Ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ oníkẹ̀kẹ́ márúwa kan pa ní ìyànà Ẹkọ̀rọ̀, ojú ọ̀nà Abule Egba sí Command ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Bélú.
A gbọ́ pé ọkọ̀ àjàgbé náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré nígbà tó jáde sí ìyànà Ẹkọ̀rọ̀ tó sì lọ kọlu kẹ̀kẹ́ maruwa náà àti àwọn ọkọ̀ méjì mìíràn.
Àwọn èèyàn méjì ni wọ́n farapa nígbà tí oníkẹ̀kẹ́ náà dágbére fáyé látàrí pé ọkọ̀ náà tẹ orí rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ LASTMA ló gbé òkú oníkẹ̀kẹ́ náà kúrò tí wọ́n sì tún gbé àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.
Taofiq Adebayo; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọkọ̀ àjàgbé náà jẹ́ onítáyà mẹ́fà tí nọ́ḿbà rẹ̀ sì jẹ́ AGL 514 XD pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré, ó kọlu kẹ̀kẹ́ maruwa kan àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Honda Pilot kan, Toyota Camry kan.
Taofiq ṣe àlàyé pé awakọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ nígbà tí ìjánu náà kọ̀ láti mú un mọ́, èyí ló fà á tó fi lọ kọlu kẹ̀kẹ́ náà pẹ̀lú awakọ̀ nínú, ó tẹ kẹ̀kẹ́ náà kọjá ìdámọ̀ kó tó lọ mú àwọn ọkọ̀ méjì náà gùn lódìkejì.
Àwọn èèyàn méjì náà kò tilẹ̀ le kúrò níbi tó há wọn mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ló wá yọ wọ́n kúrò.
Taofiq Adebayo gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé ìjàm̀bá náà fa súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ díẹ̀ àmọ́ wọ́n yanjú rẹ̀.
Adarí àjọ LASTMA; Ọ̀gbẹ́ni Olalekan Bakare-Oki banujẹ́ lórí ìjàm̀bá náà, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ṣe é dabo kó má wáyé bí ọkọ̀ àjàgbé náà bá pa òfin gbèdéke eré sísá mọ́.
Ó bá àwọn ẹbí oníkẹ̀kẹ́ náà kẹ́dùn ó sì tún gbàdúrà kí Ọlọ́run mú ara àwọn tó farapa dá.
Ọ̀gbẹ́ni Bakare-Oki rọ àwọn awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé láti máa pa òfin eré sísá mọ́ kí wọ́n ó sì máa se àyẹ̀wò ọkọ̀ kí wọ́n tó gbé e sí ojú pópó.
Ní ìpínlẹ̀ Plateau, ọkọ̀ ojú irin tẹ kẹ̀kẹ́ maruwa pa lánàá yìí kan náà.
Ọkọ̀ ojú irin ti tẹ oníkẹ̀kẹ́ márúwá kan àti èrò inú rẹ̀ pa ní oríta Phototek, Abattoir ní Gúúsù Jos, ìpínlẹ̀ Plateau.
A gbọ́ pé ìjàm̀bá náà wáyé ní ọjọ́rú, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Belu ní èyí tó mú ẹ̀mí méjì lọ lójú ẹsẹ̀.
Ọkọ̀ ojú irin náà ń bọ̀ láti Bukuru lọ sí Jos, oríta Phototek yìí jẹ́ ojú ọ̀nà tí ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ ilẹ̀ ń pín lò, láti òkèrè ni ọkọ̀ ojú irin yìí ti ń fọn tantan àmọ́ oníkẹ̀kẹ́ náà ní kí òun ó sáré kọjá, ó bani lọ́kàn jẹ́ pé ọkọ̀ ojú irin náà mú un gùn mọ́lẹ̀ pẹ̀lú èrò inú rẹ̀.
Àwọn tí ìjàm̀bá náà ṣojú wọn ṣe àpèjúwe rẹ̀ bí èyí tó burú jáì. Mary Philip wí pé kẹ̀kẹ́ náà gbìyánjú àti sáré kọjá kí ọkọ̀ ojú irin náà ó tó dé àmọ́ ó káa mọ ojú ọ̀nà ó sì tẹ̀ ẹ́ wómúwómú.
Muhammed Ibrahim náà ṣe àlàyé pé ọkọ̀ ojú irin náà ń bọ̀ láti Bukuru ó sì ń lọ sí Jos, aago mọ́kànlá ló dé oríta phototek níbi tó ti tẹ oníkẹ̀kẹ́ àti èrò kan pa, àwọn èrò méjì yòókù kò kú àmọ́ wọ́n farapa yánayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin; Adam Abdullahi fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó di ẹ̀bi ìjàm̀bá náà ru awakọ̀ kẹ̀kẹ́ náà nítorí pé ó kọ̀ láti dúró pẹ̀lú bí ọkọ̀ ojú irin náà ṣe fọn tó.
Ó wí pé àwọn òṣìṣẹ́ gan-an wà níbẹ̀ tí wọ́n ń dá ọkọ̀ ilẹ̀ dúró àmọ́ síbẹ̀ oníkẹ̀kẹ́ yìí kọ̀ láti dúró.
Wọ́n ti gbé òkú wọn kúrò àmọ́ ipa náà ṣì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹran ara wọn já mọ́ ojú irin náà yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
Èyí tún jẹ́ ìjàm̀bá mìíràn tó peléke lẹ́yìn èyí tó áyé ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn láìpẹ́ yìí.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn lọ́gbọ̀njọ́, oṣù Ọ̀wàrà kọjá àfẹnuròyìn.
Ìjàm̀bá náà wáyé láàrin àwọn ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù lórí afárá Kara ní Mowe. Ìjàm̀bá yìí mú kí ọkọ̀ náà ó gbaná tí ó sì dá súnkẹrẹ-fàkẹrẹ sílẹ̀.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Èkó kọ ọ́ sí ojú òpó wọn pé ọkọ̀ àjàgbé kan tó kó ẹrù gbaná nígbà tí òmíràn dànù pẹ̀lú ọ̀pọ̀ páálí bisikí, ọkọ̀ àjàgbé mìíràn kọlu kankéré etí afárá náà ó sì ré sínú odò.
Àwọn èèyàn mẹ́jọ ló ti kú nínú ìjàm̀bá yìí nígbà tí iṣẹ́ ń lọ láti dóòlà àwọn yòókù.
Mélòó la ó kà nínú eyín adìpèlé ni ọ̀rọ̀ ìjàm̀bá ọkọ̀ dà lójú pópó lásìkò yìí. Ṣé ẹ́ rántí àwọn èyí tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun lọ́jọ́ kan náà? Ó kọjá bẹ́ẹ̀.
Ọkọ̀ Toyota kan tó kó èèyàn méje láti ìpínlẹ̀ Osun wá sí Èkó pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó ń lọ ní tirẹ̀.
Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjàmbá yìí wáyé lónìí ọjọ́ àìkú.
Ọ̀gbẹ́ni Sanni Saifullahi ló wa ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà, ọkọ̀ àjàgbé yìí ga tó ìwọ̀n ogójì ẹsẹ̀ bàtà, ilé iṣẹ́ Ay and Rolly’s ventures tó wà ní Magodo, ìpínlẹ̀ Èkó ló ni ọkọ̀ àjàgbé yìí.
Ọgbẹ́ni Sunday Okpe ti ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló wa ọkọ̀ Sienna yìí.
Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ọ̀gbẹ́ni Sunday ti gbéra pẹ̀lú èrò méje, ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ìta Olúwo, Ìkòròdú ni ọkọ̀ yìí ti pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà.
Arábìnrin Miracle Chibuzor tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló jókòó níwájú, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá yìí, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn fara pa yánnayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn pé arábìnrin Miracle pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ló kó àwọn márùn-ún tí wọ́n farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn Falobis tó wà ní Mowe fún ìtọ́jú.
Wọ́n gbé òkú arábìnrin Miracle lọ sí ilé ìgbókùúsí Idera fún àyẹ̀wò àti ìwé ẹ̀rí.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wọ́ àwọn ọkọ̀ méjèèjì náà lọ sí àgọ́ wọn tó wà ní Shagamu kí àwọn òṣìṣẹ́ VIO le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Ìjàmbá ọkọ̀ mìíràn wáyé ní ìta Olúwo yìí kan náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ àárọ̀.
Arábìnrin kan tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ni ó jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ márúwá lẹ́nu tó sì padà gbé ẹ̀mí mìn.
Usman Abdullah; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ló wa kẹ̀kẹ́ TVS náà, obìnrin yìí fẹ́ sọdá títì ló jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ Abdullahi lẹ́nu, orí ló fi ṣèṣe. Àwọn èèyàn ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn Omowunmi tó wà ní Kusela, Ogijo àmọ́ obìnrin yìí padà jẹ́ ìpè Elédùà.
Àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀, wọ́n ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì wọ́ kẹ̀kẹ́ náà lọ sí àgọ́ wọn. Abdullahi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìwádìí lórí bí ìjàmbá náà ṣe wáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kòrò ojú sí ìjàmbá méjèèjì yìí, wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé ní èyí tó le mú kí ìjàmbá ọkọ̀ ó wáyé, bákan náà ni wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti má màa sún mọ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò pẹ́kípẹ́kí.







