Ibi ètò ìsìnkú èèyàn wọn kan ni àwọn èrò náà ti ń bọ̀, ọkọ̀ ojú omi méjì ló kó wọn. Ẹ̀ẹ̀kan náà ni àwọn ọkọ̀ ojú omi méjèèjì kọlu ara wọn tí gbogbo èrò inú rẹ̀ sì dà sínú odò.
Ìjọba ìbílẹ̀ Gúsù Warri ní ìpínlẹ̀ Delta ni èyí ti ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́rú ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ebìbí ọdún 2025.
Àwọn èèyàn náà ń darí bọ̀ láti ibi tí wọ́n ti lọ sìnkú èèyàn wọn kan. Ohun tí àwọn ọlọ́fintótó wí pé ó fa ìjàmbá náà ni pé ojú ọjọ́ ṣú, àwọn awakọ̀ náà kò ríran ló fàá tí wọ́n fi kọlu ara wọn.
A kò tíì le sọ iye èèyàn tó kó sódò ní pàtó àmọ́ ó lé ní ogún àwọn èèyàn tí wọ́n fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọn kò tíì rí.
Òkú márùn-ún ni àwọn adóòlà ẹ̀mí ti rí yọ nígbà tí àwọn kan wẹ odò náà já láàyè.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nígbà tó ṣe àlàyé pé àwọn èrò náà kò wọ aṣọ adóòlà ẹ̀mí, èèyàn mẹ́fà ni wọ́n rí yọ láàyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mu omi yó, òkú márùn-ún ni wọ́n rí yọ nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì wà lábẹ́ omi.
Edafe wí pé àwọn adóòlà ẹ̀mí ṣì ń wá àwọn tó kù títí di àsìkò yìí.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìjàmbá burúkú. Emmanuel Okoro ṣe àlàyé pé àwọn èèyàn ń ké gbàjarè nínú omi náà títí wọ́n fi wọ ìsàlẹ̀ odò lọ.
Wọ́n ti kó àwọn tí wọ́n rí yọ láàyè lọ sí ilé ìwòsàn kan ní Warri fún ìtọ́jú. Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì kò tíì sọ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìbànújẹ ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ fún gbogbo àwọn ará ìpínlẹ̀ Delta, wọ́n ní bó bá ṣe pé àwọn èèyàn náà wọ aṣọ adóòlà ẹ̀mí ni, ó ṣeéṣe kí wọ́n má rì sódò.
Àsìkò ti tó fún mínísítà fún ìrìn àjò orí omi; Adegboyega Oyetola láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdàá lórí ọ̀rọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi yìí.
Pàápàá júlọ bí àwọn awakọ̀ ojú omi kìí ṣe é ní àwọn aṣọ adóòlà ẹ̀mí tí àwọn èrò yóò wọ̀ torí bí ìjàmbá ó bá wáyé. Aṣọ yìí kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn ó rì, yóò gbé wọn lẹ́fòó títí àwọn adóòlà ẹ̀mí ó fi rí wọn yọ àmọ́ àwọn awakọ̀ àti èrò kò kàá kún.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi yìí ti gba ọ̀pọlọpọ̀ ẹ̀mí. Èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Benue kìí ṣe ohun tí a le gbàgbé bọ̀rọ̀.
Ọjà ni àwọn èèyàn náà lọ ná tí wọ́n sì ń padà sílé tí wọ́n fi pàdé ikú òjìji nígbà tí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ dànù sínú alagbalúgbú omi.
Ọjà Ocholonya tó wà ní Agatu, ìpínlẹ̀ Benue ni àwọn èèyàn náà ti ń bọ̀ tí wọ́n sì ń padà sí abúlé wọn ní Apochi àti Odenyi tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Doma ní Nasarawa.
Ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ dànù sínú omi náà, àwọn èèyàn mọ́kànlá ni wọ́n rí yọ láàyè nígbà tí wọ́n ti rí òkú èèyàn ogún. Wọ́n ṣì ń wá àwọn yòókù títí di àsìkò yìí.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Agatu; Melvin James fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé obìnrin ló pọ̀jù nínú àwọn èèyàn náà tí wọ́n lọ ná ọjà ní Ocholonya, ilé wọn ni wọ́n ń padà sí kó tó di pé ọkọ̀ ojú omi wọn dànù.
Melvin wí pé òun kò le sọ pé òkú ogún èèyàn ni wọ́n ti rí nítorí pé òun kò mọ̀ dájú àmọ́ òun mọ̀ pé wọ́n rí àwọn kan yọ.
Bó bá ṣe pé àwọn èrò yìí wọ aṣọ adóòlà ẹ̀mí ni, ó ṣeéṣe kí wọ́n má ṣègbé sínú alagbalúgbú omi.
Ṣé ẹ ò gbàgbé èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó náà ní ọjọ́ keje, oṣù Ọ̀wàrà ọdún tó kọjá Àwọn èèyàn méjì ni wọn kò rí títí di ìsìn yìí.
A mú ìròyìn náà fún yín pé:
Àwọn òṣìṣẹ́ àbò orí omi àti àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì orí omi sọ̀rọ̀ nípa àwọn méjì tí wọn kò tíì rí láti ìgbà tí ìjám̀bá ọkọ ojú omi náà ti ṣẹlẹ̀.
Ọjọ́ keje, oṣù Ọ̀wàrà ni ọkọ̀ ojú omi ‘ONLY GOD 13’ tó kó èèyàn mẹ́ẹ̀dógún láti Ebute èrò lọ sí Agbádárìgì lọ dànù sínú alágbalúgbú ní Imore, Amuwo-Odofin, ìpínlẹ̀ Èkó. Ìjàm̀bá yìí wàyé nígbà tí ọkọ̀ ojú omi yìí fi ọ̀nà tirẹ̀ sílẹ̀ lọ kọlu ọkọ̀ ojú omi mìíràn tó ń bọ̀ ní jẹ́jẹ́ǹjẹ́jẹ́ tirẹ̀.
Èèyàn mẹ́wàá ni ọkọ̀ ojú omi kejì kó, márùn-ún nínú wọn farapa, mẹ́ta ló kú nígbà tí wọn kò tíì rí àwọn méjì yòókù di àsìkò yìí.
Olùdarí ilé iṣẹ́ ìrìn-àjò orí omi, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Èkó; Ọ̀gbẹ́ni Oluwadamilola Emmanuel jábọ̀ láàárọ̀ yìí pé wọ́n rí gbogbo àwọn èèyàn mẹ́ẹ̀dógún inú ọkọ̀ ‘ONLY GOD 13’ yọ lómi, wọ́n sì rí àwọn mẹ́ta inú ọkọ̀ ojú omi kejì yọ láàyè àti òkú àwọn mẹ́ta mìíràn àmọ́ wọn kò tíì rí àwọn méjì yòókù, kò sì dájú pé wọ́n le rí wọn mọ́.
Benjamin Hundeyin; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé wọn kò tíì rí àwọn méjì yòókù o.
Èèyàn mẹ́wàá ni ọkọ̀ ojú omi kejì tí ‘ONLY GOD 13; lọ kọlù kó, nínú àwọn mẹ́wàá náà, èèyàn márùn-ún ni wọ́n farapa, èèyàn mẹ́ta ló kú sínú omi náà nígbà tí wọn kò tíì rí àwọn méjì yòókù di àsìkò yìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti ilé iṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì orí omi pẹ̀lú àjọ ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú omi NIMA fi ọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti dóòlà ẹ̀mí àwọn èrò ọkọ̀ náà àmọ́ mẹ́ta ti kú nínú wọn. Àwọn méjì yòókù ni kò jọ pé wọ́n ṣì le rí wọn mọ́.
Ilé iṣẹ́ ààbò tó ń wá wọn ti ṣe tán báyìí láti dẹ́kun wíwa wọn. Àwíjàre wọn náà ni pé kò dájú pé wọ́n ṣì le rí wọn.
Èyí kò dí ìgbẹ́jọ́ aláṣẹ́ ilé iṣẹ́ náà lọ́wọ́, ó di dandan kó káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ níwájú ìjọba. Wọ́n ṣì ń wá ọkùnrin awakọ̀ náà tó wa ọkọ̀ ojú omi tí à ń sọ yìí títí di àkókò tí a kọ ìròyìn yìí.
Àfikún ni pé ìjọba ti fi òfin gbé ẹni tó ni ilé iṣẹ́ ‘ONLY GOD’ fún ẹ̀sùn ìfẹ̀mí-àwọn-èèyàn-wéwu àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tó rọ̀ mọ́ ìjàm̀bá tó wáyé náà.
Ẹ̀sùn náà ni pé awakọ̀ ojú omi náà kó ju iye èrò tó yẹ kó kó lọ ní èyí tí kò jẹ́ kó ríran rí iwájú tó fi lọ kọlu ọkọ̀ ojú omi kejì. Ẹkejì ni pé ilé iṣẹ́ náà kò tẹ̀lé àwọn àlàkalẹ̀ ìjọba nípa àwọn ohun èlò ìdábòbò fún ìrìn-àjò orí omi ní èyí tó ṣe okùnfà ìjàmbá náà.
Bákan náà ni wọ́n ní kí ó fa awakọ̀ náà kalẹ̀ fún ìjẹ́jọ́ ẹ̀sùn tirẹ̀.
Ìgbésẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ìrìn-àjò orí omi NIMA ṣe yóò jẹ́ kí àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́kọ̀ ojú omi yòókù ó sán bàǹtẹ́ wọn. Wọn yóò le mọ̀ pé kò sí ààyè fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi kankan láti fi ẹ̀mí àwọn èèyàn wé ewu.
Ṣé ẹ̀yin náà wá ríi pé àfọwọ́fà ló pọ̀ jù nínú àwọn ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi yìí?
Àsìkò ti tó fún Adegboyega Oyetola láti ṣọ́ ohun tí wọ́n fi ẹlẹ́mọ̀ṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ kó yé ṣe àyanjúràn sí ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀.