Ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan ló fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ ní Apapa, Iyana Isolo ní ìpínlẹ̀ Èkó, ọkọ̀ yìí gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Ọkọ̀ àjàgbé agbépo yìí ló forí gbárí pẹ̀lú ọkọ̀ korope kan tí àwọn tírélà méjì mìíràn náà sì sá wọnú ara wọn.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkọ̀ àjàgbé agbépo yìí gbaná, àwọn èèyàn sá àsálà fún ẹ̀mí wọn àmọ́ àwọn mẹ́ta kan há sínú ọkọ̀ korope náà. Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ati ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ló wá pa iná náà tí wọ́n sì yọ àwọn mẹ́ta náà àmọ́ iná náà jó wọn dé ààyè kan.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu ọ̀gá àgbà ẹ̀ka ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó; Fadairo Maria pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní aago kan ọ̀sán kọjá, àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀ wọ́n sì pa iná náà.
Apapa ni ọkọ̀ àjàgbé agbépo náà ti gbéra tó sì ń lọ sí Oshodi kó tó di pé ó ní ìjàmbá ní Iyana Isolo.
Àwọn èèyàn ti rápálá jáde láti dóòlà ẹ̀mí wọn àmọ́ àwọn mẹ́ta kan há sínú ọkọ̀ korope náà kó tó di pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná wá yọ wọ́n.
Margaret Adeseye; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ náà rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe pẹ̀lẹ́ lójú pópó kí irú ìjàmbá yìí má bàa ṣẹlẹ̀ mọ́.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ lójú pópó náà sọ nípa ìjàmbá yìí, wọ́n ní ọkọ̀ àjàgbé agbépo náà pàdánù ìjánu rẹ̀ nígbà tó fẹ́ ṣẹ́ kọ́nà ìyànà Oshodi náà ló fà á tó fi lọ kọlu ọkọ̀ korope náà.
Àjọ LASTMA ní àwọn náà sáré dé ibẹ̀ láti kún àwọn òṣìṣẹ́ panápaná lọ́wọ́ láti yọ àwọn èèyàn náà.
Bakare Oki; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ LASTMA ṣe àlàyé pé kò sí ẹni tó kú nínú ìjàmbá náà, àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA sa ipá wọn láti gba àwọn èèyàn náà kalẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n darí ìgbòkègbodò ọkọ̀ láti ṣe àdínkù sí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ lójú pópó náà.
Nínú oṣù Okúdù ni ìjàmbá ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan wáyé lórí afárá Otedola tí àwọn èèyàn ò le gbàgbẹ́ bọ̀rọ̀.
Ìjàmbá yìí mú ẹ̀mí tọkọtaya àṣẹ̀ṣẹ̀fẹ́ kan lọ lójijì.
Ọ̀sẹ̀ kẹta lẹ́yìn tí tọkọ-tayà ṣègbéyàwó, tí wọ́n filé pọn ọtí, fi ọ̀nà rokà; tí inú ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ n dùn ṣìkìn fún wọn, tí ẹbí àti ará n wúre pé ọkọ yóò gbó, ìyáwó yóò kùtà, pé ẹ̀yìn ìyàwó kò ní mẹní, pé lẹ́yìn oṣù mésàn án, a ó wá b’áwọn gbọ́wọ́ ṣíbí ìbejì lẹ́yìn ti ìyàwó ti finúṣoyún yóò fẹ̀yìn gbọ́mọ pọ̀n, pé tọkọ tayà yóò gbó kùjẹ́-kùjẹ́ ṣùgbọ́n ikú dóró, ikú ṣebí, ikú kò gbowó,ikú kò gbobì, ikú kọ̀ kò ṣe é tù lójú, ikú wólé ọlá, ikú sọ ilé ọlá di ahoro.
Ìjàmba iná yìí tún dá ẹ̀mí Mẹkáníìkì Olóòtú ìwé Ìròyìn Eagle légbodò lọ́jọ́ yìí.
Dotun Oladapo sọ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán TVC bí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣe bani lọ́kàn jẹ́ gidigidi, nítorí ṣe ni Rotimi Adeleye ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọkọ̀ Toyota ìyàwó rẹ̀ tán ni, Ó sì sọ pé kí n wá yẹ̀ ẹ́ wó pé ó ti n ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mò n gbọ́ tí Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ náà n kígbe ‘Ọkọ̀ yìí kò ní ìjánu!’ a ò tilẹ̀ tètè gbọ́ nítorí fèrèsé wà ní títì pa ṣùgbọ́n nígbà tí a máa fi gbọ́, ó ti pẹ́ jù , ní mo bá n ké tantan fún Rotimi kó kúrò lójú ọ̀nà àmọ́ kò gbọ́, àṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rin ìhòhò wọ ọjà.
Ní bàyìí, àwọn Aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ kàn ti n ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. A gbọ́ pé ènìyàn márùn-ún ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èrò tètè dù ẹ̀mí wọn lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Gbàgádà ṣùgbọ́n àìsàn ni a rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Èlòmìíràn tó tún bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná náà lọ ní ọ̀gbẹ́ni Akintayo Akintoye.
Ó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn náà:
Àwọn arìnrìnàjò há sí ojú ònà lónìí nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan ṣàdédé gbaná lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn.
Àárín Ọ̀rẹ́méjì sí Ọlọ́runṣògo ni ọkọ̀ náà ti gbaná ní èyí tó fa kí àwọn èèyàn ó má le kọjá.
Kò sí ẹni tó bá ìjàmbá yìí lọ, ó kàn jẹ́ pé àwọn èèyàn kò le kọjá lọ ibi tí wọ́n ń lọ ni.
Iná náà pọ̀ gan-an àmọ́ kò mú ẹ̀mí lọ, àwọn panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ló ta mọ́ra dé ibẹ̀ láti kojú rẹ̀.
Adarí ilé iṣé panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́; Ọ̀gbẹ́ni Akinyemi Akinyinka fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ti yára kojú iná náà láti ṣẹ́gun rẹ̀.
Bákan náà ni iná jó ọkọ̀ ní Abuja:
Ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé afẹ́fẹ́ tí ọkọ̀ le mú sàgbára CNG ló pàdánù ìjánu rẹ̀ ní ìtòsí afárá Karu ní Abuja.
Ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́rú ni ìjàmbá yìí wáyé, ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì lọ kọlu ọkọ̀ mìíràn, kíá ni iná sẹ́yò tí ó sì ràn kárí láàárín ìṣẹ́jú àáyá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí iná yìí ká mọ́ inú ọkọ̀ ni iná yìí ti mú balẹ̀, a kò tíì le sọ ní pàtó iye ènìyàn tí ó ti bá ìsẹ̀lẹ̀ yii rìn.
Nínú fọ́nrán tí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan gbé jáde ni àwọn èèyàn ti ń kígbe tí wọ́n sì ń jó nínú iná náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àti ẹ̀ka mìíràn tọ́rọ̀ kàn dé níbẹ̀.
A kò ní ríjà iná ọ, àṣẹ.





