Nígbà tí àwọn èèyàn ṣì ń japoró ìjàm̀bá ọkọ̀ agbépo tó wáyé ní ẹnu ìloro ìpínlẹ̀ Ogun lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọkọ̀ agbépo mìíràn tú tẹ àwọn èèyàn pa ní oríta Ẹkọ̀rọ̀, ojú ọ̀nà Meirn ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ agbépo náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ni ó bá rọ́ lu àwọn ìsọ̀ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ojú pópó náà, gbogbo àwọn tí wọ́n ń ta ọjà ní ìtòsí ibẹ̀ ni ó fara gbá nínú ìjàm̀bá náà.
Nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Ẹtì ni ìjàm̀bá náà wáyé ní oríta Ẹkọ̀rọ̀, ọkọ̀ agbépo náà kọ́kọ́ tẹ ọkọ̀ Corolla kan kí ó tó wọ́ ọ mọ́ àwọn ìsọ̀ náà.
Ìjàm̀bá náà pọ̀ gan-an tí àwọn ìsọ̀ náà wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, èèyàn kan ló kú lójú ẹsẹ̀ àmọ́ àwọn tó farapa lé ní mẹ́rin.
Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ adarí ẹ̀ka ọ̀rọ̀ ìlú ilé iṣẹ́ LASTMA ló ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ ní kíá, wọ́n gbé òkú èèyàn kan wọ́n sì yọ àwọn mẹ́rin mìíràn tí wọ́n há sínú àwọn èérún ọkọ̀ àti ìsọ̀ náà. Ó gbà wọ́n lómi díẹ̀ kí wọ́n tó rí àwọn èèyàn náà yọ níbi tí ìjàm̀bá náà burú dé. Kò dájú pé àwọn ẹni náà yóò fi ẹsẹ̀ wọn rìn lọ́dún yìí níbi tó burú dé.
Ọ̀rọ̀ Taofiq tẹ̀síwájú pé àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA darí ọkọ̀ ní agbègbè náà láti dín súnkẹrẹ-fàkẹrẹ̀ ọkọ̀ kù, wọ́n ṣe ìtọ́jú òkú ẹni tó kú náà wọ́n sì tún ṣe ìtọ́jú àwọn tó farapa ṣáájú kí ọkọ̀ agbáláìsàn tó dé.
Lẹ́yìn tí ọkọ̀ agbáláìsàn kó àwon ẹni náà lọ sílé ìwòsàn ni wọ́n wọ́ ìyókù ọkọ̀ agbépo náà kúrò lójú pópó tí wọ́n sì kó ìyókù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, òun kò fẹ́rẹ̀ ṣẹ́kù tààrà ní tirẹ̀, ìtẹ̀kutẹ̀ ni ọkọ̀ agbépo náà tẹ̀ ẹ́.
Ọ̀rọ̀ yìí dé etígbọ́ adarí àgbà àjọ LASTMA; Olalekan Bakare-Oki, ó banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó sì bá àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n pàdánù èèyàn wọn kẹ́dùn.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Bakare rọ àwọn awakọ̀ láti máa ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ wọn kí wọ́n tó gbé e sí ojú pópó, ó ní púpọ̀ nínú àwọn ìjàm̀bá báyìí ló jẹ́ pé awakọ̀ ló dágúnlá àwọn àpẹẹrẹ tí ọkọ̀ náà ti ń fún un.
Ó ṣe ìlérí pé àwọn yóò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìjàm̀bá náà, ẹni tí aje rẹ̀ bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ojú winá òfin.
Èèyàn mélòó ni ọkọ̀ agbépo yóò pa? Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkọ̀ agbépo yóò pàdánù ìjánu rẹ̀, ó ṣẹlẹ̀ ní ẹnu ìloro ìpínlẹ̀ Ogun lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí níbi tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti bọ́.
Bí kò ṣe ọkọ̀ agbépo a sì ṣe ọkọ̀ ajàgbé, ìjánu wọn kìí yé daṣẹ́ sílẹ̀, nínú oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá yìí ni ọ̀kan ṣe ọṣẹ́ ní ibùdókọ̀ Meiran, ẹ̀mí èèyàn méjì ló bọ́ ní fọnnáfọnṣu. Ṣé ẹ rántí?
Nǹkan bíi aago mẹ́fà àbọ̀ ìdájí ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Ọ̀pẹ ni ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan pàdánù ìjánu rẹ̀ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Meiran Alágbàdo, awakọ̀ náà gbìyànjú àti fi ọkọ̀ náà kọlu ògiri ni ó fi yà bàrà sí òpópónà Meiran, ó fi orí sọ ògiri lóòótọ́ àmọ́ kò ṣàì má mú ẹ̀mí àwọn èèyàn méjì dání.
Odidi kẹ̀kẹ́ márúwá kan ló gbé nílẹ̀ tó sì wọ́ rọ́lu ògiri ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní oríta Meiran náà. Bákan náà ló tẹ ọkọ̀ kórópe kan àti kẹ̀kẹ́ bíi mẹ́rin mìíràn wómúwómú.
Àwọn èrò inú kórópe náà sá àsálà fún ẹ̀mí wọn, wọ́n sá jáde wọ́n sì yè àmọ́ wọn kò ṣaláì má farapa.
Àwọn èèyàn mìíràn náà fi ara gbá nínú ìjàm̀bá yìí, àwọn kan ń lọ tiwọn nígbà tí àwọn mìíràn ń ṣòwò wọn lọ́wọ́ lásìkò ìjàm̀bá náà.
Méjì ni àwọn èèyàn tó kú níbi ìjàm̀bá yìí nígbà tí àwọn yòókù ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Lára àwọn tó kú yìí ni olùkọ́ ilé ìwé kan tí kò jìnnà sí Meiran, olùkọ́ yìí kúrò ní ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ lọ ra oúnjẹ jẹ ní oríta náà nígbà tí ó ṣe àgbákò ìkọlù náà.
Abala ogiri ilé ìwòsàn náà rún wómúwómú, àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwòsàn náà kò sí nínú yàrá kótópó wọn ni orí fi kó wọn yọ nítorí inú yàrá náà gan-an ni ọkọ̀ náà balẹ̀ sí.
Àwọn ọlọ́pàá Meiran àti àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ni wọ́n yọ àwọn tó há sí inú èérún àwọn kẹ̀kẹ́ márúwá náà àti inú ògiri ilé ìwòsàn náà.
Awakọ̀ àjàgbé náà tó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ Dangote fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ lẹ́yìn ìkọlù náà, àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ sí wá a báyìí.
Taofik Adebayo; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde. Ó ṣe àlàyé pé ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lójijì lórí eré ó sì yà wọ inú òpópónà Meiran, ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ ló tẹ̀ nítorí ibùdó wọn ni oríta náà bẹ́ẹ̀ sì ni ó tẹ ọkọ̀ kórópe kan kan látẹ̀rún wómúwómú.
Adarí àjọ LASTMA; Ọ̀gbẹ́ni Bakare Oki bá ẹbí àwọn tó kú náà kẹ́dùn ó sì gbàdúrà ìmúláradá fún àwọn tó farapa.

Ká tún padà sí Ẹkọ̀rọ̀, ìjàm̀bá kan wáyé ní ìyànà Ẹkọ̀rọ̀ tó yẹ ká mú wá sí ìrántí yín lórí ìjánu àwọn ọkọ̀ àjàgbé yìí kan náà:
Ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ oníkẹ̀kẹ́ márúwa kan pa ní ìyànà Ẹkọ̀rọ̀, ojú ọ̀nà Abule Egba sí Command ní òwúrọ̀ Ọjọ́rú, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Bélú.
A gbọ́ pé ọkọ̀ àjàgbé náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré nígbà tó jáde sí ìyànà Ẹkọ̀rọ̀ tó sì lọ kọlu kẹ̀kẹ́ maruwa náà àti àwọn ọkọ̀ méjì mìíràn.
Àwọn èèyàn méjì ni wọ́n farapa nígbà tí oníkẹ̀kẹ́ náà dágbére fáyé látàrí pé ọkọ̀ náà tẹ orí rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ LASTMA ló gbé òkú oníkẹ̀kẹ́ náà kúrò tí wọ́n sì tún gbé àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.
Taofiq Adebayo; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọkọ̀ àjàgbé náà jẹ́ onítáyà mẹ́fà tí nọ́ḿbà rẹ̀ sì jẹ́ AGL 514 XD pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré, ó kọlu kẹ̀kẹ́ maruwa kan àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Honda Pilot kan, Toyota Camry kan.
Taofiq ṣe àlàyé pé awakọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ nígbà tí ìjánu náà kọ̀ láti mú un mọ́, èyí ló fà á tó fi lọ kọlu kẹ̀kẹ́ náà pẹ̀lú awakọ̀ nínú, ó tẹ kẹ̀kẹ́ náà kọjá ìdámọ̀ kó tó lọ mú àwọn ọkọ̀ méjì náà gùn lódìkejì.
Àwọn èèyàn méjì náà kò tilẹ̀ le kúrò níbi tó há wọn mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ló wá yọ wọ́n kúrò.
Taofiq Adebayo gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé ìjàm̀bá náà fa súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ díẹ̀ àmọ́ wọ́n yanjú rẹ̀.
Adarí àjọ LASTMA; Ọ̀gbẹ́ni Olalekan Bakare-Oki banujẹ́ lórí ìjàm̀bá náà, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ṣe é dabo kó má wáyé bí ọkọ̀ àjàgbé náà bá pa òfin gbèdéke eré sísá mọ́.
Ó bá àwọn ẹbí oníkẹ̀kẹ́ náà kẹ́dùn ó sì tún gbàdúrà kí Ọlọ́run mú ara àwọn tó farapa dá.
Ọ̀gbẹ́ni Bakare-Oki rọ àwọn awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé láti máa pa òfin eré sísá mọ́ kí wọ́n ó sì máa se àyẹ̀wò ọkọ̀ kí wọ́n tó gbé e sí ojú pópó.

Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ Olalekan Bakare-Oki, àfọwọ́fà látàrí ìdágunlá ló ń fa ọ̀pọ̀ àwọn ìjàm̀bá yìí, ìgbà wo ni àtúnṣe yóò wà?




