Ohun tí a ó jẹ là ń wá lọ, ká má pàdé ohun tí yóò jẹ wá, àgbà àdúrà ni o, ó yẹ kí èèyàn ó ṣe amin fi ọwọ́ rẹ̀ bọ́jú ni.
Ní ọ̀sán ọjọ́ náà, òṣìṣẹ́ àbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Èkó LASTMA ń lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀ tí yóò ti darí ọkọ̀, bí ó ṣe dé Ọgbà ni ọkọ̀ àjàgbé kan tí ó wá láti ìpínlẹ̀ Bauchi sáré pàdé rẹ̀ tó sì rún ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ wómúwómú.
Ọkọ̀ yìí jáde láti Agidingbi ya wọ oríta Omole, eré àsápajúdé gidi ni wọ́n sọ pé ọkọ̀ yìí bá jáde, ó pàdánù ìjánu rẹ̀ lójijì ó sì mú òṣìṣẹ́ lastma yìí gùn mọ́lẹ̀.
Awakọ̀ yìí ṣíyán kò dúró gbọbẹ̀, ó fẹsẹ̀ fẹ́ẹ nígbà tó rí ohun tó ṣẹlẹ̀ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá dọdẹ rẹ̀ wọ́n sì ríi mú.
Nígbà tí wọn yóò fi gbé òṣìṣẹ́ LASTMA yìí dé ilé ìwòsàn ìjọba ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ti ìpínlẹ̀ Èkó; LASUTH, ẹ̀ka ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ni wọ́n gbé e lọ, àwọn dọ́kítà sì wí pé wọn le tọ́jú apá náà àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ náà ní kíákíá.
Wọ́n gé ẹsẹ̀ ọ̀tún arákùnrin yìí o, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ náà kò gbé ṣéṣé mọ́.
Ọ̀gá àgbà àjọ LASTMA ṣe àbẹ̀wò sí arákùnrin yìí nílé ìwòsàn, kò le royìn gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ rí tán.
Olalekan Bakare-Oki wí pé ọ̀rọ̀ náà burú fún arákùnrin yìí. Ó ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi àgbákò burúkú.
Ó ṣe àfikún pé bí awakọ̀ náà bá ṣe jẹ́jẹ́ ni, ó ṣeéṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ asọnidaláàbọ̀ ara yìí ó má ṣẹlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ LASTMA; Adebayo Taofiq pé òṣìṣẹ́ Lastma kan tó ń lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀ ṣe alábàápàdé ìjàmbá tó mú ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lọ tó sì tún mú ìpalára bá ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Wọ́n ní ọwọ́ tẹ awakọ̀ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ sá lọ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ṣe àwárí rẹ̀.
Awakọ̀ yìí ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí fún ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí òṣìṣẹ́ Lastma máa ko ìjàmbá lẹ́nu iṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjàmbá àìròtẹ́lẹ̀ ni èyí, a mú ìròyìn wá nígbà kan nípa awakọ̀ tó da epo bẹntiróòlù lé ọkọ̀ rẹ̀ lórí pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ lastma nínú tó sì ṣáná síi.
Àwọn òṣìṣẹ́ àbò ojú pópó ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó LASTMA ṣi iṣẹ́ ṣe nígbà tí wọ́n dá ọkọ̀ akérò kan dúró lórí pé kò tẹ̀lé òfin ọkọ̀ wíwà.
Agbègbè Mile 2 ni wọ́n ti mú ọkọ̀ náà, wọ́n sọ awakọ̀ náà kalẹ̀ wọ́n sì kó sínú rẹ̀ láti wàá lọ sí àgọ́ wọn.
Awakọ̀ náà kò ṣe méní ṣe méjì, ó gbé epo bẹntiróòlù ẹ̀yin ọkọ̀ rẹ̀ ó sì dàá sí ara ọkọ̀ náà lójijì, lẹ́yìn náà ló ṣá iná síi.
Àwọn LASTMA inú ọkọ̀ yìí jóná díẹ̀díẹ̀, wọ́n yára bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà àmọ́ ọ̀kan nínú wọn jóná dáadáa ó sì wà nílé ìwòsàn.
Ọ̀gá won ti sọ̀rọ̀ o, ó ní àwọn ń wá awakọ̀ náà kó wá jẹ́ ẹjọ́ ìwà tó hù náà.
Kò sí iṣẹ́ tí kò ní ìjàmbá tirẹ̀ àmọ́ ohun tí ojú àwọn lastma ń rí lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí kò dẹrùn.
Ní òwúrọ̀ yìí lójú ọ̀nà abúlé ẹ̀gbá sí Agége, ọkọ̀ fẹ́rẹ̀ gbá òṣìṣẹ́ lastma kan tó ń dá ọkọ̀ dúró.
Ìdájí ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ni, ọ̀yẹ̀ kò tíì là dáadáa, òṣìṣẹ́ lastma yìí dúró sí ààrin gbùngbùn ọ̀nà abúlé ẹ̀gbá sí Agége ó sì ń darí ọkọ̀, kò sí iná ọba lásìkò yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iná òpó iná títì kò tàn, ìtànná kékeré kan tí kò mọ́lẹ̀ tààrà ni Lastma yìí mú lọ́wọ́ tó fi ń dà àwọn ọkọ̀ dúró.
Ọkọ̀ akérò kan ti kàn án lára tán kó tó ríi pé èèyàn ló dúró sí ojú títì, ó jáwọ́ lójijì ó sì fẹ́rẹ̀ kọlu kẹ̀kẹ́ márúwá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, kẹ̀kẹ́ márúwá yìí náà jáwọ́ ó sì tún fẹ́rẹ̀ kọlu kẹ̀kẹ́ márúwá mìíràn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Báyìí ni ìjàmbá yìí ṣe ré lórí òṣìṣẹ́ Lastma yìí.