ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn

ỌKỌ̀ AKÉRÒ ÌJỌBA JÓNÁ NÍ ORÍ AFÁRÁ THIRD MAINLAND.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
January 7, 2026
in Ìròyìn, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ọkọ̀ akérò ìjọba BRT gbaná lórí afárá Third mainland ní ìtòsí ìyànà òwòrò, Èkó.
Nǹkan bíi aago kan ọ̀sán ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni èyí ṣẹ̀, a ríi kà lójú òpó LASTMA pé ọkọ̀ náà gbaná lórí eré lójijì ní èyí tó fa súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ lórí afárá náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná sa ipá wọn àwọn LASTMA náà sì ṣe tiwọn àmọ́ súnkẹrẹ ọkọ̀ náà nípọn fún àwọn awakọ̀ yòókù.
Ohun tó ṣe okùnfà iná náà kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.

ÒGIRI WÓ PA ÀWỌN ỌMỌ MÁRÙN-ÚN NÍ ÌPÍNLẸ̀ BORNO.

ADVERTISEMENT

Àwọn ọmọ mẹ́fà ní wọ́n wà ní ìtòsí ògiri ilé náà lásìkò tó dà wó, márùn-ún nínú wọn ló kù nígbà tí ọ̀kan yòókù wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ọmọ náà ń ṣeré lára ògiri ilé náà ní abúlé Bulumkutu ní Maiduguri tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́.
Òjijì ni ògiri ilé náà ṣídìí tó sì wó lu àwọn ọmọ mẹ́fà náà, márùn-ún nínú wọn ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ọ̀kan yòókù ṣì wà ní ilé ìwòsàn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti ríi dájú pé ejò kò lọ́wọ́ nínú dídàwó tí ògiri ilé náà dà wó.

BÀBÁ ẸNI ỌDÚN MÁRÙNDÌNLỌ́GỌ́TA FÚN ỌMỌBÌNRIN ỌMỌ ỌDÚN MẸ́Ẹ̀DÓGÚN LÓYÚN.

Bàbá kan ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó fún ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún lóyún.
Àlàyé láti ẹnu Abayomi Jimoh; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ni pé àwọn ará àdúgbò ríi pé ọmọbìnrin náà ti fẹ́rakù wọ́n sì pè é, wọ́n tẹ̀ ẹ́ nínú kí ó jẹ́wọ́ ẹni tó fún un lóyún.
Ọmọ yìí jẹ́wọ́ fún wọn pé ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ náà ló máa ń bá a lájọṣepọ̀, ọ̀kan lára wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adewale ló lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí tí wọ́n sì lọ gbé bàbá náà.
Ademola Joshua ni orúkọ bàbá yìí, ọmọ àbúrò rẹ̀ ni ọmọ náà tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀, bàbá yìí kò gba ẹ̀sùn náà bẹ́ẹ̀ sì ni kò kọ̀ ọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lọ́gán tí ìwádìí bá parí. Wọ́n gbé oríyìn fún àwọn ará àdúgbò náà fún àkíyèsí àti ipa wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

WỌ́N TI GBÉ ÌYÀ ÀTI ỌMỌ LỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ONDO.

Alẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta ni àwọn kan lọ ká obìnrin kan tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ mọ́lé ní ìpínlẹ̀ Ondo tí wọ́n sì gbé òun àti ọmọ rẹ̀ lọ.
Iṣẹ́ kanlékanlé ni ọkọ obìnrin yìí ń ṣe ní agbègbè Supare-Akoko, kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀. Ohun tí a rí gbà ni pé àwọn agbébọn ya wọ àdúgbò náà ilé rẹ̀ ni wọ́n sì gbà lọ tààrà, wọ́n kó obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ ní pápámọ́ra wọ́n sì gbé wọn lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwàdíì lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

PÁSÍTỌ̀ CHRIS OKAFOR TI FA ARA RẸ̀ KALẸ̀ FÚN ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ.

Pásítọ̀ àgbà ìjọ Mountain of liberation and Miracle; Pásítọ̀ Chris Okafor ti fa ara kalẹ̀ fún àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìbánilopọ̀ tí àwọn obìnrin fi kàn án.
Igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà; Sylvester Alabi ni yóò darí ìwádìí náà. Ọjọ́ Àìkú ni àwọn ọlọ́pàá ránṣẹ́ síi pé kí ó yọjú sí àgọ́ àmọ́ ó fi èsì ránṣẹ́ láti e.nu agbẹjọ́rò rẹ̀ pé òun yóò yọjú ní ọjọ́ Ajé, nígbà tí kò yọjú lọ́jọ́ Ajé ni wọ́n pàṣẹ kí wọn ó lọ gbé e àmọ́ ó fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn lọ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Jimoh Olohundare sọ lórí ìkànnì amóhùnmáwòrán TVC pé àwọn ti ṣí ìwé ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn tí àwọn obìnrin náà fi kàn án lọ́tùn-ún lósì ní èyí tó le da àlàáfíà ìlú rú, ó ní àwọ tún wá gbọ́ láti òkè pé igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà gan-an ti ṣí ìwé ìwádìí lórí rẹ̀.
Olohundare ṣe àlàyé pé àwọn ti pa ìwé tiwọn dé àwọn sì ti fa ẹjọ́ náà lé igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá lọ́wọ́ nítorí pé ipò rẹ̀ ga ju tiwọn lọ.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ìtàkùn ayélujára ti di ọ̀nà kan gbòógì tí àwọn èèyàn ti le fi ẹjọ́ sùn, ó ní àwọn kò le kọtí ikún sí ẹjọ́ tí àwọn èèyàn bá fi sùn lórí ìtàkùn ayélujára kí àlàáfíà le jọba.

ADVERTISEMENT

ÀWỌN AGBÉBỌN ṢE ÌKỌLÙ SÍ IBÙDÓKỌ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́.
Àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù sí ibùdókọ̀ tó wà ní Oloka ní ìjọba ìbílẹ̀ Orire, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn agbébọn náà kó wọ́n ní pápá mọ́ra, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀, àwọn èèyàn mẹ́rin ni wọ́n rán lọ́run àṣàǹte nígbà tí èèyàn kan wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run nílé ìwòsàn báyìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Ayanlade Olayinka. Ó ṣe àlàyé pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Femi Haruna àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò mìíràn ti ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Femi Haruna ti pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ó yí agbègbè náà ká, ìdí ni láti dẹ́kun irú ìkọlù báyìí àti láti dá àlàáfíà padà sí agbègbè náà.

ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ YÌNBỌN PA OBÌNRIN KAN.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti yìnbọn pa obìnrin kan nígbà tó fẹ́ fi ọkọ̀ rẹ̀ gun orí àwọn èṣọ́ náà lọ bẹrẹbẹ.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà ni pé obìnrin náà àti àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tí wọ́n dá a dúró jọ ní gbólóhùn asọ̀ lórí ìwé ìgbélùú rẹ̀, obìnrin yìí ṣíná sọ́kọ̀ ó sì fẹ́ gbá wọn kọjá lọ ní tirẹ̀, ọ̀kan nínú wọn ló yìnbọn fún un tó sì kú.
Àwọn èṣọ́ yìí ṣe àpèjúwe ìwà obìnrin yìí gẹ́gẹ́ bíi ìwà ìfẹ̀míṣòfò, wọ́n ní àwọn kò jẹ̀bi ìbọn ti àwọn yìn pa á wọ́n sì ti kó àwọn ẹ̀ṣọ́ tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.
Àwọn èṣọ́ aṣọ́bodè orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà ń kojú oríṣìí àdojúkọ láti ìgbà tí ààrẹ orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà; Donald Trump ti pàṣẹ fún wọn kí wọn ó fi gbogbo ẹni tí kò bá ní ìwé tó yẹ sọkò padà sí ìlú wọn.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #happenings#iweiroyinyoruba#TRENDINGNEWSTODAY#trendingpostAfojúsùn Iwe Iroyin YorubablogerbloggingdontmissitÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubanewsnewsflashnewsinyorubanewsolypolicetrendingyorubabloggeryorubablogging
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
OMIJÉ BỌ́ NÍBI ÌSÌNKÚ ÒṢÌṢẸ́ FRSC TÓ WÁYÉ NÍ ÒṢOGBO.

OMIJÉ BỌ́ NÍBI ÌSÌNKÚ ÒṢÌṢẸ́ FRSC TÓ WÁYÉ NÍ ÒṢOGBO.

Recommended

ÀBẸ̀WÒ MI SÍ ILÉ MUHAMMADU BUHARI KÒ LỌ́WỌ́ ÒṢÈLÚ NÍNÚ – EL RUFAI

ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ EL-RUFAI Ó SAN Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀RÚN MÍLÍỌ́NÙ NÁÍRÀ OWÓ ÌTANRÀN.

1 year ago
Ìròyìn Jákèjádò.

Ìròyìn Jákèjádò.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.