Ladan Zubairu ni ìmáàmù mọ́ṣáláṣí Yusuf Garko tó wà ní Maraba, ìpínlẹ̀ Kano. Ní ìdájí, Ladan yóò pe irun àkọ́kọ́ yóò sì jókòó ṣe àdúrà kó tó pe irun ẹlẹ́ẹ̀kejì. Lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Ọ̀pẹ, Ladan lọ sí mọ́ṣáláṣí láti pe ìrun gẹ́gẹ́ bíi ìṣe rẹ̀, bó ṣe jókòó pé kí ó bẹ̀rẹ̀ àdúrà ni ọkùnrin kan sún mọ́ ọn, ó fa ọ̀bẹ yọ ó sì dú u lọ́rùn.
Ọkùnrin yìí gbìyànjú àti sá lọ àmọ́ àwọn èrò lé e bá, wọ́n lù ú títí ẹ̀mí rẹ̀ fi bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ọ̀bẹ tó fi pa Ladan àti gògóńgọ́ Ladan tó yọ ni wọ́n bá nínú àpò aṣọ tó wọ̀ sọ́rùn.
Ọmọ Ladan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isa ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé bàbá òun fẹ́ràn láti máa ṣe àdúrà láàrín ìpè ìrun ìdájí àkọ́kọ́ àti èkejì. Orí àdúrà náà ló wà lọ́jọ́ Ajé tí ọkùnrin náà fi dú u lọ́rùn tó sì tún yọ gògóǹgò rẹ̀ lọ àmọ́ àwọn èrò lé e bá wọ́n sì pa òun náà.
Abdullahi Haruna Kiyawa; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ó wí pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ láti pẹ̀tù sí àdúgbò náà kí àlàáfíà le jọba padà.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sọ pé ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbo Muhammad Abdullahi Wase ni wọ́n gbé òkú àwọn èèyàn méjéèjì náà lọ fún àyẹ̀wò.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Ibrahim Adamu Bakori pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìkọlù àwọn agbébọn:
Àwọn agbébọn ya wọ́ Ora ní ibodè ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti ìpínlẹ̀ Kwara wọ́n sì gbé bàbá kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìnyì ní ẹ̀ka aṣọ́bode lọ.
A gbọ́ pé ilé ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Owolabi gan-an ni wọ́n ti kó o ní pápá mọ́ra tí wọ́n sì gbé e wọ igbó lọ.
Ìyàwó Emmanuel tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Titilayọ ṣe àlàyé pé ní ọjọ́ Ajé, ìyẹn ọjọ́ kẹẹdógún, oṣù Ọ̀pẹ ni ọkọ òun wá bá òun ní ìsọ̀, ó ní kí òun máa lọ sí ilé lọ dáná pé òun ṣì ń jáde lọ nítòun.
Titilayo ti ìsọ̀ ní aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ó sì lọ ilé láti dáná oúnjẹ alẹ́. Nígbà tó di aago méje ni àwọn agbébọn ya wọ ìlú, ilé rẹ̀ gan-an ni wọ́n mórí lé tààrà. Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé òun kò kọbi ara sí ìró ìbọn náà nítorí àwọn ọdẹ a máa wọ ìlú wá àmọ́ nígbà tó ń ró lemọ́lemọ́, òun bọ́ sínú àgbàlá láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó rí àwọn agbébọn náà tí wọ́n fo ìgànná wọlé, ó sọ ède Hausa sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú lálùbami wọ́n sì ń bèèrè owó. Ẹ̀kannáà ló gbọ́ ìró ọ̀kadà láti ìta tí wọ́n gbé ọkọ rẹ̀ lọ. Titilayọ̀ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọn ó dákun gba ọkọ rẹ̀ kalẹ̀.
Nínú ìkọlù yìí ni àwọn agbébọn náà ti yìnbọn pa olóyè ìlú nígbà tó ń bọ̀ láti oko. Olóyè Dennis ń ti oko bọ̀ ló pàdé àwọn agbébọn yìí, ó fẹ́ sá ni wọ́n bá ta á níbọn tó sì kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abiodun Ojelabi.
Ojelabi ní lọ́gán tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ni àwọn ti kán lu ìgbẹ́ láti gba ọkùnrin náà kalẹ̀, ó ní àwọn ń ṣiṣẹ́ kárakára láti ríi pé Emmanuel padà wálé. Bákan náà ló wí pé ibi tí wọ́n pa olóyè Dennis sí ti kọjá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Kwara ni yóò ṣe ìwádìí ikú rẹ̀.
Ó dé ìpínlẹ̀ Kwara náà:
Ọ̀sán gangan ni àwọn adigunjalè dá ọkọ̀ kan dúró ní Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara. Ọkọ̀ náà wà lórí ìrìn ni àwọn adigunjalè náà bíi mẹ́rin dá a lọ́nà, wọ́n yìnbọn fún awakọ̀ náà wọ́n sì kó owó tí wọ́n dì sínú páálí mẹ́rin lọ.
Ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé pé àwọn adigunjalè náà wa ọkọ̀ tiwọn dubú ọkọ̀ náà, wọ́n fi ìbọn fọ́ táyà rẹ̀ wọ́n sì tún yìnbọn fún awakọ̀ náà. Páálí bíi mẹ́rin tí wọ́n kó owó sí ni wọ́n gbé sá lọ.
Adetoun Ejire-Adeyemi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àlàyé pé nǹkan bíi aago mọ́kànlá àbọ̀ òwúrọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀. Wọ́n yìnbọn fún awakọ̀ náà ní ọwọ́ wọ́n sì gbé owó tí a kò tíì mọ iye rẹ̀ sá lọ. Wọ́n ti gbé awakọ̀ náà lọ sí ilé ìwòsàn ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ẹ̀ṣè wo ni aláboyún yìí le ṣẹ̀?
Aláboyún kan àti ọmọ rẹ̀ ọmọ oṣù mẹ́rìndínlógún kan ni àwọn kan ti pa sínú ilé wọn tí wọ́n sì tún dáná sun òkú wọn.
A gbọ́ pé ọkọ aláboyún yìí dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ àbámẹ́ta ló ríi pé ilẹ̀kùn wà ní títì sí ìta. Ó já ilẹ̀kùn náà wọlé, òkú ìyàwó rẹ̀ tó lóyún sínú àti ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún kan àbọ̀ ni ó bá lórí ìbùsùn.
Wọ́n gún obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ pa wọ́n sì tún dáná sun òkú wọn.
Ahmad Sani; ẹni tó jẹ́ adarí agbègbè náà banú jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n kọ̀ láti yan ọlọ́pàá sí abúlé náà. Ó ní àwọn dá owó jọ kọ́ àgọ́ ọlọ́pàá nítorí ètò ààbò tó mẹ́hẹ àmọ́ wọn kò yan ọlọ́pàá sí abúlé náà. Ọwọ́ Ọlọ́run ni gbogbo wọn wà.
Sani rọ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano; Ibrahim Bakori láti yan ọlọ́pàá sí abúlé náà kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí le dẹ́kun.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, Abdullahi Haruna; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.




