Rofiat Lawal; agùnbánirọ̀ tí àwọn ajínigbé gbé ní Ore ti dé láti àkàtà wọn, ó ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́hùn-ún.
Mílíọ́nù márùn-ún náírà ni wọ́n fi gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi yìí.
Nínú àlàyé rẹ̀ ló ti sọ pé inú igbó ni wọ́n kó àwọn wọ̀, ìrìn àrìnwọ́dìí ni wọ́n rìn ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n fi wà níbẹ̀, gààrí sì ni wọ́n ń fún wọn jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Rofiat wí pé bí wọ́n ṣe lu àwọn yòókù tó, ìwọ̀n ìyà díẹ̀ ni òun jẹ. Ìdí ni pé ọ̀kan nínú wọn fẹ́ràn òun ó sì wí pé òun ó fẹ́ òun lọ sí Sokoto.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àjọ agùnbánirọ̀ pé kí wọn ó fún òun ní àkókò díẹ̀ láti sinmi àti láti gba ìtọ́jú kí òun tó padà sí ẹnu iṣẹ́.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá la mú ìròyìn wá pé wọ́n gbé Rofiat Lawal; ẹni tó jẹ́ agùnbánirọ̀ nígbà tó ń padà bọ̀ wá sí Ògbómọ̀ṣọ́ tó ti ń sìnlú pé ‘Àgùnbánirọ̀ ni Rofiat Lawal, ìlú Ogbomosho ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ó ti ń sin ilẹ̀ bàbá rẹ̀, Ogbomosho náà ló ń lọ tí àwọn ajínigbé fi gbé e lójú ọ̀nà Benin sí Ìbàdàn.
Rofiat lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo, Ogbomosho níbi tó ti ń sìnlú ló ń padà sí tí àwọn ajínigbé fi gbé e lọ.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agbakwara ṣe àlàyé pé Rofiat pe òun láti àkàtà àwọn ajínigbé náà pé kí òun ó bá òun wá ogún mílíọ̀nù náírà owó ìtúsílẹ̀.
Agbakwara ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn òbí Rofiat kò là bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ṣagbe, ìbo ni kí wọ́n ti rí adúrú owó náà?
Aminat Lawal, ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Rofiat bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé Rofiat pè lórí aago tó sì ń sunkún pé kí wọn ó bá òun tu owó ìtúsílẹ̀ náà. Ogún mílíọ̀nù náírà ni wọ́n bèèrè fún àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ ti gba sí mílíọ̀nù márùn-ún náírà.
Aminat rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ Nàìjíría láti má dá àwọn dá èyí kí wọn ó dákun dábọ̀ fi iye tí wọ́n bá ní ránṣẹ́ kí wọn ó le gba Rofiat kalẹ̀.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé nínú ọ̀rọ̀ tí Rofiat sọ ni wọ́n ti ríi dì mú pé awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajinigbe lọ́wọ́.
Èrò Ìbàdàn ni ọkọ̀ náà kó láti Benin, bó ṣe dé Ore ló dúró tí àwọn ajinigbe ọ̀hún sì jáde láti inú igbó. Fúnra awakọ̀ náà ló kó wọn lé àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́ tó sì bá tirẹ̀ lọ.
Aminat ṣe àlàyé pé àwọn ti kàn sí àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ èsì tí àwọn gbà náà ni pé Rofiat kò gba ìyànda tó fi lọ sí ilé, wọ́n ní àwọn ti ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn àgùnbánirọ̀ láti máa gba ìyànda bí wọ́n bá fẹ́ lọ sí ilé tàbí rin ìrìnàjò kankan.
Àjọ àgùnbánirọ̀ wí pé àwọn ti da àwọn ẹ̀ṣọ́ síta láti wá ọmọ náà jáde.
Ìjínigbé kìí ṣe ìròyìn mọ́ lórílẹ̀-ède Nàìjíríà, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbé àwọn èèyàn bí ìgbà tí wọ́n bá gbé ewúrẹ́. Kò fẹ́rẹ̀ sí ibi tí ààbò ti péye mọ́ nílùú yìí, Nàìjíríà wá di kóńkó jabele; kálukú ń ṣe tirẹ̀’
A bá Rofiat Lawal dúpẹ́ a sì bá a yọ̀, kò wọ́pọ̀ ẹni tó ní àǹfààní àtibọ̀.