi fi gba Tuface àti Natasha káàbọ̀ sí ilé ìtaṣọ rẹ̀.
Nínú fọ́nrán tí wọ́n fi léde náà la ti rí Natasha tó ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó ń yẹ àwọn aṣọ náà wò ó sì fi èyí tí yóò wọ̀ lọ́jọ́ Ajé lọ sí ìjókòó ilé hàn wá.
Ẹ má gbàgbé pé ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ìpínlẹ̀ Edo ni Natasha, òun ló ń ṣojú ẹ̀kun Egor nílé ìgbìmọ̀ aṣofin.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni wọ́n ṣe ìgbéyàwó yìí, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn kọjá àfẹnutúká.
Yàtọ̀ sí àwọn àna orí ayélujára, àwọn àna Natasha náà kò faramọ́ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn yìí pàápàá ìyá Tuface.
Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ń rúgbó bọ̀, Arábìnrin Rose Idibia ké gbájarè pé:
Gbogbo ohun tí Tuface ń ṣe yìí ni kò tẹ́ ìyá rẹ̀ lọ́rùn. Ó fìgbà kan ké gbàjarè pé:
A kìí ní igi lóko ká má mọ èso rẹ̀, ìyá tó bí gbajúgbajà olórin nnì Tuface ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Natasha pé kó dákun dábọ̀ tú ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tó dè é mọ́.
Arábìnrin Rose se ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nínú fọ́nrán kan tó gbòde pé ọmọ òun ìyẹn Innocent tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Tuface kìí ṣe irú ọmọ bẹ́ẹ̀ pé dájúdájú ejò lọ́wọ́ nínú.
Arábìnrin Rose Idibia ṣe àlàyé pé òun mọ Innocent ọmọ òun dáadáa, kìí ṣe ẹni tó le kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí náà kí Natasha ó tú ẹ̀gbà ọrùn to fún ọmọ òun nítorí pé òun ló fi dè é mọ́lẹ̀.
Bóyá ó dè é mọ́lẹ̀ o, kò dè é mọ́lẹ̀ o, a ti ti òjé bọ olóòṣà lọ́wọ́ báyìí, Tuface ti ṣe ìgbéyàwó ìbílẹ̀ pẹ̀lú Natasha, ọ̀rọ̀ bùṣe.
Ó ṣe pàtàkì láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Natasha aya Tuface kìí ṣe Natasha tí òun àti Akpabio jọ ní aáwọ̀ ọ.
Ìpínlẹ̀ Kogi ni Natasha Akpoti-Uduaghan ń ṣojú nígbà tí Natasha Osawuru ń ṣojú ìpínlẹ̀ Edo.
Àpèjúwe Natasha Osawuru.
Natasha Osawuru ni àpèjá orúkọ arábìnrin yìí. Ó jẹ́ olóṣèlú, inú oṣù igbe ọdún 2023 ni wọ́n dìbò yàn án sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo. Natasha ló ń ṣojú ẹ̀kun Egor lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP





