Bàbá ọmọdékùnrin kan tí Salawu Omikansola pa nípakúpa ti ṣe àlàyé ikú tó pa ọmọ náà.
Olumide Lawal ni orúkọ bàbá Wahab, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni Wahab lásìkò ikú rẹ̀.
Agbègbè Igbile Ijebu ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
Lọ́jọ́ kọkànlélógún, oṣù Agẹmọ ni Wahab sọnù tí kò wá sílé, nígbà tó di ọjọ́ kẹta, wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ títì tí ẹ̀yà ara rẹ̀ kò sì pé mọ́.
Wọ́n ti gé orí àti ọrùnwọ́ rẹ̀ wọ́n sì ti yọ ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.
Bàbá Wahab ṣe àlàyé pé Igbile Ijebu ni ìyá ọmọ náà ń gbé nígbà tí òun ń gbé ní Ijebu Ode.
Lọ́jọ́ náà, ìyá Wahab pe bàbá rẹ̀ pé ṣé Wahab wá sí ọ̀dọ rẹ̀ ni nítorí pé wọn kò ríi.
Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń wá a kiri gbogbo Igbile Ijebu àti Ijebu Ode.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta ni àwọn ará àdúgbò wá pe baba Wahab nílé pé wọ́n rí òkú kan lọ́nà oko pẹ̀lú irú asọ Wahab.
Olumide ní òun kò gbàgbọ́ àmọ́ òun tẹ̀lé wọn dé ibẹ̀. Wọ́n bá òkú Wahab nílẹ̀, aṣọ àti bàtà ni wọ́n fi dá a mọ̀ nítorí pé wọ́n ti gé orí rẹ̀, ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ọkàn àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lọ.
Àwọn ọdẹ àdúgbò ló júwe Salawu Oyinkansola fún wọn pé àwọn pàdé rẹ̀ lóru ọjọ́ tí ọmọ náà sọnù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ lára aṣọ rẹ̀.
Salawu sọ fún àwọn ọdẹ pé òun lọ bá àwọn èèyàn kan pa ajá fún Ògún ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ta sí òun láṣọ, ni wọ́n bá fi sílẹ̀.
Ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú Salawu Oyinkansola, òun ló dárúkọ Serefusi Agemo.
Salawu ṣe àlàyé pé Serefusi ló ní kí òun ó pa ọmọ náà kí òun ó sì yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀. Ó ní ẹ̀rù ba òun àmọ́ Serefusi ló ki òun láyà.
Serefusi Agemo ni olórí àwọn Alágẹmọ agbègbè náà. Kò sọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn tí Salawu fi kàn án àmọ́ ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Baba Wahab; Olumide Lawal rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ rẹ̀. Ó wí pé òun gbọ́ pé Serefusi ní igi lẹ́yìn ọgbà tó sì máa ń mú ẹ̀sùn jẹ àti pé àwọn kan ti ń dúnkokò mọ́ òun láti pa ẹjọ́ náà tì.
Olumide ní ohun tí òun ń fẹ́ náà ni ìdájọ́ òdodo kí ọmọ òun má kú gbé.
Ìròyìn nípa àwọn alápatà àwọn èèyàn ni ó gbòde kan lọ́sẹ̀ yìí, ìpànìyàn lọ́tùn-ún, ìjínigbé lósì. Ìlú kan gógó.
Àwọn èèyàn kò tíì japoró nọ́ọ̀sì tí Chiemere sẹkú pa tó tún jẹ́ aláboyún tán, òmíràn ló tún délẹ̀ yìí.
Ìròyìn nọ́ọ̀sì tí Chiemere pa náà tàn kálé káko.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Arábìnrin kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó sì tún lóyún sínú ni àwọn méjì kan ti sẹkú pa báyìí tí wọ́n sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Chiemere Elobisi; ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló tan nọ́ọ̀sì náà wá sí ilé rẹ̀ pé kí ó wá tọ́jú òun, nígbà tí nọ́ọ̀sì yìí dé ilé rẹ̀, Chiemere pa á ó sì kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú àwọn ọ̀rá dúdú.
Lẹ́yìn náà ni ó ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn oníṣègùn káàkiri. Ìyókù rẹ̀ tó dà sí inú kòtò ìdaminù ni ó mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya tí wọ́n sì tọpinpin dé ilé rẹ̀.
Chiemere ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ àmọ́ ọwọ́ tẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ; Somtochukwu Nwafor.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Somtochukwu, ó ṣe àlàyé pé òun kò lọ́wọ́ sí pípa àti kíkun nọ́ọ̀sì náà, òun kàn nu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tí Chiemere pa á tán ni.
Somtochukwu ló mú àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ àwọn oníṣègùn tí Chiemere ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún ọwọ́ sì ti tẹ ọ̀kan nínú wọn.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní agbègbè Ogbunike ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyi.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti mú Somtochukwu tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin Chiemere nígbà tí Chiemere gan-an ti sá lọ.
Somtochukwu júwe àwọn oníṣègùn tí Chiemere máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún. Èyí ni wọ́n fi mú Nwafor Chibunna tí wọ́n sì bá ẹ̀yà ara nọ́ọ̀sì yìí àti àwọn mìíràn lákàtà rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń wá àwọn oníbàárà ẹ̀yà ara yòókù àti Chiemere.
Kò tán síbẹ̀ o, ikú Fish Magnet náà mílẹ̀ tìtì ó sì bani lọ́kàn jẹ́.
Báyìí ni ìròyìn bí wọ́n ṣe pa Fish Magnet ṣe lọ:
Ní òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni àwọn ajínigbé náà ya wọ ilé rẹ̀ ní Ezinifite, wọ́n kó o ní pápámọ́ra, wọ́n yin ìbọn fún un lẹ́sẹ̀ kí wọ́n tó fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé e lọ.
Ọjọ́ mẹ́ta ni ó lò ní àkàtà wọn tí wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ ṣeni wọ́n pa á tí wọ́n sì ju òmú rẹ̀ nù sí ẹ̀gbẹ́ títì.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé àwọn ti rí ọkọ̀ Onyekere tí wọ́n fi gbé e lọ àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ikú Fish Magnet yìí mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya lórí ètò ààbò ilẹ̀ wa tó mẹ́hẹ àti bí àwọn ajínigbé ṣe ń fi ojoojumọ́ gbilẹ̀ síi.
Vincent Otse; ẹni tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Verydarkman dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
Ó ṣe àpèjúwe ikú Fish Magnet gẹ́gẹ́ bíi ohun tó báni lọ́kàn jẹ́, ó wí pé ògo ọ̀la kan tún ni àwọn ajínigbé dá légbodò yìí.




