Ọwọ́ àwọn ẹṣọ́ aláàbò ÀMỌ̀TẸ́KÙN ti Ifọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan tó n fi àwọn ọmọdébìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju méjìlá lọ ṣòwò nàbì. Iye àwọn tó n gun orí àwọn ọmọdébìnrin yìí lójoojúmọ́ tó mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún kan náírà sì ni owó iṣẹ́ tí wọ́n san fún wọn. Ọ̀gá ni wọ́n n ṣiṣẹ́ sìn lójoojúmọ́.
Ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ọwọ́ pálábá wọn ségi nígbà ti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ÀMỌ̀TẸ́KÙN náà dáná ogun yá wọn ní bùbá wọn, èèyàn mẹ́ẹ̀dógún sì ni ọwọ́ bà pẹ̀lú ọ̀gá burúkú yìí tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ JOY IDEM.
Agbègbè ojú irin reluwé tó wà ní BÁNKÌ IFỌ̀, ìpínlẹ̀ Ògùn ni ọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n. Àwọn ọmọdébìnrin náà jẹ́wọ́ pé tìpá-tìkúùkù ni iṣẹ́ òwò nàbì náà ní ṣíṣe fún àwọn láti fi sin ọ̀gá bí bẹ́ẹ̀kọ́, ikú ni yóò jásí. A gbọ́ pé ọ̀gá ti ni kí wọ́n mulẹ̀ ìbúra pé àwọn kò ní tú àṣírí náà síta fún ẹnikẹ́ni.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nnkan bí owó tó tó ẹdẹ̀ẹ́gbẹ̀rin náírà, òògùn olóró, rọ́bà ìdáàbòbò, ohun afákọlágbára ìbálòpọ̀ bí i jápátá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò bá ní bùbá àwọn ẹni ibi yìí.
Ọ̀gá àgbà àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ÀMỌ̀TẸ́KÙN, Ọ̀gágun ÀLÀDÉ ADÉDIGBA ní ọmọdébìnrin mọ́kànlá ló wá láti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom tí àwọn tókù sì wá láti ìpínlẹ̀ Cross Rivers àti Delta. Àsìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo ni àṣírí ti tú pé ìbẹ̀rubojo ni àwọn ọmọdébìnrin náà fi mulẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni irú iṣẹ́ láabi tí wọ́n n ṣe. Ọ̀gá tún fá irun orí àti abẹ́ wọn fún ìmùlẹ̀ náà, èyí kìí ṣe ojú lásán ooo, JOY IDEM fẹ́ kí àwọn ọmọ náà le è máa ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti máa siṣẹ́ sìn ín.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà tí a fi orúkọ bo láṣìírí ni oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá lòun darapọ̀ mọ́ wọn, òun mulẹ̀ àṣírí, ọ̀gá JOY ní òun yóò ṣiṣẹ́ ọdún kan ṣángílítí. Ọmọdébìnrin náà ni ọkùnrin mẹ́wàá sí méjìlá ni oníbàárà òun lójoojúmọ́ pẹ̀lú owó iṣẹ́ ẹgbẹ̀rún kan lọ́wọ́ ẹnikọ̀ọ̀kan wọn tí òun yóò sì kó fún ọ̀gá Joy Idem pátápátá.
Èèmọ̀ dé ooo! Ẹ̀yin òbí àti ará, Ẹ ò ráyé lóde bí? Gbogbo wa lá ni iṣẹ́ ṣe oooo, Afúnṣọ́ la jẹ́ fún àwọn ọmọ wa, ÈDÙMÀRÈ yóò bi wa bá a ti da ẹran wọn jẹ sí. Ẹ jẹ́ a mójútó àwọn ògo wẹẹrẹ wa, Àṣá àjọ́mọgbé kò ní ṣe deede àwọn ọmọ wa. (àmí)