Ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers ti gbé àwọn ilé ìwòsàn márùn-ún tì pa látàrí pé wọ́n ń ta àwọn ọmọ titun tí wọ́n bá bí sí ibẹ̀, òkú ọmọ kan tí wọ́n ti ṣe lọ́jọ̀ ni wọn yóò gbé han àwọn òbí ọmọ pé ọmọ wọn kú àmọ́ níṣe wọn ń ta àwọn ọmọ náà.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbógun ti ayédèrú ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ náà ló s.e àwárí àwọn ilé ìwòsàn yìí tí wọ́n sì mú àwọn afurasí méje. Àwọn ẹni yìí dá ilé ìwòsàn sílẹ, wọ́n ń ṣiṣẹ́ abẹ, wọ́n ń kọ òògùn wọ́n sì ń gbẹ̀bí láì ní ìwé àṣẹ tàbí ìwé ìforúkọsílẹ̀ kankan.
Wọ́n tún gbóyà débi pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní iṣẹ́ nọ́ọ̀sì láì ṣe pé àwọn gan-an mọ iṣẹ́ náà.
Ọ̀gá ni ilé ìwòsàn El Dona nínú iṣẹ́ ibi yìí, obìnrin tó ni ilé ìwòsàn yìí yóò gbẹ̀bí fún aláboyún, yóò gbé òkú ọmọ hàn án yóò sì ta ọmọ tí ẹni náà bí lówó gọbọi. Àti òun àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ti wà ní àhámọ́ báyìí.
Ilé ìwòsàn kan náà ní Ndele fún ọmọbìnrin ẹni ogún ọdún kan lábẹ́rẹ́ tó sì já sí ikú, ìdí ni pé abẹ́rẹ́ náà lòdì pátá sí àìsàn tó ń ṣe ọmọ náà, wọ́n ti gbé òun náà tì báyìí.
Ikọ̀ yìí ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ìjọ ẹ̀sìn àti àwọn mìíràn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ètò àyẹ̀wò ara fún àwọ́n aráàlú láti gba àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba.
Ọgọ́ta àwọn ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ni wọ́n bá nílé ìwòsàn náà láì ní ìwé àṣẹ, olùdásílẹ̀ rẹ̀ ti wà ní àhámọ́ báyìí.
Bó ṣe wà ní Lìkì náà ló wà ní Gbàǹja, wọ́n ti mú dọ́kítà kan náà ní Ikotun ní ìpínlẹ̀ Èkó lórí ẹ̀sùn pé ó ta ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìbejì tí obìnrin náà bí.
Ìyá ọmọ gan an ni ó bu dọ́kítà so pé kí ó gbé ọmọ òun sílẹ̀.
Fọ́nrán kan ti gba orí ìtàkùn ayélujára kan nínú èyí tí a ti rí obìnrin kan tó bímọ àti àwọn ẹbí rẹ̀ tí wọ́n bu dọ́kítà tó gbẹ̀bí so pé kí ó gbé ọmọ kejì kalẹ̀. Ẹ̀sùn tí obìnrin yìí àti àwọn ẹbí rẹ̀ fi kan dọ́kítà náà ni pé ó jí ọ̀kan gbé nínú ọmọ ìbejì tí obìnrin náà bí ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀.
Obìnrin yìí dúró lórí pé ọmọ méjì ni ó wà nínú ikùn òun nígbà tí òun ya àwòrán oyún náà àmọ́ ọmọ kan ni dọ́kítà gbé kalẹ̀ nígbà tó bímó tán.
Ọ̀rọ̀ náà ti dé etí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, àlàyé tí a rí gbà ni pé ilé ìwòsàn Tip Top ní Ikotun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀, ìyá ọmọ titun; Blessing Isioma David takú pé àwòrán oyún tí òun yà fi hàn pé ọmọ méjì ló wà nínú ikùn òun, ọmọ kan wà nípò tó dára nígbà tí èkejì dùbúlẹ̀. Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ni àwọn ọmọ náà bí àwòrán náà ṣe fi hàn.
Blessing fi ẹ̀sùn kan dọ́kítà tó gbẹ̀bí rẹ̀ pé ó jí ọ̀kan gbé nínú àwọn ọmọ náà pé kí ó gbé e jáde.
Wàyí o, dọ́kítà àgbà ilé ìwòsàn Tip Top; Sunday Babajide ṣe àlàyé pé ọmọ kan ṣoṣo ni àwọn gbé jáde nínú Blessing, ó wí pé ọkọ rẹ̀ gan-an wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
Dọ́kítà Babajide ṣe àlàyé pé àwòrán oyún tí Blessing yà kùnà láti rí ohun gbogbo dájú, ó wí pé ó ṣeéṣe kí àwòrán oyún ó ṣe àṣìṣe àmọ́ àṣìṣẹ tiwọn ni pé àwọn kò ní kí ó tún àwòrán náà yà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó rọ àwọn èèyàn láti mú sùúrù pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n mú àwọn márùún kan tí wọ́n ta ọmọ ọ̀sẹ̀ méjì ní Èkó:
Àwọn márùn-ún ló ti wà ní agodo àwọn àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ta ọmọ ìkókó, ọmọ ọ̀sẹ̀ méjì.
Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọwọ́ ti tẹ àwọn èèyàn wọ̀nyìí, ọkùnrin ni ọmọ náà. Àlàyé tí a rí gbà lẹ́nu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin ni pé Happiness lóyún ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlógun kò sì mọ ẹni tó loyún. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní owó àti ohun tó le fi tọ́jú rẹ̀ ló bá mú un lọ sí ọ̀dọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nonye Osi tó dúró bíi aláàánú.
Ìgbà tí Nonye gbé Happiness kúrò ní ilé tó gbà fún un lọ sí ibòmíràn ni ara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fu ẹ̀gbọ́n Happiness, láti ìgbà náà ni kò ti rí Happiness mọ́.
Nígbà tí yóò tún padà rí Happiness, kò sí oyún nínú rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ọmọ lọ́wọ́ rẹ̀. Happiness gan-an ò le sọ pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ síi.
Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá wọ́n sì gbé Nonye, òun ló ka àwọn mẹ́rin yòókù tí wọ́n jọ ta ọmọ náà. Orúkọ àwọn yòókù ni Akintan Adedayo, Jimoh Bashiru, Elizabeth Bishop àti Bukola Oladapo.
Wọ́n jẹ́wọ́ pé lẹ́yìn tí Happiness bímọ́ tán ni àwọn ta ọmọ náà ní mílíọ́nù mẹ́ta náírà fún àwọn tó nílò rẹ̀ fún aájò.
Agbègbè Agemuwo ní Badagry ni àwọn ọlọ́pàá ti lọ gbé ọmọ náà. Ìwádìí ṣì ń lọ láti mú àwọn tí wọ́n ta ọmọ náà sí Badagry nítorí pé àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n fi títà rẹ̀ ṣe.
Òwò ọmọ títà ń peleke síi ní àwùjọ wa, bí àwọn kan ṣe ń jí ọmọ tà ni àwọn kan ń ta ọmọ tí wọ́n bí fúnra wọn.
