Àjọ SERAP ( SOCIO-ECONOMIC RIGHTS AND ACCOUNTABILITY PROJECT) ti ké tantan sí Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO pé ní kíákíá, mọna wáà! fagilé ẹjọ́ tó dá fún Sẹ́nétọ̀ tó n ṣojú aàrin gbùngbùn ìpínlẹ̀ Kogi, NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN lọ́ṣẹ̀ tó kọjá pé kó lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà gbáko, pé àwọn kò gbọdọ̀ rí eégún tó n jẹ́ Àjíkẹ́ rẹ̀ nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Nàìjíríà.Àjọ SERAP tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé ẹjọ́ tí wọ́n dá fún NATASHIA AKPOTI kò bá òfin mu rárá yálà òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tàbí òfin adúláwọ̀; gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ sí èrò àti ìsọ̀rọ̀ lábẹ́ òfin lábẹ́ òfin abala kọkàndínlógójì òfin ilẹ̀ Nàìjíríà àti ẹ̀tọ́ ọmọ adúláwọ̀; àjọ SERAP tún tẹnumọ́ pé ‘kò bójúmọ rárá’.
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin wa gbọdọ̀ jẹ́ àríkọ́ṣe rere láti máa dáàbò bo ẹ̀tọ́ ọmọ Nàìjíríà kìí ṣe lọ́nà tí wọ́n gbé e gbà yìí; KOLAWOLE OLUWADARE ló sọ èyí. Àjọ SERAP tún tako bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ̀tọ́ àwọn ará ìpínlẹ̀ Kogi mọ́lẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí èyí kìí sì ṣe ìlànà ìjọba awa-ara-wa;DẸ̀MÓKÍRÉSÌ. Rírọkúnlé tí Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO ní kí NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà kò ní fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kogi láàyè nítorí kò ní sí ẹni tí yóò máa ṣojú wọn ní gbogbo àkókò tí yóò wà ní ìgbélé náà. SERAP ní kí wọ́n fagilé ìjìyà náà kí ó má báa dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ilé ẹjọ́ yóò gba àlejò àwọn méjéèjì. SERAP ní òfin tí wọ́n fi mú u tọdún 2023 kò lágbárá láti yọọ́ bí i jìgá.Lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù yìí ni igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ SERAP tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ KOLAWOLE OLUWADARE fi ìwé ìkìlọ̀ ṣẹwọ́ síta pé Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO yóò fi ojú winá ìjọba nílé ẹjọ́ bí ó bá kọ̀ láti wọ́gilé ìjàyà tó fi jẹ NATASHIA AKPOTI lásìkò yìí títí di òní tí í ṣe wákàtí méjìdínláàdọ́ta
Àjọ SERAP ṣàlàyé ìgbẹ̀jọ́ náà bí èyí tó lòdì pátápátá sí ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn láti sọ tàbí fọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ síta fún aráyé gbọ́.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n fi ẹ̀sùn kan NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN pé ó n tú ìtukútu nípa akẹ́gbẹ́ rẹ̀ nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ wa lórí Sẹnetọ GOODSWILL AKPABI, pé NATASHIA tún kọ̀ láti jókòó sí ibi tí Sẹnetọ̀ àgbà yàn fún un, oṣù mẹ́fà gbáko ni wọ́n fi ni kó lọ́ ọ́ rọọ́kúnlé láì ní gbowó oṣù àti àwọn àjẹmọ́nú kankan ní gbogbo àsìkò yìí, kò sì gbọdọ̀ rìn ní gbèrègbéré ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin lásìkò ìgbélé rẹ̀ yìí; AKPABIO tún ní kò gbọdọ̀ ṣe àfihàn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ìgbìmọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.
Lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù yìí ni igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ SERAP tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ KOLAWOLE OLUWADARE fi ìwé ìkìlọ̀ ṣẹwọ́ síta pé Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO yóò fi ojú winá ìjọba nílé ẹjọ́ bí ó bá kọ̀ láti wọ́gilé ìjàyà tó fi jẹ NATASHIA AKPOTI lásìkò yìí títí di òní tí í ṣe wákàtí méjìdínláàdọ́ta. Ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé náà ni:
‘Ẹnikẹ́ni kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìyà jẹ ẹnìkejì lábẹ́ òfin látàrí sísọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde fún aráyé gbọ́ láì gba àṣẹ nílé ẹjọ́, kò tún gbọdọ̀ sí ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́ èyí kò sì yọ NATASHIAN AKPOTI UDUAGHAN sílẹ̀; à n ṣe kìlọ̀kìlọ̀ báyìí kí Sẹnetọ AKPABIO wọ́gilé ìdájọ́ rẹ̀ lórí NATASHIA: Àjọ SERAP
ÌTẸ̀TỌ́-ẸNI MỌ́LẸ̀ LÓNÀ ÀÌTỌ́
Àjọ SERAP tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé ẹjọ́ tí wọ́n dá fún NATASHIA AKPOTI kò bá òfin mu rárá yálà òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tàbí òfin adúláwọ̀; gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ sí èrò àti ìsọ̀rọ̀ lábẹ́ òfin lábẹ́ òfin abala kọkàndínlógójì òfin ilẹ̀ Nàìjíríà àti ẹ̀tọ́ ọmọ adúláwọ̀; àjọ SERAP tún tẹnumọ́ pé ‘kò bójúmọ rárá’.
Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin wa gbọdọ̀ jẹ́ àríkọ́ṣe rere láti máa dáàbò bo ẹ̀tọ́ ọmọ Nàìjíríà kìí ṣe lọ́nà tí wọ́n gbé e gbà yìí; KOLAWOLE OLUWADARE ló sọ èyí. Àjọ SERAP tún tako bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ̀tọ́ àwọn ará ìpínlẹ̀ Kogi mọ́lẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí èyí kìí sì ṣe ìlànà ìjọba awa-ara-wa;DẸ̀MÓKÍRÉSÌ. Rírọkúnlé tí Sẹnetọ GOODSWILL AKPABIO ní kí NATASHIA AKPOTI UDUAGHAN lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà kò ní fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kogi láàyè nítorí kò ní sí ẹni tí yóò máa ṣojú wọn ní gbogbo àkókò tí yóò wà ní ìgbélé náà. SERAP ní kí wọ́n fagilé ìjìyà náà kí ó má báa dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ilé ẹjọ́ yóò gba àlejò àwọn méjéèjì. SERAP ní òfin tí wọ́n fi mú u tọdún 2023 kò lágbárá láti yọọ́ bí i jìgá.
Sẹnetọ AKPOTI NATASHIA ti lu Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, KAYODE FAYEMI lọ́gọ̀ ẹnu, ó sì gbé òṣùbà ràbàndẹ̀ fún un látàrí bí ó ti tan ìmọ́lẹ̀ sí ẹ̀sùn tí Alàgbà CYRIL FASUYI fi kàn án ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà lórí awuyewuye pé FAYEMI KAYODE pàápàá n fi òwò nàbì lọ òun náà bí i ti GOODSWILL AKPABIO. Ó sọ èyí lórí ẹ̀rọ ayélujára fesibúùkù pé “Ẹ ṣeun, ọlálájùlọ KAYODE FAYEMI fún títan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tó n jà ranyinranyin nílẹ̀, ìgbìyànjú mi nígbà náà lọ́hùn ún ni láti ṣe ìgbénde ọ̀kàn lára ọrọ̀ ajé wa, Àjàòkúta, ojú gbàmí tì fún FASUYI bo ti ṣe n parọ́ ojúkorojú mọ́ mi, ó tún n ṣe ìtọ́kasí láti inú ìwé Bíbélì mímọ́, Hùn ùn! Ọlọ́run kú u sùúrù. Gómìnà àná ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, KAYODE FAYEMI sọ gbangba-gbàngbà pé aáwọ̀ tòun pẹ̀lú NATASHIA jẹ́mọ́ lórí iṣẹ́ àti ìlọsíwájú ilẹ̀ Nàìjíríà, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ!Èmi ò- jù- ọ́, ìwọ ò- jù- mí , ibí ni mo fẹ́ jókòó, èmi ò fẹ́ ibí, jókòó síbẹ̀, mi ò jókòó ló dá yánpọnyánrin sílẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ wa láàrín Olórí kẹta ilẹ̀ Nàìjíríà , Sẹnẹtọ GOODSWILL AKPABIO àti Sẹnẹtọ tó n ṣojú ìpínlẹ̀ Kogí, Arábìnrin NATASHIA AKPOTI-UDUAGHAN láìpẹ́ yìí títí tí awuyewuye pé ṣé GOODSWILL AKPABIO wá kéré nínú ayé ni, ìkọlù-kọgbà ni òkò ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ sí NATASHIA AKPOTI ni òun náà bá bọ́ ohùn pé níṣe ni GOODWILL AKPABIO n fi òwò nàbì lọ òun ìdí nìyí tí kò fi jẹ́ kí òun mí nílé ìgbìmọ̀ àṣofìn àgbà ilẹ̀ wa