Tọkọtaya kan tí wọ́n ń gbé ní Ita-Eku ní igirigiri, Ado Ekiti tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ekiti ni wọ́n ṣá ara wọn ládàá pa ní òru ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí.
Ọ̀rọ̀ náà ṣe àwọn ọmọ wọn gan-an ní kàyéfì, kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ó ṣe ṣẹ̀lẹ̀ nítorí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí.
Àkọ́bí wọn lọ́kùnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà pé bàbá àwọn dé ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́, ó ní òun kò le jẹun àyàfi bí ìyá àwọn bá dé.
Nígbà tí ìyá wọn dé, gbogbo wọn jọ jẹun, wọ́n gbàdúrà, bàbá wọn ka bíbélì sí wọn létí, gbogbo wọn sì wọ yàrá wọn lọ sùn.
Nígbà tó di òru ni àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró àdá láti inú yàrá bàbá wọn, títì láti inú ni ìlẹ̀kùn wọn wà, àwọn ọmọ bá lọ pe awon ará àdúgbò, nígbà tí wọn yóò fi dé, wẹ́lo ni yàrá náà kò sí ariwo kankan mọ́.
Àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò já ìlẹ̀kùn yàrá náà, òkú tọkọtaya ni wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpá àdá tó jinú lára wọn. Kódà, nǹkan ọmọkùnrin bàbá ti dá dúrò nílẹ̀; kò sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́.
Ohun tí wọ́n le sọ nípa ipò tí wọ́n bá wọn náà ni pé bóyá ìyàwó gé okó ọkọ rẹ̀ ni ọkọ náà bá kó àdá bò ó ni wọ́n bá ṣá ara wọn pa. Èrò lásán ni èyí, kò ṣojú ẹnìkankan.
Àwọn akọ̀ròyìn bi ọmọ náà léèrè pé ṣé àwọn òbí wọn máa ń jà tẹ́lẹ̀.
Ọmọ yìí fèsì pé ìjà kìí ṣe ohun titun nílé àwọn nítorí pé gbogbo ìgbà ni ìyá àwọn máa ń bá bàbá àwọn jà lórí ẹ̀sùn pé bàbá àwọn ń yan àlè.
Ó wí pé bàbá àwọn máa ń bá àwọn ṣeré dáadáa àmọ́ tí ìyá awo bá ti dé ni àyà rẹ̀ ó máa já. Ọmọ yìí wí pé bàbá òun sọ fún òun lọ́jọ́ kan pé ẹ̀rù ìyá òun ń ba òun.
Àmọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, ìjà ni àwọn ń retí bí ìyá àwọn ṣe dé àmọ́ ẹ̀rín àti ọ̀yàyà ni ìyá wọn bá wọlé, inú gbogbo wọn dùn láìmọ̀ pé gbẹgẹdẹ ó padà gbiná lóru.
Ọmọ mẹ́rin ló wà láàárín tọkọtaya yìí, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni àkọ́bí wọn, kò sí èyí tó tójú bọ́ nínú wọn.
Àwọn ará àdúgbò náà kín àlàyé tí ọmọ yìí ṣe lẹ́yìn. Wọ́n ní fádèyí olóró àdúgbò ni arábìnrin náà, gbogbo ìgbà ni ó máa ń bá ọkọ rẹ̀ jà, á wí pé ọkọ òun ń yan àlè.
Wọ́n ní ohun tó ṣẹlẹ̀ lóru ọjọ́ náà gan-an kò yé ẹnikẹ́ni tààrà nítorí pé wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí. Àwọn ará àdúgbò tilẹ̀ ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ̀ngbọ̀n nítorí pé ọlọ́pàá ni ọkùnrin náà kó tó kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.