ọ̀fin titun fún àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ láti ẹnu Ọ̀gá àgbà fún ilé ìfowópamọ́ àgbà ní ilẹ̀ Nàìjíríà; CBN; Alàgbà Cardoso ni ó pọn dandan kí àwọn oníbàárà bẹ̀rẹ̀ sí i fara gbá ọgọ́rùn ún kan náírà lórí Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírá ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fi káádì gbowó lẹ́nu ẹ̀rọ tí kìí ṣe èyí tó jẹ́ bánkì ti wọn.
Ọ̀gá àgbà ní ìkìlọ̀ ni kí gbogbo ilé ìfowópamọ́ máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà sókè fún oníbàárà lẹ́ẹ̀kan náà láìsí gbígbowó kélekèle. Bí owó bá jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà, ọgọ́wàá náírà ni oníbàárà yóò san lórí owó náà, bí owó ṣe n pọ̀ si ní ìfaragbá yóò ma gòkè sí.
Òfin yìí yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kínní, oṣù Erénà tó n bọ̀ yìí láti le è máa fi tọ́jú ẹ̀rọ ìgbowó àti ike ìgbowó náà. Bí oníbàárà bá lo ẹ̀rọ ìgbowó EÉ TI ẸẸMÙ àwọn ilé ìtajà nlá nlá tábí ilé oúnjẹ ìgbàlódé, Bánkì yóò kọ́kọ́ fa ọgọ́rùn ún náìrà yọ pẹ̀lú ẹdẹ̀ẹ́gbẹ̀ta náírà ṣángílítí.
Ì bá dára bí àwọn oníbàárà kọ̀ọ̀kan kò bá ṣàyọjúràn sí ti ẹlòmíìràn, kí ilé oge wọn tóge e jẹ, kí wọn ma bá a fi ìgbákúùgbá gbára látàrí lílo ẹ̀rọ ìgbowó ÉÉ TII ẸẸMÙ tí kìí ṣe ti wọn tàbí èyí tó jẹ́ ti ilé ìtajà àti ilé oúnjẹ ìgbàlódé,èyí tí owó ti wọn tún gara.
A tún ún rọ àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ kí wọn máa lo afẹ́fẹ́ ìfowóránṣẹ́ àti èyíkèyí nínú ọ̀nà tí a lè fi owó ṣẹwọ́ sí ìbòmííràn láì faragbá ìjìyà ọgọ́rùn ún náírà sókè. Oníbàárà tún le è máa lọ sọ́dọ̀ àwọn osìṣẹ́ bánkì ẹsẹ̀ títì; P.O.S. láti yẹra fún owó ìyọkúyọ yìí.
Èyí ò wa pọ̀jù báyìí lórílẹ̀ èdè wa? Láìpé yìí ni epo gbówó lórí, iye owó NẸ́PÀ náà fò fẹ̀rẹ̀ lọ sókè,àwọn ilé ìfowópamọ́ náà tún ní kí ló ṣubú tẹ òun? ÈDÙMÀRÈ jọ̀wọ́, bá wa sọ ìgbà dẹ̀rọ̀ kí a le rówó ná.