Àjọ ètò ìdìbò ilẹ̀ wa; INEC ti kéde èsì ìdìbò Gómìnà tó wáyé lọ́jọ́ kẹ́jọ, oṣù Belu, ẹni tó jáwé olúborí náà ni gómìnà tó wà nípò lọ́wọ́lọ́wọ́; Chukwuma Soludo, èyí ni yóò jẹ́ sáà kejì rẹ̀ báyìí.
Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni Soludo fi la àwọn olùdíje yòókù, ẹni tí ibò tirẹ̀ náà ta bíọ́bíọ́ díẹ̀ náà ni olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Nicholas Ukachukwu.
Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ INEC; mẹ́rìndínlógún ni àwọn olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kànlélógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà ni Soludo ti jáwé olúborí, dájúdájú, kékeré kọ́ ni bàbá fi ju ọmọ lọ.
Omoregie; ẹni tó kéde èsì ìdìbò náà wí pé lẹ́yìn gbogbo àkójọ àti kíkà; Soludo ni ó jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà. Ó wí pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan kojú ìdààmú àti rògbòdìyàn ní èyí tó mú kí wọn ó fagi lé ibò wọn níbẹ̀ àmọ́ èyí kò dí èsì àpapọ̀ lọ́wọ́.
Omoregie wí pé lákòótán, òun fi ọwọ́ sọ̀yà pé ìdìbò náà lọ nírọwọ́ rọsẹ̀ tí Chukwuma Soludo; ẹni tó jẹ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APGA jáwé olúborí.
bí Soludo ṣe ń yọ̀ ni olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ní kó má tíì dunnú jù. Ẹ ka ohun tó wí:
Nicholas Ukachukwu; ẹni tó jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti sọ ìhà tó kọ sí èsì ìdìbò náà, ó wí pé òun kò tíì gbà pé Chukwuma Soludo; ẹni tó wà nípò náà báyìí tó sì tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ló jáwé olúborí, ó wí pé àwọn yóò ṣe àtúnyẹ̀wò èsì ìdìbò náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ bá mú wá.
Ó wí pé àwọn èèyàn tí iye wọn dín díẹ̀ ní mílíọ́nù kan ló dìbò fún òun, èyí túmọ̀ sí pé àwọn aráàlú ń fẹ́ òun nípò náà fún ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè, láìpẹ́ láìjìnnà, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni yóò máa darí ìpínlẹ̀ Anambra.
Ọ̀rọ̀ Nicholas tẹ̀síwájú pé láti ibi ìdìbò abẹ́lé ni àwwọn ti ń ṣe akitiyan, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òun gbìyànjú wọ́n sì ṣe bẹbẹ kí gbogbo rẹ̀ ó le já sí rere àmọ́ lásìkò ìdìbò náà, àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù fún àwọn olólùfẹ́ mi àti àwọn aṣojú mi, wọ́n tilẹ̀ gbé ọ̀kan nínú wọn pamọ́ di ẹ̀yìn ìbò.
Ẹ̀yìn náà ríi pé ejò lọ́wọ́ nínú èsì ìdìbò náà. Mo ń dúró de ìjábọ̀ àwọn aṣojú mi àti ohun tí ẹgbẹ́ APC yóò sọ kí n tó mọ ohun tí màá ṣe.
Wọ́n tún fi ẹ̀sùn ìbò rírà kàn mí, ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe fún ẹni tí kò sí nípò láti ra ìbò?
Bí mob á ra ìbò lóòótọ́, èsì ìdìbò ni yóò fi hàn kìí ṣe àwọn ni yóò ṣe máa sọ. Gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ló jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọ́n tún dáná sun ilé obìnrin kan tí òun náà jẹ́ olólùfẹ́ APC, ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àparútu ni ẹgbẹ́ òṣèlú APGA ṣe? Nicholas ló bèèrè bẹ́ẹ̀.
Mìmì kan ò ní mi ẹgbẹ́ òṣèlú APC, digbí ni ó wà tí yóò sì borí – Nicholas Ukachukwu.
Wàyí o, ààrẹ Bola Ahmed bá oníre yọ, ó kí Soludo kú oríire.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí gómìnà àtúnyàn ti ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwuma Soludo kú oríire àtúnyànsípò rẹ̀ fún sáà kejì ó sì tún ṣe ìlérí pé ìjọba àpapọ̀ yóò fún un ni gbogbo àtìlẹ́yìn pátápátá porogodo.
Ààrẹ ṣe àpèjúwe ìṣèjọba Soludo gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà àbáyọ fún àwọn aráàlú, dájúdájú, ìwé kíkà ní ipa rere nínú ìṣèjọba tó yaranti.
Bákan náà ni ààrẹ ṣe ìrántí àbẹ̀wò tó ṣe sí ipínlẹ̀ Anmabra lóṣù Èbìbí ńgbà tó lọ ṣí àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí Soludo ṣe sí ìpínlẹ̀ náà, mi ò le gbàgbe àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta tó o gbéṣe ní Anambra.
Ààrẹ kí Gómìnà Soludo káre fún ṣíṣe àmúlò ọgbọ́n, òye, oore-ọ̀fẹ́, làákàyè àti ìbáwí nínú ìṣèjọba rẹ̀ ní èyí tó jẹ́ kí oríkì ó ro ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ìmọ̀lẹ̀ orílẹ̀-èdè.
Mo ṣe ìlérí fún ọ Soludo pé ìjọba àpapọ̀ yóò tì ọ́ lẹ́yìn gbọ̀ngbọ̀n láti ṣe àṣeyọrí – ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Lórí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú yìí ná la ṣì wà – Fayose ṣe àbẹ̀wò sí olusegun obasanjo ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ ogun.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹ́lẹ̀rí; Ayodele Fayose ti balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ogun láti ṣe àbẹ̀wò sí ààrẹ ìjarùn-ún; Olóyè Olusegun Obasanjo ní ilé rẹ̀.
Nínú àwòrán tí Lere Olayinka fi léde la ti rí Olóyè Obasanjo tí ó wọ aṣọ ìbílẹ̀ funfun àti fìlà aláwọ̀ ewé ; ìfẹ́ Nàìjíríà kò fìgbà kan kúrò lọ́kàn bàbá.
Oloye Obasanjo àti Ayodele Fayose jọ ta ayò àmọ́ a kò le sọ ẹni tó para wọn láyò.
Lára àwọn tó wà níbẹ̀ ni igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀rí; Yemi Osinbajo. Osinbajo wí pé òun fi òkò kan pa ẹyẹ méjì ni òun ṣe yọjú síi nítorí pé òun ko ní le wá síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbẹ́ rẹ̀ tí yóò wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù yìí.
Fayose àti Osinbajo kíra tẹ̀ríntọ̀yàyà, wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn. Osinbajo kí Fayose kú akitiyan rẹ̀ nínú ìṣèlú àti bí orúkọ rẹ̀ kò ṣe ṣe é fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.
Fayose náà kò ya abaramóore-jẹ, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó gba àlejò rẹ̀, ó ní àpọ́nlé òun wọ́n ṣe òun sì mọ̀ ọ́n, ó ṣe àpèjúwe èyí gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ láàrín àwọn olóṣèlú.
Àbẹ̀́wò yìí ti pè fún àríwísí lórí ìtàkùn ayélujára nítorí pé Fayose àti Obasanjo ò rẹ́ láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Kín ni ẹ̀yin lérò pé ó ń ṣẹlẹ̀?





