Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ̀ ní agbègbè Ikoyi ní Ireolede, ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀ òòrùn Ilorin ní ìpínlẹ̀ Kwara nígbà tí ọmọdébìnrin kan ọmọ ọdún méjìlá kó sínú kànǹga tó sì kú sínú rẹ̀.
Ìròyìn fi yé wa pé nǹkan bíi aago mọ́kànlá ń lọ lù àárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ọmọ náà lọ í ìdí kànǹga náà láti pọn omi àmọ́ ó yọ̀ ó sì kó sínú rẹ̀.
Mayowa; ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò náà ló pe ilé iṣẹ́ panápaná tó fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wọn létí, nígbà tí wọn yóò fi yó ọmọ náà jáde láti inú kànǹga náà, kò í ẹ̀mí lára rẹ̀ mọ́. Wọn yọ òkú rẹ̀ jáde wọ́n sì gbé e fún àwọn òbí rẹ̀.
Àlàyé tí àwọn tí wọn jọ wà lódò lásìkò náà ṣe ni pé ọmọ náà ń fa omi jáde láti inú kànǹga ni ẹsẹ̀ rẹ̀ kan fi yọ̀, yíyọ̀ tó yọ̀ ló mú un dayà dé kànǹga tó sì ré sínú rẹ̀.
Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Ọ̀gbẹ́ni Falade Olumuyiwa rọ àwọn òbí láti máa mọ irú iṣẹ́ tí wọn yóò rán ọmọ pàápàá ọmọdé nídìí kànǹga.
Lórí ìjàm̀bá kànǹga yìí náà, àwọn méjì ni wọ́n kó sínú kànǹga ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó:
Arákùnrin kan ni ikú ré kété lórí rẹ̀ lẹ́yìn tí ó há sínú kànǹga àmọ́ tí wọ́n ríi yọ jáde láàyè.
A gbọ́ pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni ọkùnrin náà, agbègbè Ikotun ní ìpínlẹ̀ Èkó sì ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀.
Ọkùnrin yìí ń ṣiṣẹ́ nínú kànǹga náà lọ́wọ́ ló fi di pé ó há sínú rẹ̀, kànǹga yìí sì jìn níwọ̀n ọgọ́rin ẹsẹ̀ bàtà.
Maria Fadairo; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ní ẹ̀ka LSFRS ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀. Fadairo wí pé àwọn yọ ọkùnrin náà jáde lẹ́yìn tí àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò gbéra láti Ejigbo lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ojúlé kejìlá, òpópónà Aiyeola, Molad, Ikotun. Wọ́n bá ọkùnrin náà níbi tó há sí ní pàlápàlá kànǹga náà.
Maria Fadairo wí pé àìlákàsí ló mú kí ọkùnrin náà ó há nítorí pé kò ṣe àwọn ohun ìdáàbò bò tó yẹ kó ṣe nídìí iṣẹ́ náà. Ó wá rọ àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ láti máa ṣètò ààbò nídìí iṣẹ́ wọn.
Bákan náà la gbọ́ pé arábìnrin kan ló kó sínú kànǹga kan ní iwájú ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní Ijegun, ìpínlẹ̀ Èkó.
Ọgbọ̀njọ́, oṣù Okúdù tó kọjá yìí ni obìnrin náà kó sínú kànǹga yìí., odidi ọjọ́ mẹ́wàá gbáko ló lò nínú rẹ̀ kí wọ́n tó wá yọ òkú rẹ̀ láàárọ̀ yìí. Wọ́n ní àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì kò ní irinṣẹ́ tí wọ́n le fi yọ ọ́ nítorí pé kànǹga náà jìn ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà àádọ́san-án.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀ láti ẹnu alukoro wọn; Maria Fadairo pé àwọn gba ìpè pájáwìrì náà nípa obìnrin kan tó kó sínú kànǹga ní iwájú ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ tó wà ní òpópọ́nà Abuba Anthony, ibùdókọ̀ Obalagbe nítòsí ilé ìtura Fadeko.
Wọ́n ní awọn ta mọ́ra débẹ̀ àmọ́ kànǹga náà jìn gan-an ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà àádọ́sàn-án (170 ft) ní èyí tó gba kí àwọn ó kàn sí àwọn ẹ̀ka mìíràn.
Odidi ọjọ́ mẹ́wàá ló gbà wọ́n láti rí òkú obìnrin náà yọ jáde. Wọ́n ní àwọn bá àwọn ẹbí rẹ̀ kẹ́dùn àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹni tó ni ilé náà.
Bákan náà ni Sunday kú sínú kàna igbà tó fẹ́ mú ẹ̀rọ ìbánsọ̀rọ̀ rẹ̀;
Ìbánújẹ́ ńlá ló wọlé bá àwọn ẹbí Sunday Jimoh lálejò ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Èbìbí yìí nígbà tí Sunday kó sínú kànǹga láti yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jábọ́ sínú rẹ̀.
Ọmọ odún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni Sunday, agbègbè Laditan ní ọjà ọ̀dàn ìpínlẹ̀ Ogun ni ilé rẹ̀ wà, ìbẹ̀ náà ni ìsọ̀ rẹ̀ wà.
Arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Kabiru Aladeshayi Ayigbere tí òun náà ń gbé ní ọjà ọ̀dàn ló ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá pé ní ọjọ́ náà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Sunday jábọ́ sínú kànǹga tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìsọ̀ rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sunday ti fẹ́ kó sínú kànǹga yìí láti yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yìí, àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n dá a lẹ́kun pé ó léwu àmọ́ nígbà tójú pofírí, Sunday padà wọ inú kànǹga yìí láti yọ ẹ̀rọ náà àmọ́ kò padà jáde láàyè, òkú rẹ̀ ni wọ́n gbé jáde.
Àwọn èèyàn kò tiẹ̀ mọ̀ pé Sunday ti padà lọ yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà, Aladeshayi ló kọ́kọ́ fura pé òun kò rí Sunday ni àwọn èèyàn náà bá rokàn rẹ̀, wọ́n kàn ní kí àwọn wo inú kànǹga náà ni pé bóyá ó padà wọ inú ẹ̀, ohun tí ojú wọn bá pàdé kọjá sísọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láàárọ̀ yìí láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Omolola Odutola. Omolola ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè láti ọjà ọ̀dàn pé arákùnrin Sunday Jimoh kan kó sínú kànǹga. Àwọn ọlọ́pàá pakítí mọ́ra, wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n gbé òkú Sunday jáde, àyẹ̀wò fi hàn pé kò sí àpá tàbí àmì kankan lára rẹ̀ pé bóyá èèyàn kan ló tìí.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ti gba ojú rẹ̀ láti ṣètò bí wọn yóò ṣe sin ín.
Èyí tí a ó fi kásẹ̀ ìròyìn nípa kànǹga yìí ni ti ọmọ tó kó síi ní Saki, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
ILÉ IṢẸ́ PANÁPANÁ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌ KAN TÓ KÓ SÍNÚ KÀNǸGA.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wí pé àwọn dóòlà ẹ̀mí ọmọ ọdún méjì kan tó kó sínú kànǹga ní agbègbè Ṣakí, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Oríta Mokola ní Sango ni ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjì náà ti kó sínú kànǹga kan tí wọn kò bò lórí.
Olùbádámọ̀ràn Gómìnà Seyi Makinde lórí ìṣẹ̀lẹ̀ iná; Maroof Akinwande ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé àwọn ti fa ọmọ náà lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ kí wọn ó le parí ìwádìí lórí bí ó ṣe kó sínú kànǹga náà.
Orúkọ ọlọ́pàá tí yóò ṣaájú ikọ̀ ìwádìí yìí ni Odunbanjo Kehinde. Akinwande rọ àwọn aráàlú láti bo àwọn kòtò àti kànǹga tó bá wà ní àyíká wọn.




