Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀rí; Yahaya Bello ti ṣe àpèjúwe ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán láti tún Nàìjíríà ṣe.
Yahaya sọ èyí lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùmáwòrán pé bí a bá ń retí kí Ọlọ́run ó sọ áńgẹ́lì kalẹ̀ láti ojú ọ̀run kí ó sì fi ìyẹ́ fò wọ Nàìjíríà, a ó dúró pẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ti sọ áńgẹ́lì náà kalẹ̀ fún wa tipẹ́ àwa la ò kíyèsí. Ta ni áńgẹ́́lì náà? Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ láti tún orílẹ̀-èdè yìí ṣe.
Ó ti pẹ́ tí a ti ń retí olùgbalà tí yóò tún Naìjíríà ṣe, áńgẹ́lì wo ló tún ju Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ? Ó yọ owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ṣètò èyáwó kàwé, ó ṣe àtúntò ẹ̀sẹ́wó owó òkèrè, ó ṣe àwọn òfin tó pawó wọlé sápò ìjọba àti aráàlú, ẹni tó bá ń retí iṣẹ́ ìyanu nìkan ni yóò sọ pé Tinubu kò ṣe tó, ààrẹ kan ò tún gbọdọ̀ ṣe ju báyìí lọ.
Ṣáájú ọdún 2015 ni a ti ń bèèrè fún Nàìjíríà titun ní èyí tí ayé ó dẹ gbogbo èèyàn lọ́rùn, gbogbo ohun tí a ń fẹ́ náà ni ààrẹ ń ṣe lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ kò le retí kí ó ṣe gbogbo rẹ̀ tán lẹ́ẹ̀kan náà nítorí pé ìlú ti bàjẹ́ jìnnà kí Tinubu ó tó gba ìjọba.
Èmi yóò maáa ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Tinubu nítèmi nítorí pé mom ọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe, kò ṣe é ṣe fún ààrẹ láti ṣe gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà mo sì nírètí pé yóò ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.
Ohun tí a ń fẹ́ lọ́jó¸iwájú ni pé nígbà tí ààrẹ ó bá fi parí ìṣejọba ẹlẹ́ẹ̀kejì, yóò fi àwọn ọmọlẹ́yìn rere lélẹ̀ tí yóò máa tọ ipasẹ̀ ààrẹ tí wọn yóò sì má atẹ̀lé ìlànà ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní èyí tí yóò jẹ́ pé irú àwọn èèyàn rere bíi èmi àti àwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-ède Nàìjíríà dénú ni yóò má abọ́ sípò ààrẹ.
Lọ́jọ́ tònìí, inú mi dùn pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Tinubu, ayọ mi kún, bí ẹ bá sì wo ìṣejọba mi nígbà tí mo wà nípò, ẹ ó ríi pé àwọn iṣẹ́ rere tí mo ṣe ń tọ̀ mí lẹ́yìn – èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Yahaya Bello sọ.
Bí ìgbà tí Àlùfáà sọ̀rọ̀ tí òjò wá kù ni ọ̀rọ̀ Yahaya Bello jẹ́ nítorí pé àwọn olóṣèlú ti sọ ṣáájú pé olùgbàlà ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu jẹ́ fún wa ni orílẹ̀-èdè yìí, wọ́n ní nítorí náà ni gbogbo àwọn ṣe ń lọ darapọ̀ mọ́ ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Uzodimma tilẹ̀ ti sọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC nìkan ló kù ní orílẹ̀-èdè yìí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, ẹni tó tún jẹ́ alága àwọn gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Hope Uzodimma ti sọ wí pé orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà ti wà ní ọ̀nà àṣelà àti ọrọ̀ rẹpẹtẹ lábẹ́ ìṣejọ́ba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Ó sọ èyí níbi ìpàdé àwọn gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kebbi pé ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu jẹ́ èyí tí yóò mú àtúntò bá ọrọ̀ ajé ní èyí tí yóò mú ayé dẹrùn gẹ́gẹ́ bí a ti ń ríi báyìí.
Èyí yóò sọ Nàìjíríà di ìlú ọlọ́rọ̀ bíi tìgbà kan, ṣíṣe àyọkúrò owó ìrànwọ́ epo bẹntiróòlù mú kí owó tó ń wọlé sí àpò ìjọba ó pọ̀ síi.
Bákan náà ni ìjọba yìí ti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tó lé ẹgbẹ̀rún ní èyí tó mú àdínkù bá ìṣẹ́ àti òṣì. Kí á tó rí ọdún díẹ̀ síi, àwọn tí ìjọba ṣètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ fún yóò ti di ọ̀gá, nìṣẹ́ bá di ohun àmúpìtàn.
Ọ̀rọ̀ Uzodimma tẹ̀síwájú pé ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló wà ní orílẹ̀-ède Nàìjíríà, APC sì ni orúkọ rẹ̀, gbogbo àwọn gómìnà àti aṣòfin ni wọ́n ń fi ojoojúmọ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nítorí ìlànà rere tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi lélẹ̀.
Bákan náà ni Nyesom Wike; ẹni tó jẹ́ mínísítà fún olú ìlú wa ti sọ pé gbogbo àwọn tí wọ́n ń bu ẹnu àtẹ́ lu òun náà ló ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nítorí pé ìṣèjọba ààrẹ ilẹ̀ yìí ní àfojúsùn rere.A mú ọ̀rọ̀ Wike wá báyìí:
Mínísítà fún olú ìlú wa; Nyesom Wike ti gbẹ́nu sí máíkì lórí ọ̀rọ̀ àwọn gómìnà tí wọ́n yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Wike wí pé èyí fi hàn pé àtìlẹyìn tí òun ń ṣe fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kò já sófo. Ó wí pé àwọn gómìnà yìí ti fìgbà kan pe òun ní igi wọ́rọ́kọ́ tó ń da iná ẹgbẹ́ òṣèlú PDP rú pé òun ń ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC, èyí tó yẹ kí wọn ó fi dúpẹ́ lọ́wọ́ òun fún líla ọ̀nà tí wọ́n le tọ̀ tí òun mú wọn mọ ọ̀nà àṣeyọrí, èébú ni wọ́n bú òun, àwọn gómìnà náà ló ti wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ẹni tó ń parọ́ ni yóò sọ pé ẹlẹ́rìí òun wà ní ọ̀run. Ìjẹ́rìí sí iṣẹ́ rere tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ń ṣe náà ni ohun tí Umahi sọ pé:
Mínísítà fún àkànṣe iṣẹ́; David Umahi ti sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ lábẹ́ ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Ó wí pé àwọn títì ọlọ́dà tí wọ́n ń ṣe lásìkò yìí yóò lò tó àádọ́ta sí ọgọ́rùn-ún ọdún kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ní bàjẹ́. Èyí jẹ́ àyípadà rere sí àwọn ọ̀nà tí ìjọba àtẹ̀yìnwá ṣe tí kìí pẹ́ bàjẹ́.
Umahi sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ojú ọ̀nà márosẹ̀ Abuja sí Kaduna sí Zaria tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́, ó wí pé wọn lo àwọn èròjà, kankéré àti irin tí yóò mú kí ọ̀nà náà ó pẹ́ pẹ́ pẹ́ nínú òjò àti ẹ̀ẹ̀rùn. Nípa báyìí, yóò lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún yóò sì tún ṣẹ́ owó kù sí àpò ìjọba.
Èrò wa yàtọ̀ sí ṣíṣe àtúnṣe ọ̀nà lọ́dọọdún bíi ti ìjọba tó lọ, àwa kìí ná ìná àpà.
Ẹni tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn ni yóò ní ààrẹ kò ṣe tó, ààrẹ ń ṣe bẹbẹ o jàre.




