ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Ìfipábánilò

ÒJÍṢẸ́ ỌLỌ́RUN NI PÁSÍTỌ WA – ÀWỌN ỌMỌ ÌJỌ GBÈJÀ PÁSÍTỌ̀ CHRIS OKAFOR.

Àlága ìgbìmọ̀ àwọn pásítọ rọ ilé ìjọ́sìn mountain of liberation láti fún pásítọ̀ chris ní àǹfààní ẹlẹ́ẹ̀kejì.

by Adeola Olanrewaju
January 4, 2026
in Ìfipábánilò, Ìròyìn
0
ÀWỌN OBÌNRIN FI Ẹ̀SÙN ÌBÁLÒPỌ̀ KAN PÁSÍTỌ̀ CHRIS OKAFOR.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn akọ̀ròyìn ṣe àbẹ̀wò sí ìjọ Mountain of Liberation and Miracle Ministries tí Pásítọ̀ Chris Okafor ti jẹ́ pásítọ̀ àgbà láti gbọ́ ìhà àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí àwọn obìnrin fi kan Pásítọ̀ Chris.
Àwọn ọ̀dọ́ obìnrin méjì kan ni a kọ́kọ́ rí, wọ́n ní àwọn kò ní ohunkóhun láti sọ lórí ẹ̀sùn náà nítorí pé Pásítọ̀ Chris ti fi gbogbo rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àmọ́ àwọn àgbà ìjọ náà tí a rí da ọ̀rọ̀ náà nù, wọ́n ní irọ́ àti ète láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà.
Alàgbà Ruben Alufe sọ pé irọ́ ni gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ kiri níta náà, èèyàn ire ni Pásítọ̀ Chris, wọ́n kàn fẹ́ ba orúkọ rẹ̀ jẹ́ ni.
Alàgbà Alufe ní ogún ọdún ni òun ti lò nílé ìjọsìn náà àti pé ìsọ̀ ìyàwó rẹ̀ wà ní iwájú ilé ìjọsìn náà nítorí náà, mo mọ Pásítọ̀ Chris dáadáa.
Kín ni ìdí tí àwọn èèyàn ó ṣe pa irọ́ bàǹtàbanta mọ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run? Pẹ̀lú gbogbo dáadáa tí Pásítọ̀ Chris ti ṣe ní àdúgbò náà, òun ló ṣe títì ọlọ́dà òpópónà ilé ìjọsìn náà, ṣé irú èèyàn ire báyìí ni ó wá hu adúrú ìwà ìbàjẹ́ yìí? Irọ́ ni wọ́n pa mọ́ ọn. Alàgbà Alufe ló sọ bẹ́ẹ̀.
Alàgbà mìíràn náà kín ọ̀rọ̀ Alàgbà Alufe lẹ́yìn, ó ní àsìkò tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà jáde fi hàn pé irọ́ ni, ibo ni wọ́n wà kí Pásítọ̀ Chris tó ṣe ìgbéyàwó? Wọ́n kàn ń jowú ìyàwó rẹ̀ lásán ni.
Owó ni wọ́n fẹ́ gbà lọ́wọ́ Pásítọ̀ Chris tí wọ́n fi fẹ́ ba orúkọ rẹ̀ jẹ́, kò jọ wá lójú nítorí ara àwọn àdojúkọ tó máa ń wá pẹ̀lú iṣẹ́ ìránṣẹ́ lèyí.
Èmi le fi ọwọ́ sọ̀yà pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni Pásítọ̀ Chris àti pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ ọn –Alàgbà.

Ọ̀rọ̀ náà ti dé etí ìgbìmọ̀ CAN, ẹ ka ohun tí alága sọ:

Àlága ìgbìmọ̀ àwọn Pásítọ̀ CAN; Pásítọ̀ Stephen Adegbite rọ ilé ìjọsìn Mountain of Liberation and Miracle Ministries láti ṣe àforíjìn fún Pásítọ̀ Chris Okafor kí wọ̣́n sì fún un ní àǹfààní ẹlẹ́ẹ̀kejì láti máa bá iṣẹ́ Olúwa lọ.
Ó wí pé níwọ̀n ìgbà tí ó ti kúnlẹ̀ níwájú ìjọ tó sì tọrọ àforíjìn, niwọ̀n ìgbà tí ó ti ronú pìwàdà tó sì bèèrè fún ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ le padà jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ọmọlẹ́yìn.
Pásítiọ̀ Adegbite rọ àwọn pásítọ̀ láti di òpó Ọlọ́run mú nínú ọdún titun yìí.
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Osazee William náà kín ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Adegbite lẹ́yìn. Ó wí pé àwọn èèyàn ń hu ìwà tó burú ju èyí lọ àmọ́ nítorí pé Pásítọ̀ ni Chris ni wọ́n ṣe mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ mẹ́nu. Ẹ má gbàgbé pé ènìyàn ni pásítọ̀ náà ó sì le ṣe àṣìṣe.
Pásítọ̀ Osazee bèèrè pé èrè wo ni àwọn èèyàn fẹ́ jẹ nínú pípolongo irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí, ṣé wọ́n fẹ́ tàbùkù Jésù ni àbí wọ́n fẹ́ ba ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórúkọ jẹ́? Kín ni ìdí tí ti Pásítọ̀ ṣe gbọ́dọ̀ yàtọ̀? Ṣebí a rí àwọn babaláwo tí wọ́n hu irú ìwà yìí tí kò sì sí ẹni tó pariwo wọn.

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Ki lo sele gangan?

Òṣèrébìnrin Doris Ogala ni ó fi èsùn kan Pásítọ̀ Chris Okafor pé odidi ọdún mẹ́sàn-án ló fi bá òun lájọṣepọ̀ pẹ̀lú ìlérí pé yóò fẹ́ òun níyàwó. Ọdún 2017 ni àwọn bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ títí tó fi wá fẹ́ obìnrin mìíràn ní ọdún 2025.
Doris ní nítorí Pásítọ̀ Chris ni òun ṣe kọ ọkọ òun nígbà tó ṣe ìlérí pé yóò fi òun ṣe aya. Ó tún wí pé Pásítọ̀ Chris fi fọ́nrán ìbálòpọ̀ òun síta fún ayé wò. Kò tán síbẹ̀ o, Doris fi ẹ̀sùn kan Pásítọ̀ Chris pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ́wọ́ òun tó sì dá òun ní gbèsè.
Bákan náà ni Doris fi àwọn àwòrán léde pé Pásítọ̀ Chris fún òun ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là kí òun ó pa ohùn dà sọ pé pásítọ̀ kan tó jẹ́ ọ̀tá rẹ̀ ló ní kí òun ó ba orúkọ rẹ̀ jẹ́.
Bílíọ́nù kan náírà ni Doris bèèrè lọ́wọ́ Pásítọ̀ Chris fún owó gbà-má-bínú fún gbogbo ìbálòpọ̀ ọdún mẹ́sàn-án àti bí àwọn ọlọ́pàá ṣe fi ìyà jẹ òun lórí ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́yìn tí Doris sọ̀rọ̀ jáde, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn náà ló ti jáde sọ̀rọ̀ pé Pásítọ̀ Chris bá àwọn lájọṣepọ̀. Lára wọn ni ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀; Bessem Okafor.
Bessem ṣe àlàyé nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pé nítorí ìtìjú ni òun ṣe kọ Pásítọ̀ Chris látàrí pé gbogbo obìnrin ló máa ń bá ní àjọṣepọ̀.
Ebere; ẹni kan tó jẹ́ akọrin ninu ìjọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ náà jáde sọ̀rọ̀ sita, ó ní òun kúrò nínú ìjọ náà nígbà tí Pásítọ̀ Chris fẹ́ fi okó tú ìfun òun jáde. Ó ní ọdún 2015 ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ní ni ajọṣepọ̀ pẹ̀lú reṛ̀ tí òun sì ṣẹ́ oyún mẹ́rin fún un, oyún karùn-ún ni òun kọ̀ láti ṣẹ́ tí òun sì fi bí ọmọ.
Obìnrin mìíràn náà jáde pé òun àti àbúrò òun ni Pásítọ̀ Chris ń kó ìbásùn fún, nígbà tí àwọn lóyún ni àwọn tó kọ̀, ó ní ọmọ tí àwọn bí jọ Chris bíi ìmumu, obìnrin yìí ní àwọn ṣetán láti ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ náà fún ẹ̀rí ohun tí àwọn sọ yìí.
Chidera Okafor; ọmọ Pásítọ̀ Chris náà fi fọ́nrán kan léde, ó ṣe àlàyé pé ọdún 2020 ni òun sá kúrò nílé nígba tí bàbá òun bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ọwọ́ pa òun lára. Pásítọ̀ Chris fèsì sí èyí pé irọ́ ni ọmọ náà ń pa.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnlinechrisokafordorisogalaIwe Iroyin Yorubanewsnews onlinenewsinyorubanewsonlinepastorchrisscandalpastorscandalscandal
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
WOJUOLA FI Ẹ̀SÙN KAN Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ LÓRÍ ÌWÀ ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDE RERE TÓ HÙ.

WOJUOLA FI Ẹ̀SÙN KAN Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ LÓRÍ ÌWÀ ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDE RERE TÓ HÙ.

Recommended

ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA LASUSTECH MÉJÌ PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ WỌN NÍNÚ ÌJÀM̀BÁ ỌKỌ̀.

ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA LASUSTECH MÉJÌ PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ WỌN NÍNÚ ÌJÀM̀BÁ ỌKỌ̀.

7 months ago
Ìròyìn Jákèjádò.

Ìròyìn Jákèjádò.

11 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.