Fọ́nrán kan ti gba orí ìtàkùn ayélujára kan ní èyí tó le tàbùkù ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti Nàìjíríà lápapọ̀ bí ó bá fi le jẹ́ òótọ́.
Ọlọ́pàá kan ni a rí nínú fọ́nrán náà pẹ̀lú aṣọ lọ́rùn, ẹ̀jẹ̀ ń dà ní ẹnu àti imú rẹ̀ látàrí lílù ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn èrò náà pé kí wọn ó dákun kí wọn ó fi òun sílẹ̀.
Èyí kò dá àwọn èrò náà lẹ́kun, wọ́n bò ó bí èèrè ṣe ń bo ṣúgà wọ́n sì ń tari rẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Ariwo olè, olè ni wọ́n ń pa lé ọlọ́pàá yìí lórí bí wọ́n ti ń lù ú.
A rí ọlọ́pàá mìíràn tó gbìyànjú àti gba akégbẹ́ rẹ̀ yìí kalẹ̀ àmọ́ ipá rẹ̀ kò ká àwọn èrò náà. A kò le sọ pàtó ibi tí ó ti ṣẹlẹ̀ àmọ́ ìgboro Èkó ni nítorí àwọn ọkọ̀ tó ń kọjá nínú fọ́nrán náà. Bákan náà ni a kò tíì le sọ ní pàtó oun tí ọlọ́pàá náà jí, ariwo olè olè nìkan ni ó gba inú fọ́nrán náà kan.
ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ FÈSÌ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti fèsì sí fọ́nrán yìí láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abimbola Adebisi pé àwọn ti rí fọ́nrán náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣe ìdámọ̀ ọlọ́pàá inú fọ́nrán náà àti ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ní pàtó.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún ìdájọ́ ọwọ́, ìlànà òfin ló yẹ kí wọn ó fi tọ gbogbo ẹ̀sùn àti ìṣẹ̀lẹ̀.
Láàrín àwọn TRACE àti àwọn awakọ̀ àjàgbé:
Àwọn awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù ti wa àwọn ọkọ̀ wọn dí ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn ní pàtó, Ogere. Wọ́n ń ṣe ìwọ́de tako àwọn òṣìṣẹ́ àbò ojú pópó TRACE àti àwọn yòókù pé wọ́n ń mú ọkọ̀ àwọn lọ́nà àìtọ́ wọ́n sì ń fi àwọn pa owó àìbófinmu.
Babatunde Akinbiyi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ẹ̀ka TRACE ṣe àlàyé pé àwọn àti àwọn ọmọ ogun mú awàkọ̀ àjàgbé kan tó fi ọkọ̀ rẹ̀ dí ojú pópó lọ́jọ́rú, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Ọ̀pẹ. Ọkọ̀ yìí fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ tí àwọn arìnrìnàjò ò sì rí ọ̀nà lọ.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ibùdókọ̀ ọkọ̀ àjàgbé wà fún wọn láti gbé ọkọ̀ wọn sí àmọ́ ojú pópó ni ó tẹ́ wọn lọ́rùn. Èyí tí awakọ̀ náà ó fi wá tọ ọ̀nà òfin, níṣe ló kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ jọ láti ṣe ìwọ́de náà.
Ọkọ̀ ilé iṣẹ́ Dangote ni ọkọ̀ tí wọ́n mú yìí, awakọ̀ náà lọ sí ọ́fíìsì àwọn TRACE láti gba ọkọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ àwọn ìlànà tí yóò tọ̀ fún un amọ́ ó fi apá jánú ó sì lérí pé wàhálà yóò ṣẹlẹ̀ bí wọn kò bá gbé ọkọ̀ rẹ̀ kalẹ̀. Ìbínú ló bá kúrò níbẹ̀ tó sì lọ kó àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ jọ láti dí ojú pópó ní òwúrọ̀ Ọjọ́bọ.
Ìwọ́de yìí ti dí àwọn arìnrìnàjò mọ́ ọ̀nà, ó sì tún sọ wọ́n sínú ewu. Gbogbo èyí ni láti tàbùkù ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó. A ti pẹ̀tù sí èyí nípa ríránṣẹ́ sí àwọn lọ́gàálọ́gàá.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogunlowo, Seriki Hausawa ti Ogere àti adelé adarí ẹ̀ka TRACE dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Adelé adarí ẹ̀ka TRACE; Omonayajo Elias pàṣẹ kí wọn ó dá àwọn ọkọ̀ àjàgbé tí wọ́n mú náà àti ti ẹni tó fa ìwọ́de náà padà kí wọn ó fà wọ́n lé Seriki Hausawa lọ́wọ́.
Ìgbòkègbodò ọkọ̀ ti ń já geere díẹ̀díẹ̀ àmọ́ súnkẹrẹ-fàkẹrẹ náà ò tíì tán nítorí àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ti há sọ́nà tẹ́lẹ̀.
Ǹjẹ́ awakọ̀ náà jẹ̀bi?
Ẹ̀ka tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Èkó; LASTMA ti mú awakọ̀ ọkọ̀ agbáláìsàn kan ní orí afárá Odò ìyá aláró ní àbáwọ títì Maryland látàrí pé ọ kọlu ọlọ́kadà kan tí ìyẹn sì kán lẹ́sẹ̀.
Ọkọ̀ àjàgbé kan ti jóná sí orí afárá náà lójọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, èyí ti fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ lọ́jọ́ náà. Ọkọ̀ agbáláìsàn yìí gbé aláboyún kan tó ń rọbí tó sì tún fi agolo èémí mí, ìgbìyànjú àti dóòlà ẹ̀mí aláboyún yìí ló mú kí ọkọ̀ agbáláìsàn yìí ó gba ọ̀nà àdojúkọ rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní one-way.
Eré tí ó ń sá bọ̀ náà ló mú un kọlu ọlọ́kadà kan tí ó sì kán an lẹ́sẹ̀. Ibẹ̀ náà ni àwọn LASTMA ti mú awakọ̀ yìí tí wọ́n sì fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Wọ́n gbé aláboyún náà sínú ọkọ̀ ìjọba pẹ̀lú agolo èémí náà lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì gbé ọlọ́kadà náà lọ sí ilé ìwòsàn pẹ̀lú.
Àjọ LASTMA ní àwọn kò ní fi ààyè gba ìlòdì sí òfin ọkọ̀ wíwà àti ààbò ojú pópó.
Ayọ̀ níí pani —
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga JOS mẹ́jọ ti pàdánù èmí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé ní àfẹ̀mọ́jú ọjọ́bọ, oṣù Ọ̀pẹ. A gbọ́ pé ọkọ̀ akérò tó kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pàdánu ìjánu rẹ̀ ní èyí tó mú un forí ṣánpọ́n.
Mọ́kànlá ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ọkùnrin sì ni gbogbo wọn. Àwọn tí ìjàm̀bá náà ṣe ojú wọn ṣe àlàyé pé awakọ̀ náà sá eré àsápajúdé ó sì ń jáwọ́ sọ́tùn-ún sósì láti la àwọn ọkọ̀ iwájú rẹ̀, ẹ̀ẹ̀kan náà ni kò rí ọkọ̀ náà kó ní ìjánu mọ́ tó sì padà ní ìjàm̀bá.
Méje làwọn tó kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ẹnìkan padà kú sílé ìwòsàn. Àwọn mẹ́ta yòókù ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn báyìí.
Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Plateau; Peter Longsan fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé ìjàm̀bá náà wáyé ní àdojúkọ ilé ifowópamọ́ UBA, òpópónà Zaria, ìpínlẹ̀ Plateau. Ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì lọ kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan níbi tó ti ń jáwọ́ kiri.
Inú adarí ẹ̀ka FRSC ìpínlẹ̀ Plateau bàjẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Olajide Mogaji rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe jẹ́jẹ́ lójú pópó.




