ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

OJORA TI IJORA RỌ ÀWỌN OLÓYÈ MẸ́FÀ LÓYÈ NÍTORÍ PÉ WỌ́N LỌ SÍ IBI ÌPOLONGO ÌBÒ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR.

Àti àwọn ìròyìn mìíràn tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
July 1, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìròyìn, Ìròyìn Tó Gbòde
0
Ìròyìn Jákèjádò.
0
SHARES
10
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ojora ti ìlú Ijora; Ọba AbdulFatai Oyegbemi ti rọ àwọn olóyè mẹ́fà lóyè nítorí pé wọ́n lọ sí ibi ìpolongo ìbò ẹgbẹ́ òṣèlú Labour.
Ojora wí pé ohun tí wọ́n ṣe yìí lòdì sí ojúṣe wọn láàfin, ó wí pé wọn kò gba àṣẹ lẹ́nu Ọba kí wọ́n tó lọ síbi ìpolongo náà.
Ó wí pé ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé Ojora ṣe àtìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ní èyí tí òun kò sì mọ̀ nípa rẹ̀.
Àwọn olóyè tọ́rọ̀ kàn náà ni Olóyè Lateef Ojora; baálẹ̀ Alaba Oro, Olóyè Saliu Biliamin; baálẹ̀ Alafia Dodoro, Olóyè Taiwo Hassan; baálẹ̀ Oke ira, Olóyè Idris Ojora; baálẹ̀ Abule kere, Olóyè Hakeem Oseni; baálẹ̀ Mosafejo Amukoko àti Olóyè Sule Balogun.
Ojora pe àwọn lóyèlóyè, Balógun àti ìgbìmọ̀ afọbajẹ jọ níbi tó ti sọ gbangba gbàǹgbà pé ohun tí àwọn olóyè mẹ́fà náà ṣe tàbùkù bá ipò òun, ó sì pàṣẹ kí wọn ó lọ rọ́kún nílé.

ÀGBÀRÁ ÒJÒ WỌ́ ỌMỌDÉKÙNRIN KAN LỌ NÍ ÌPÍNLẸ̀ GOMBE.

Òkú ọmọdékùnrin kan ni wọ́n rí ní òjú àgbàrá ní Hayin Kwarin Misau ní ìpínlẹ̀ Gombe.
Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá kan rọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé kí wọn ó tó rí òkú ọmọ náà ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Kò sí ẹni tó mọ ọmọ yìí ní agbègbè náà, wọ́n ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé láti agbègbè mìíràn ni àgbàrá òjó ti wọ́ ọ wá.
Àyẹ̀wò àwọn òṣìṣẹ́ ìlera fi hàn pé ọmọ náà mu omi kú ni ní èyí tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àgbàrá òjò ló gbé e.
Wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ sí ilé ìgbókùúsí ti ilé ìwòsàn ìjọba Gombe. Ìjọba Gombe kéde pé ẹni tó bá mọ ọmọ náà kó ta àwọn lólobó kí wọn ó le kàn sí àwọn èèyàn rẹ̀.
ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ṢE ÌWỌ́DE TAKO ÀYÍPADÀ ORÚKỌ ILÉ ÌWÉ WỌN.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga The Polytechinc, Ibadan ti tú jáde báyìí láti ṣe ìwọ́de tako àyípadà orúkọ ilé ìwé náà sí Omololu Olunloyo Polytechnic.
Ìwọ́de yìí ti dá súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ ní ojú ọ̀nà Sango sí Eleyele.
Gómìnà Seyi Makinde ló ṣe àyípadà orúkọ ilé ìwé náà ní ìrántí Olololu Olunloyo tó papodà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún.
Ìròyìn fi yé wa pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti dí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ilẹ́ ìwé náà.

ADVERTISEMENT

ÒKÚ DANTATA TI BALẸ̀ SÍ SAUDI FÚN OORUN ÌKẸYÌN.

Wọ́n ti gbé òkú Aminu Dantata dé Saudi níbi tí yóò sùn báyìí.
Ìròyìn fi yé wa pé àwọn ìdíwó ètò ìwé àṣẹ ló fàá tó fi di òní kí wọn ó tó gbé e dé Saudi.
Ní báyìí, òkú Dantata ti dé Saudi láti Dubai, àwọn ẹbí, ará àti aṣojú láti Nàijíríà náà ti balẹ̀ sí ọ̀hún láti àná. Ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́.

ADVERTISEMENT

A KÒ ṢE ÀFIKÚN ỌJỌ́ ÌSÌNLÚ RAYE – ÀJỌ AGÙNBÁNIRỌ̀.

Àjọ agùnbánirọ̀ ilẹ̀ yìí NYSC ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tó ń jà ràìnràìn lórí ìtàkùn ayélujára pé àwọn fi ọjọ́ kún iye ọjọ́ tí Raye ó fi sin ìlú.
Rita Uguamaye tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Raye ni ọmọbìnrin tó bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣejọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Àjọ NYSC wí pé àwọn ti yọwọ́ nínú ohun tí ọmọ náà ṣe pé àwọn kò ṣe àfikún iye ọjọ́ ìsìnrú ìlú rẹ̀.
Ohun tí Raye sọ nínú fọ́nrán tó fi bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣejọba Ààrẹ Tinubu ni pé ọrọ̀ ajé ti dorí kodò, gbogbo nǹkan ló gbówó lórí tí Tinubu kò sì bìkítà rárá, ó ṣe àpèjúwe Tinubu gẹ́gẹ́ bíi Olórí burúkú.
Lẹ́yìn tó ṣe fọ́nrán yìí ni ó padà ké gbajàre pé àwọn kan ń dúnkokò mọ́ òun bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn òṣìṣẹ́ àjọ NYSC ń halẹ̀ mọ́ òun. Lọ́jọ́ tí ọ̀gá rẹ̀ ní NYSC pè é sí ìpàdé, Omoyele Sowore àti àwọn mìíràn tẹ̀lé e lọ àmọ́ ọ̀gá náà kò yọjú.
A kò gbọ́ nǹkan kan mọ́ lórí rẹ̀ títí di àsìkò yìí tó tún wá sọ pé àjọ NYSC ti fi oṣù mẹjì kún iye ọjọ́ tó yẹ kí òun ó lò, ó wí pé nítorí ohun tí òun sọ nígbà náà ni wọ́n ṣe ṣe bẹ́ẹ̀.
Ní èsì sí èyí, Omoyele Sowore kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé àwọn yóò ya bo ibi ayẹyẹ ìjáde àwọn agùnbánirọ̀ bí wọn kò bá jẹ́ kí Raye ó bá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ jáde.
Alukoro fún àjọ NYSC; Carol Embu náà fèsì pé Sowore kò já mọ́ nǹkankan nínú àjọ NYSC kò sì le è pàṣẹ fún àwọn. Ó ní àwọn kò ṣe àfikún fún Raye àmọ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá gba àfikún, òfin wà tí àwọn yóò tẹ̀lé kìí ṣe Sowore ni yóò sọ ohun tí àwọn yóò ṣe.

ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDE NÀÌJÍRÍÀ KÚ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDE INDIA.

Agbo Onyeka; ẹni tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Uguru ní Nsukka, ìpínlẹ̀ Enugu ti dákẹ́ sí ilé ìwòsàn Greater Noida ní Uttar Pradesh, India.
Sky ni ìnagijẹ Onyeka, a kò ní àrídájú ohun tó ṣe okùnfà ikú rẹ̀. Ẹ̀rí tí a rí kò ju fọ́nrán kan tí arábìnrin kan ṣe níbi tí a ti rí Onyeka lórí ibùsùn nílé iwòsàn náà tí ṣòkòtò rẹ̀ sì tùtù jẹ̀bẹ̀tẹ̀.
Obìnrin tó ká fọ́nrán yìí tó ń dárò Onyeka lábẹ́lẹ̀ ló fi hàn pé Onyeka ti dágbere fáyé.
Àwọn ọ̀rẹ́ Onyeka wí pé Onyeka ti kú láti bíi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn àmọ́ wọn kò mọ bí wọn yóò ṣe túfọ̀ rẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀ ni kó tó di pé fọ́nrán náà jáde síta.

ÀWỌN AGBÉBỌN DÁ ỌKỌ̀ AKÉRÒ LỌ́NÀ, WỌ́N KÓ ÀWỌN ARÌNRÌNÀJÒ LỌ.

Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ akérò ilé iṣẹ́ Benue links wọ́n sì kó àwọn èrò mọ́kànlá àti awakọ̀ inú rẹ̀ lọ.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ọkọ̀ náà gbéra ní Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ó sì ń lọ sí Makurdi tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Benue.
Nígbà tí wọ́n dé Eke Elengbecho ní ìjọba ìbílẹ̀ Okpokwu, àwọn agbébọn dá wọn lọ́nà wọ́n sì kó gbogbo wọn lọ. Méjìlá ni àwọn èrò náà awakọ̀ ló ṣìkẹtàlá, ẹnìkan ló ríbi sá lọ nínú wọn tó fi jẹ́ mọ́kànlá àti awakọ̀ ni wọ́n kó wọ igbó lọ.
Ẹni tó sá yìí ló lọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí ní àgọ́ tó wà ní Eke.
Johnson Daniel; ẹni tó jẹ́ olùfitónilétí ilé iṣẹ́ Benue links fi àtẹ̀jáde kan léde, nínú rẹ̀ ló ti sọ pé àwọn ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò láti ṣe àwárí àwọn èèyàn náà láàyè.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newsupdatesÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubakidnappingnewsinyorubanewsonlinetrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
TUFACE RA ÀWỌN AṢỌ TITUN FÚN ÌFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA

OBÌNRIN KAN KÒ LE TẸ́ ỌKÙNRIN LỌ́RÙN – TUFACE.

Recommended

ÈMI KỌ́ OOO, MI Ò MỌ NNKANKAN NÍPA ÀÌSÀN RẸ̀, MO F’ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ

ÈMI KỌ́ OOO, MI Ò MỌ NNKANKAN NÍPA ÀÌSÀN RẸ̀, MO F’ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ

1 year ago
ÀWỌN AJÀFẸ́TỌ̀Ọ́MỌNÌYÀN BU ẸNU ÀTẸ́ LU ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ LÓRÍ OHUN TÍ WỌ́N ṢE FÚN ÀWỌN AFẸ̀HÓNÚHÀN.

ÀWỌN AJÀFẸ́TỌ̀Ọ́MỌNÌYÀN BU ẸNU ÀTẸ́ LU ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ LÓRÍ OHUN TÍ WỌ́N ṢE FÚN ÀWỌN AFẸ̀HÓNÚHÀN.

4 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.