Ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Osemudiamen dá ẹ̀bi bí ó ṣe ṣekú pa ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóbìnrin ru òogùn olóró.
Àgọ́ ọlọ́pàá ló ti ṣe àlàyé pé ní ọjọ́ náà, òun ń ti òde bọ̀ ni òun pàdé Fredrick níbi tó ti ń mu òògùn olóró, ó fún òun ní kólósì àti òmíràn tí òun gbé lura.
Nígbà tó dé ilé, ó ki ọmọ ìkókó ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀ ó sì fún un lọ́rùn pa. Osemudiamen tẹ̀síwájú pé òun jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye àti wí pé òun ti ń ṣètò àti kúrò nínú ẹgbẹ́ náà àmọ́ òun kò ní owó tí òun yóò san fún agbẹjọ́rò.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba pé òògùn olóró ló fà á, òun kò fi ojú lásán pa ọmọ náà.
INÁ ÈÉDÚ TÍ WỌ́N FI SÍLẸ̀ JÓ ILÉ ALÁJÀ MÉJÌ NÍ Ọ̀YỌ́.
Iná èédú tí mọ̀lẹ́bí kan fi se oúnjẹ alẹ́ ló ràn mọ́ gbogbo ilé nígbà tí wọn kò pa á kí wọ́n tó wọlé lọ sùn.
A gbọ́ pé ilé alájà méjì kan tó wà ní òpópónà Agbaakin ní Iwo road, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀. Wọ́n kò pa iná èédú tí wọ́n fi dáná oúnjẹ alẹ́, iná yìí ràn mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní ìtòsí rẹ̀ tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ràn mọ́ odidi ilé alájà méjì náà.
Aago mẹ́sàn-án alẹ́ ń lọ lù ni ilé iṣẹ́ pàjáwìrì gba ìpè pé ilé náà ń jó, yàrá méjì ló ti jó gúrúgúrú nínú yàrá méjìlá tó wà ní ilé náà.
Wọ́n dóòlà ẹ̀mí àwọn olùgbé ilé náà àmọ́ obìnrin kan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ TARABA YÓÒ DARAPỌ̀ MỌ́ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC NÍ OṢÙ KÌÍNÍ, ỌDÚN 2026.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba; Ibrahim Tukur ti kéde pé òun yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún tó ń bọ̀. Ó ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Bélú tó lọ yìí ni òun ṣètò àti darapọ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kebbi ni ó mú kí òun ó sún un sí ọdún tó ń bọ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́síwájú pé òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà ní abẹ́lé àmọ́ àjọyọ̀ rẹ̀ tí yóò wáyé ní gbàgede ni òun yóò ṣe ní ọdún 2026 náà. Bí abá ti mú ọjọ́ kan pàtó nínú oṣù Ṣẹẹrẹ náà, a ó kéde fáyé gbọ́.
EBI Ò LE PA MÍ MỌ́ LÁYÉ YÌÍ – PELLER.
Habeeb Hamzat tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Peller ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn kan sọ pé owó yóò dá lọ́wọ́ rẹ̀ bí ìkànnì Tiktok ṣe fi òfin de àwọn ọmọ Nàìjíríà. Ìkànnì Tiktok ti fi òfin de àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà nípa lílo ìkànnì náà ní alẹ́ mọ́ òru, ní àwọn àsìkò yìí, wọn kò tún ní ní àǹfààní àtiwo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn.
Àwíjarè Tiktok ni pé àwọn ń ṣe àyẹ̀wò ìkànnì náà láti ríi dájú pé kò sí ewu fún àwọn tó ń lò ó nípa ohun tí àwọn èèyàn ń fi orí rẹ̀
Èyí ni àwọn kan fi sọ pé owó yóò dá lọ́wọ́ Peller nítorí pé orí ìkànnì náà ni ó ti ń ṣe àwọn fọ́nrán tó fi ń pa owó.
Peller ti fèsì báyìí pé kí wọn ó ti Tiktok pátápátá kò le tu irun kan lára òun nítorí pé kìí ṣe orí ìkànnì náà nìkan ni òun ti ń rí owó.
Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ńlá ni mo ń ṣe ojú fún tí kò sì sí èyí tó san dín ní ogójì mílíọ́nù fún mi, ẹ ń retí kí n máa sunkún nítorí wọ́n fi òfin de Tiktok, ẹ kó iyán mi kéré gan-an.
Mo ní àwọn ojú òpó ayélujára miíràn tó ń mú owó wọlé fún mi, ẹ má tẹ́ńbẹ́lú mi pẹ̀lú pé owó Tiktok ni mo fi ń jẹun – Peller.
MỌ̀LẸ́BÍ ẸLẸ́NI MẸ́TA LÓ BÁ ÌJÀM̀BÁ NÁÀ LỌ.
Ìtẹ̀síwájú lórí ìròyìn tí a mú wá láìpẹ́ yìí nípa ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn náà ni pé àwọn mẹ́ta tí wọ́n kú náà jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan; bàbá, ìyá àti ọmọ wọn kan ṣoṣo kékeré.
Taofiq Adebayo; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ẹ̀ka LASTMA ló ṣe àlàyé pé ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù kan ló sáré àsápajúdé tó sì gbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mọ̀lẹ́bí náà láti ẹ̀yìn, ọkọ̀ yìí pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kọlu àwọn ọkọ̀ méjì mìíràn.
Awakọ̀ ọkọ̀àjàgbé náà fi ẹsè fẹ́ẹ, ó fi àwọn ẹni náà sílẹ̀ nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ wọn. Àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ṣe iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n tó rí àwọn méjì tí wọ́n há sí inú èérún ọkọ̀ náà yọ, wọn kò kú àmọ́ bóyá ni wọ́n le fi ẹsẹ̀ wọn rìn mọ́.
Adarí ẹ̀ka LASTMA; Ọ̀gbẹ́ni Olalekan Bakare-Oki ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bíi ọ̀fọ̀ ńlá tí kò ṣe é rọ́pò. Ó rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe jẹ́jẹ́ lójú pópó pàápàá àwọn awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé.
ỌKỌ̀ AGBÁLÁÌSÀN KỌLU ỌLỌ́KADÀ KAN NÍ ORÍ AFÁRÁ ODÒ IYA-ALARO.
Ẹ̀ka tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Èkó; LASTMA ti mú awakọ̀ ọkọ̀ agbáláìsàn kan ní orí afárá Odò ìyá aláró ní àbáwọ títì Maryland látàrí pé ọ kọlu ọlọ́kadà kan tí ìyẹn sì kán lẹ́sẹ̀.
Ọkọ̀ àjàgbé kan ti jóná sí orí afárá náà lójọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, èyí ti fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ lọ́jọ́ náà. Ọkọ̀ agbáláìsàn yìí gbé aláboyún kan tó ń rọbí tó sì tún fi agolo èémí mí, ìgbìyànjú àti dóòlà ẹ̀mí aláboyún yìí ló mú kí ọkọ̀ agbáláìsàn yìí ó gba ọ̀nà àdojúkọ rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní one-way.
Eré tí ó ń sá bọ̀ náà ló mú un kọlu ọlọ́kadà kan tí ó sì kán an lẹ́sẹ̀. Ibẹ̀ náà ni àwọn LASTMA ti mú awakọ̀ yìí tí wọ́n sì fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Wọ́n gbé aláboyún náà sínú ọkọ̀ ìjọba pẹ̀lú agolo èémí náà lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì gbé ọlọ́kadà náà lọ sí ilé ìwòsàn pẹ̀lú.
Àjọ LASTMA ní àwọn kò ní fi ààyè gba ìlòdì sí òfin ọkọ̀ wíwà àti ààbò ojú pópó.




